Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí Ọlọ́pàá kéde pé òun ń wá lórí ẹ̀sùn pé ó fẹ́ dojú ìjọba Bola Tinubu bolẹ̀, fọhùn síta

Oríṣun àwòrán, NPF
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe oun n wa ọkunrin ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan, Andrew Waynn lori ẹsun pe o fẹ doju ijoba Naijiria bolẹ.
Yatọ si Waynne, ọlọpaa tun sọ pe awọn n wa ẹlomiran to jẹ ọmọ Naijira, Lucky Obiyan, lori ẹsun pe awọn mejeji n gbimọ pọ lati wu iwa laabi naa.
Ọlọpaa fẹsun kan ọmọ ilẹ Gẹẹsi ọhun pe o n ko awọn eeyan kan jọ lati lo wọn fun iditẹgbajọba ati lati da omi alaafia Naijiria ru.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adejobi, fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aje, lo ti fi ọrọ naa lede.
"Ọmọ ilẹ Gẹẹsi, Wynne, n ṣiṣẹ loju mejeji, to si n na obitibiti owo lati da ijọba Naijiria ru"
Adejọbi ni “lẹyin ọpọlọpọ iwadii ati ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹka ọtẹlẹmuyẹ mii, a ti fi ṣikun ofin mu eeyan mẹsan an ti wọn n gba owo lati ilẹ okeere lọna ati da omi alaafia Naijiria ru.
“Iwadii wa fi han pe lara iṣẹ wọn ni ṣiṣe onigbọwọ ifẹhonuhan to ni jaigidijagan ninu, pinpin iroyin ẹlẹjeẹ kiri ati ṣiṣẹ awọn nnkan mii to lodi si ofin lati doju ijọba Naijiria bolẹ.
“Ọfintoto wa ṣawari ọmọ ilẹ okeere kan, Andrew Wynne (ti wọn tun mọ si Andrew Povich tabi Drew Povey), ọmọ ilẹ Gẹẹsi, to n ko awọn eeyan kan jọ labẹle lati doju ijọba Naijiria bolẹ.
“Ọkunrin naa ya ọọfisi kan ni ile ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC House to wa niluu Abuja nibi to ti n ta iwe.
O tun da ile ẹkọ 'STARS of Nations Schools' silẹ, eyii to fi bo nnkan to n ṣe gangan mọlẹ.”
Ọlọpaa sọ siwaju si pe Wynne n ṣiṣẹ loju mejeji, bẹẹ lo n na obitibiti owo lati da ijọba Naijiria ru.
Lẹyin naa lo ke si gbogbo araalu lati ṣe iranlọwọ fun ọlọpaa lọna ati mu afurasi ọmọ ilẹ okeere naa atawọn alabaṣiṣẹ rẹ.
Mi o jẹ gbi, mi o le ku gbi – Waynne sọrọ
Wayi o, afurasi naa ti sọ pe oun ko ṣẹ si ofin Naijiria, bẹẹni oun ko bẹru lati ba awọn ọlọpaa sọrọ nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.
Wynne lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.
O ni “Mi o tilẹ mọ pe wọn n wa mi tabi ọdaran ni ni mi, o ti le lọdun marundinlogun ti mo ti n ṣabẹwọ si Naijiria.
“Lati ọpọ ọdun naa, ileeṣẹ agbofinro Naijiria ko sọrọ kankan nipa mi, ọmọ orilẹede kan ṣoṣo ni mi, mi o si ni iwe irinna orilẹede meji.
“Mo ṣetan lati ni ijiroro pẹlu awọn ọlọppaa lori ikanni WhatsApp tabi Zoom, bẹẹ ni mo ṣetan lati lọ ba awọn aṣoju Naijiria sọrọ niluu London.
Lọwọ yii, ilẹ Gẹẹsi ni afurasi naa wa, iyawo rẹ to jẹ ọmọ Naijiria si ti na papa bora latari bi ọlọpaa ṣe n wa ọkọ rẹ.















