Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 2 Owewe, 2024
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́ - 2 Owewe, 2024
Ẹyin ọmọ Naijiria eti yin melo?
Maa wi, a n gbọ
O jọ bii pe ọwọngogo epo bẹntiro to wa lode yii ko ni tete tan nilẹ o
Ah, emi lode lode
Ajọ NNPC ti sọ pe gbese bilọnu mẹfa dọla toun jẹ awọn to n ko epo fun Naijiria lo ṣokunfa ọwọngogo naa
Hmmmmmm
Amọ o ni iṣe ti bẹrẹ lati wa ojutu si ọrọ naa
Igba wo ni ka wa maa reti ati ri epo ra lọpọ yanturu bayii?
Lọ soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
_______________________________________________
Ni Canada
Ọwọ ọlọpaa ilu Toronto ti tẹ obinrin ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni, Amaka Sonnberger
To ni ki awọn eeyan kan maa fun awọn ọmọ Yoruba ati Benin ni majele lọna ti gbẹmi wọn
Ileeṣẹ ọlọpaa Toronto sọ pe oni ọjọ Aje gan ni obinrin ọhun yoo foju bale ẹjọ
Ẹsun idunkokomọni lori ayelujara ni wọn fi kan an