Mo lọ ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje torí mo fi ewì bú ìjọba, láti ìgbà náà, ń kò da aṣọ bojú mọ́ - Ologundudu

Àkọlé fídíò, Ologundudu: Ewi Olanrewaju ni mo fi kọ́ ewì, mo bá Adeboye ṣiṣẹ́, kí ń tó lọ sọ́dọ̀ Sunny
Mo lọ ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje torí mo fi ewì bú ìjọba, láti ìgbà náà, ń kò da aṣọ bojú mọ́ - Ologundudu

Odu ni Akewi Kunle Ologundudu ni agbo ewi kike, kii si se aimọ fun oloko nilẹ Yoruba.

Ọpọ eeyan si lo mọ gbajumọ akewi naa gẹgẹ bii aketata ki ọlọrọ gbọ, to si ti gbe aimọye awo ewi jade.

Oniruru ni awọn ewi Kunle Ologundudu, nigba miran, awo ewi rẹ maa n sọko ọrọ tabi pe akiyesi ijọba to wa lori aleefa sawọn isẹlẹ kan.

Nigba miran, o si le jẹ gbajumọ kan lawujọ ni yoo ko sọwọ Kunle Ologundudu, ẹni ti yoo fi ewi pe ọpọlọ onitọhun wa sile ninu awọn iwa ibajẹ to n se.

A le pe gbajumọ akewi naa gẹgẹ bii ajafẹtọẹni tabi ajafẹtọlu nitori ọpọ awo orin rẹ lo fi maa n tako iwa ibajẹ.

Nigba miran, Ologundudu maa n fara pamọ si kọrọ tabi da asọ asiri boju lati pọ ti ọfun rẹ sita tako aida ti ẹnikan n hu tabi ijọba tabi awujọ kan.

Iwa akikanju akọrin akewi yii lo mu ki BBC Yoruba se awari rẹ lati mọ iru ẹni ti Kunle Ologundudu jẹ ati awọn ohun to ti gbe ile aye se.

Ninu fidio yii si lo ti salaye itan igbesi aye rẹ, ohun to sọ di ajafẹtọlu ati awọn aseyọri to ti fi ewi ni.

Kunle Ologundudu

“Ewi ori redio ni mo fi bẹrẹ lọdọ Gbenga Adeboye, ki n to lọ di manija ikọ orin King Sunny Ade, emi ati Lati Suebebe to ku, dijọ wa lọdọ Sunny Ade ni”

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Kunle Ologundudu ni oun ni ọkọ sọja, ọkọ oselu, ọmọ kan soso ti Oodua bi.

“Ko to di pe mo de ibi isẹ ewi, mo ti kọkọ sisẹ Olukọ ni Aries secondary school nilu Ile Ife ki oun to lọ ba Gbenga Adeboye nilu Eko

Mo maa n kewi lori Radio nigba naa, ki n to lọ maa se alakoso ikọ orin King Sunny Ade, mo si jẹ ọmọde nigba naa.

Lara awọn ti a dij wa lọdọ Sunny Ade nigba naa ni Dayo Adewunmi (Lati Suebebe) to ku yẹ, a dijọ sisẹ papọ ni.

Bakan naa, Toyin Elegede wa pẹlu wa nigba naa.

Mo si maa n kọ orin juju bii ti Sunny Ade nigba ti mo wa nile ẹkọ girama.

“Mo maa n kewi nile ẹkọ girama amọ ko dan mọran, ewi Lanrewaju Adepoju ni mo fi kọ ewi"

Nigba to n salaye bi oun se bẹrẹ orin ewi, Kunle Ologundudu ni ile ẹkọ girama ni oun ti maa n kewi diẹ diẹ amọ ewi naa ko da mọran rara.

“Olanrewaju Adepọju lo wa nita nigba naa bii gbajumọ akewi ti gbogbo aye mọ.

Olukọ mi wa gba mi nimọran pe ki n lọ maa gbọ awọn awo orin ewi Olanrewaju Adepọju lati dangajia ninu ewi kike.

Mo si maa n kewi ti awa akẹkọ ba n se ijiroro lọjọ Alamisi, ti maa si maa gbọ awo orin ewi Adepoju, paapaa eyi to pe akọle rẹ ni ‘Ijamba Mọto’

Kunle Ologundudu

“Ọdun 1994 ti mo kọrin ewi sọko ọrọ si ijọba ologun labẹ akoso Babangida to fagile ibo June 12 ni mo di gbajumọ akewi”

Nigba to n salaye awo orin to gbe jade bii ilumọọka akewi, eyi ti aye n gba tiẹ, Kunle Ologundudu ni ọdun 1994 ni oun di gbajumọ akewi.

Ologundudu ni oun ko fi bẹẹ maa kewi mọ taara mọ nigba ti oun wa lọdọ Sunny Ade, titi di igba ti isẹlẹ June 12 waye.

“Lọdun i994 yii, Sunny Ade yẹ ko ko wa lọ soke okun, mo si ti ra tikẹẹti irinna lai mọ pe Sunny Ade ko gba fisa fun mi lati ba a rinrinajo naa.

Asiko yii si ni Abiola kede ara rẹ bii aarẹ ti ilu dibo yan, mo si da tikẹẹti ilu oyinbo naa pada fun Nigeria Airways, wọn fun mi ni owo pada, eyi ti mo lo lati fi kọrin ewi .

Orin ewi naa ni mo fi n se atilẹyin fun Oloye MKO Abiola to bori ibo June 12 amọ tijọba ologun labẹ Ibrahim Babangida wọgile ibo naa.

Mo wa kewi lati ti Abiola lẹyin nigba to kede ara rẹ bii aarẹ tuntun ti aye dibo yan eyi tijọba ologun wọgile.

Lati igba naa ni mo ti n gbe ọpọ awo orin sita lati tako ijọba Babangida ati ti ijọba ologun Sani Abach to tẹle.

Koda, mo tun kọ orin ewi lati na ijọba alagbada labẹ Oloye Olusẹgun Obasanjo ni pasan.

Kunle Ologundudu

“Ọpọ igba ni mo ti lọ si ọgba ẹwọn tori awọn awo orin ti mo kọ lati bu ijọba”

Ologundudu tẹsiwaju lati salaye nipa ọpọ ipenija to la kọja tori pe o n kọrin ewi bu ijọba ati awọn adari wa.

Koda, o ni ọpọ igba ni wọn ti dunkoko ẹwọn mọ oun, ti wọn si sọ oun si atimọle.

“Awọn eeyan kan mu mi nigba kan, pe ki n sanwo fun wọn ki wọn maa gbe mi lọ si Dodan Barrack lai mọ pe irọ ni.

Sugbọn awo orin ti mo se fun aarẹ Obassanjọ lo mu ki wọn maa wa mi, ti wọn si gbe mi nile Ife lọ si Abuja.

Wọn fi mi si ọgba ẹwọn ni Kuje, mo si lọ sile ẹjọ, ti Tafa Balogun to jẹ ọga agba ọlọpaa nigba naa si ni ki n maa fi nọmba ipe mi sori awọn awo orin ti mo ba gbe jade.

Lẹyin igba ti wọn fi mi silẹ ni mo lọ silu oyinbo, mo n gbe awo orin jade, ti mo si n fi ransẹ sile.”