Portable sọ òkò ọ̀rọ̀ ságbo amúlùúdù torí ọ̀rọ̀ Bobrisky àti TG Omori

Oríṣun àwòrán, Portable/TG Omori/Bobrisky
Gbajumọ olorin, Habeeb Okikiola “Portable” ti sọ oko ọrọ si awọn akẹgbẹ rẹ pe ifẹ oju aye lasan ni wọn n ṣe fun ara wọn.
Portbale lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to ti fẹsun kan awọn gbajumọ ni Naijiria pe wọn kọ lati da owo jọ fun itọju adari orin, Thankgod Omori, ti ọpọ mọ si TG Omori to ni aisan kidinrin.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn eeyan naa le da owo jọ fun Bobrisky amọ wọn kọ lati da owo jọ lati itọju TG Omori.
Lara awọn ti Portable sọ oko ọrọ si ni gbajumọ agbabọọlu, Victor Osmhen, Don Jazzy, atawọn mii.
Gẹgẹ bii ohun ti Portbale sọ, wọn gbaruku ti Bobrisky lasiko ti EFCC ran lọgba ẹwọn ṣugbọn wọn kọ lati ṣe irufẹ iranwọ bẹẹ fun akẹgbẹ wọn ninu iṣẹ orin.
O ni “TG Omori ni aisan kidirin, awọn gbajumọ kọ lati da owo jọ fun itọju rẹ tabi ki wọn fun ni kidinrin tuntun, amọ Victor Osimhen atawọn mii da owo jọ fun Bobrisky ti ko ṣe anfanni fun ẹnikẹni.
“Ifẹ ori ahọn lasan lo kun aarin awọn olorin.”
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni TG Omori ti kọkọ lede pe oun ni aisan kidinrin.
Omori ṣiṣẹ abẹ lati paarọ kidinrin rẹ amọ iṣe abẹ naa ko ṣe aṣeyọri, eyii to mu ki awọn akẹgbẹ rẹ bii Davido ati Kizz Daniel ba kẹdun.
TG Omori fesi
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wayi o, TG Omori funra rẹ ti sọrọ soke pe awọn akẹgbẹ oun ko da oun da isọro oun.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ lọjọ Aiku, ọkunrin naa ni ọrọ ko ri bi Portable ṣe lero, nitori awọn akẹgbẹ oun nidi iṣe orin duro ti oun lasiko iṣoro aisan kidinrin naa.
O ni “adura, atilẹyin ati ifẹ yin nikan ni mo nilo... awọn akẹgbẹ atawọn ọrẹ mi ko kọ mi silẹ fun ọpọlọpo oṣu ki n to sọrọ sita nipa aisan mi.
“Ẹ maṣe naani awọn aja to n gbo.
"Jesu lọba."















