Ìjàm̀bá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn mẹ́rin, ọ̀pọ̀ míì farapa l’Osun

Aworan awọn ọfisa FRSC

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eeyan mẹrin ti padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ kan to waye ni agbegbe Ikeji-Arakeji, ilu kan to wa oju opopna Ilesa si Akure nipinlẹ Osun.

Bakan naa, ogun eeyan mi farapa yanayana lasiko ti ijamba naa waye, ti ọpọ ọkọ si kọlu ara wọn.

Ajọ to n risi oju opopona lorilẹede Naijiria, FRSC lo kede iṣẹlẹ yii.

Ninu fọnran kan to tẹ wa lọwọ nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ina sọ lara ọkọ kan, ti ọpọ ero ọkọ si yi ka.

Eeyan mẹta ninu awọn eeyan to farapa lo jẹ agunbanirọ. Pupọ awọn eeyan to farapa ni aṣọ ọrun wọn kun fun ẹjẹ.

Agbẹnusọ FRSC nipinlẹ Osun, Taofeek Sokunbi ni ere asapajude lo sokunfa ijamba naa.

O ni obinrin mẹta ati ọkunrin kan lo padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ naa.

“Ọkọ mẹta lo kọlu ara wọn, ti eeyan mẹrin si padanu ẹmi wọn. Bọọsi akero meji ati ọkọ nla kan lo kọlu ara wọn.

“ Mo n rọ awọn dirẹba ọkọ pe o se koko ki wọn ni suuru lasiko ti wọn wa ọkọ, ki wọn si yago fun ere asapajude .

“Awọn dirẹba ọkọ ti wọn ko ni suuru lo fa ijamba yii.”