Ààrẹ Tanzania fi orúkọ alátakọ̀ rẹ̀ sọ kìnìún aláìgbọ́ràn kan lọ́gbà ẹranko

Oríṣun àwòrán, Tanzania Wildlife Management Authority
Yoruba bọ wọn ni wọn o fẹ ọ niluu, o da orin ta ni yoo ba ọ gbe e. Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu Aarẹ Samia Saluhu Hassan orilẹede Tanzania to fi orukọ kiniun alaigbọran kan sọ ọkan lara awọn olori ẹgbẹ oṣelu alatako nilẹ naa.
Nigba ti Aarẹ Samia n ṣabẹwo si ọgba ẹranko nla kan lorilẹede Tanzania ni wọn fi kiniun kan ti kii gbọ kii gba han an.
Bayii ni aarẹ beere wi pe ‘’ṣe kiniun yii ni orukọ? Bi bẹẹ kọọ, ẹ fun un ni Tundu Lissu.’’
Ọgbẹni Lissu ni adari ẹgbẹ oṣelu alatako Chadema.
Awọn ọlọpaa ti fọwọ ofin mu Lissu ninu ọdun 2024 yii lori ẹsun wi pe o fẹ lo awọn ọdọ lati ṣe ifẹhonuhan tako ijọba to wa lode.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ọgbẹni Lissu fẹ lo iwọde ọhun lati da rogbodiyan silẹ lorilẹede Tanzania.
Aarẹ Samia ni oun fun kiniun yii lorukọ Lissu tori bi adari ẹgbẹ oṣelu alatako naa kii ṣe le jokoo jẹjẹ sibi kan.
Kinni adari ẹgbẹ oṣelu alatako sọ nipa orukọ rẹ ti aarẹ fi sọ kiniun?
Ọpọ eeyan lo fẹ mọ iha ti Ọgbẹni Lissu kọ si bi Aarẹ Samia ṣe fi orukọ rẹ sọ kiniun alaigbọran to wa lọgba ẹranko.
Amọ, o dabi ẹni pe Ọgbẹni Lissu ko ri nnkan naa bi ohun to buru.
‘’Idile awọn akọni ni mo ti wa, baba to bi baba mi pa kiniun to ṣe ikọlu si i atawọn maalu rẹ,’’ Ọgbẹni Lissu lo sọ bẹẹ fawọn akọroyin.
Ọgbẹni Lissu jẹ gbajugbaja alatako ijọba Aarẹ Samia, koda, o moribọ ninu ikọlu tawọn agbebọn kan ṣe si i lọdun 2017.
Ọta ibọn mẹtadinlogun ni wọn yin sara ọkọ to wa ninu rẹ, amọ, Lissu moribọ pẹlu ifarapa.
Ko si ẹni to mọ awọn to wa nidi ikọlu yii titi di oni.
Ọgbẹni Lissu dupo aarẹ orilẹede Tanzania lọdun 2020, amọ, o fidirẹmi nigba ti John Magufuli jawe olubori ninu ibo ọhun.
Arabinrin Samia to jẹ igbakeji aarẹ nigba naa lo di adari lọdun 2021 nigba ti Magufuli ku.
Eto idibo gbogbogbo mii yoo waye lọdun to n bọ, Aarẹ Samia si ti n gbero lati dije fun saa keji ninu eto idibo naa.
O ṣee ṣe ki Ọgbẹni Lissu ati aarẹ Samia jọ waako ninu eto idibo naa lọdun 2025.















