Obìnrin kan kú lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ láti fọn ìdí l'Eko, ọlọ́pàá ní dókítà ti sálọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arabinrin kan, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Abiola lo ti padanu ẹmi lojiji lasiko to n se iṣẹ abẹ lati fọn idi ko le tobi si i ni ile iwosan kan nipinlẹ Eko.
Ẹni ọdun merindinlogoji yii lọ ba dokita kan ti orukọ rẹ n jẹ Idara Bassy ni agbegbe Lekki ni fun iṣẹ abẹ to gba odi lọ lara rẹ, to si ran lọ si oorun aremabọ
Iroyin to tẹ BBC lọwọ ni pe oloogbe naa lọ si ile iwosan naa ni Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2024 sugbọn ọrọ yii ba ibo miiran yọ nigba ti nọọsi kan fun oloogbe ni abẹrẹ eyi to gbodi lọ lara rẹ.
Iṣẹ abẹ yii ni ọpọ mọ si Brazilian Butt Lift (BBL), ninu eyi ti wọn ti ma n ko ọra lati apa ibi kan lara sinu idi lati le mu ki idi naa tobi si i, ati lati mu ko duro daadaa.
Lẹyin ti Abiola gba abẹrẹ tan, to si n lọ si ile pada ni awakọ to n gbe e pada ṣakiyesi pe, oloogbe bẹrẹ si ni ma mi ni ọna to ba ni l'ẹru pupọ, to si pada jade laye.
Oun lo si fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ni afurasi to jẹ dokita ile iwosan ti salọ.
“Afurasi lori iṣẹlẹ ti ṣalọ bayii, o ni lati wa pese idahun si awọn ibeere kan.
“Iwadii n lọ lọwọ bayii.”
Bakan naa ni Hundeyin ni nọọsi to fun oloogbe ni abẹrẹ pẹlu aṣẹ dokita rẹ ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa fun ifọrọwanilẹnu wo.
Eyi ki se igba akọkọ ti iroyin lori pe eeyan kan padanu ẹmi rẹ lẹyin to se iṣẹ abẹ lati fọn idi, jade laye.
Ni ọdun 2023, arabirin kan ti orukọ rẹ n jẹ Destiny padanu ẹmi rẹ lẹyin to se iṣẹ abẹ lati fọn idi nipinlẹ Eko kan naa.















