Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Aworan Ko ṣe e ma gbọ o

Akinlabi, n gbọ se loootọ ni pe ijọba fẹẹ maa fun awọn araalu ni Mita ina mọnamọna lọọfẹ?

Haa, Busayo, bayẹn kọ ni ọrọ se ri o

O da, ba mi tan imọlẹ si i.

Minisita fun ina mọnamọna, Adebayo Adelabu, ni ko si nnkan to jọ mọ pe ọọfe ni Mita ina mọnamọna

Ọdun mẹwaa gbako ni awọn eeyan to ba n lo Mita yii yoo fi san owo naa pada

Elo ni owo naa ati pe bawo lawọn eeyan yoo se san owo yii pada fun ijoba

Kan si oju opo BBC.com/Yoruba lati mọ nipa rẹ

O ya ẹ tun sun mọ mi kẹ ẹ mọ bo se n lọ

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, Joe Ajaero, ti pada yọju si olu ileeṣẹ ọlọpaa o

Koda tilu-tifọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ, agbẹjọro ati awọn ololufẹ rẹ fi tẹle e debẹ niluu Abuja

Eyi waye lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa kọwe wa a wi tẹnu rẹ si i.

Lori ẹsun ṣiṣe atilẹyin fun igbesunmọmi ati iditẹmọ ijọba

Sugbọn, sọ fun mi, ki ni Ajaero ba bọ lati ibi ifọrọwanilẹnuwo naa

To o ba fẹ mọ ọ, kan si oju opo BBC.com/Yoruba fun ẹkunrere iroyin