Kí ló dé tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún ránṣẹ́ pe Ajaero lẹ́ẹ̀kejì?

Awọn oṣiṣẹ to korajọ lati ṣe atilẹyin fun Ajaero
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileṣẹ ọlọpaa Naijiria tun ti ranṣẹ pe aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, ẹka ti NLC, Joe Ajaero nigba keji.

Wọn ni ki Joe Ajaero yọju si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja l’Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan an, ọdun ti a wa yii.

Ninu lẹta kan ti kọmiṣanna ọlọpaa, Ibitoye Rufus Alajide buwọlu lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, o sọ pe ki Joe Ajaero ati Emmanuel Ugboaja to jẹ akọwe agba fẹgbẹ NLC yọju si wọn lọjọ karun-un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024.

Lẹta ọhun sọ pe igbakeji ọga ọlọpaa patapata ti ẹka ọtẹlẹmuyẹ ti wọn pe ni Force Intelligence Operation ni ki Ajaero ati Ugboaja yọju si lati dahun ibeere lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe ni itẹsiwaju lori ẹsun “iwa ọdaran ti hihalẹ, iwa to le da wahala silẹ niluu ati biba dukia jẹ,” nibi ti orukọ rẹ ti jẹyọ.

Eyii ni yoo jẹ igbakeji ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo maa ranṣẹ pe Joe Ajaero lati yọju si ileeṣẹ wọn lori ẹsun iwa ọdaran.

Ṣaaju asiko yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ti pe aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa lati yọju si olu ileeṣẹ wọn logunjọ, oṣu kẹjọ, lori ẹsun ṣiṣe agbatẹru awọn agbesunmọmi, nibi ti wọn sọ pe orukọ rẹ ti jẹyọ ninu iwadii awọn.

Ṣugbọn Joe Ajaero da ọga ọlọpaa lohun pe oun ti ni eto fun ọjọ naa, ati pe oun yoo yọju nigba miran.

Atẹjade ti igbimọ agbẹjọro, eyi ti Samuel Ogala buwọlu sọ pe “Kọmureedi Ajaero ti gbaradi” fun ifọrọwerọ naa l’Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2024.

Ju gbogbo rẹ, ajọ NLC ranṣẹ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn lati yọju si olu ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ipinlẹ to wa ni Naijiria, titi digba ti ọga wọn yoo fi jade.

Lẹyin ifọrọwerọ ọhun pẹlu ọlọpaa, Ajaero pada si ile ẹgbẹ NLC lọjọ naa.

Olorí ẹgbẹ́ NLC, Joe Ajaero sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tó lọ j'ẹ́jọ́ rẹ̀ níléèṣẹ́ ọlọ́pàá

Joe ajaero

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Joe Ajaero ti sọ pe ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan oun ko lẹsẹ nilẹ, ati pe awọn ko le kawọ gbera fun ẹnikẹni lati maa dunkooko mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria.

Joe Ajaero lo sọ eyi ni kete to kuro ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Abuja, nibi to ti lọ dahun awọn ibeere lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Deedee agogo mẹwaa kọja iṣẹju mẹtadinlogun owurọ lo wọ ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ikọ ẹgbẹ oṣiṣẹ, to si kuro nibẹ ni deedee agogo mọkanla kọja iṣẹju mẹẹdogun owurọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ẹka ti IRT fi ẹsun oriṣiriṣi kan Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Joe Ajaero, ti won si ni o gbọdọ yọju si wọn laarin wakati mẹrinlelogun, bi bẹẹkọ, awọn yoo fi kele ofin gbe e.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Ajaero ni ṣiṣagbatẹru ikọ agbesunmọmi, iwa ọdaran ori ayelujara, aṣilo ipo ati iditẹmọjọba.

Nigba to n sọrọ ni kete to jade sita lẹyin to ti dahun oriṣiriṣi ibeere, Ajaaero sọ pe awọn ẹsun ti wọn fi kan oun ko lẹsẹ nilẹ, ati pe oun ko ni aṣiri ikọkọ kankan lati fi pamọ.

“Wọn ko le dunkooko mọ wa. Gbogbo ẹsun ti wọn fi kan wa ni ko lẹsẹ nilẹ, ati pe a ko ni ohunkohun tabi aṣiri ikọkọ lati fi pamọ,” Ajaero sọ bẹẹ.

Ogbontarigi agbẹjọro lorileede Naijiria, Femi Falana wa lara awọn to lewaju Ajaero lọ sileeṣẹ ọlọpaa, to fi mọ awọn agbaagba ẹgbẹ oṣiṣẹ ati awọn alatilẹyin rẹ.

“Ẹ ko le ṣe iru iṣẹ ti a n ṣe yii lai la iru awọn ipenija bayii kọja. Lawọn ẹka kereje, pupọ ninu wa la ni iriri rẹ, koda lọdun 1997 si 1998, a wa lọgba ẹwọn Abacha pẹlu Femi Falana,” Ajaero tẹsiwaju.

“Ṣugbọn ko nii ṣe pẹlu ohun to ba jẹ, a maa tẹsiwaju ninu ilakaka naa, a ti gba owo oṣu tuntun to kere julọ, wọn ko si le dunkooko mọ wa. A ni lati tun tẹsiwaju fun sisan owo oṣu tuntun naa laipẹ.

O ni gbogbo ohun ti yoo ba mu igba aye irọrun ba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, ni oun yoo lọwọ si.

Bakan naa ni Aarẹ NLC naa tun jẹ ko di mimọ pe oun wa si ọdọ ọlọpaa lati dahun ibeere wọn, lati le kadi gbogbo ẹsun buruku ti wọn fi kan oun nilẹ kuro, ati lati jẹ ki wọn mọ pe oun ko lẹbọ-lẹru.

“Ibi ti a fẹnuko si lagbara ju ti tẹlẹ lọ. A maa tubọ maa lewaju ohun to ba jẹ ti oṣiṣẹ kaakiri orileede yii, lai nii ṣe pẹlu ohun to ba fẹẹ jẹ idiwọ,”Ajaero kadi ọrọ rẹ.

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yọjú síléèṣẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ṣíṣe àtìlẹyìn fún ìgbésùnmọ̀mí

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, NLC

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Joe Ajaero, ti yọju si ileeṣẹ ọlọpaa lati dahun ibeere lori ẹsun iditẹmọ ijọba, ati gbigbọ bukata igbesunmọmi.

Ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ni ileeṣẹ ọlọ̀paa ranṣẹ si Ajaero lati yọju si wọn.

Amọ aarẹ ẹgbẹ NLC ọhun sọ pe ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, to jẹ Ọjọbọ, ni oun yoo yju.

Lẹyin eyi ni awọn ọmọ ẹgbẹ dunkooko pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi, ti awọn ọlọpaa ba fi mu aarẹ wọn.

Ogunlọgọ awọn oṣiṣẹ ọhun si lo pejọ si olu ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Abuja, lati sẹ atilẹyin fun Ajaero.

Amọ akọroyin BBC jabọ pe, nigbẹyin, awọn alaṣẹ NLC ko jẹ ki awọn oṣiṣẹ naa ba aarẹ wọn lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa.

Awọn oṣiṣẹ to korajọ lati ṣe atilẹyin fun Ajaero
Awọn oṣiṣẹ to korajọ lati ṣe atilẹyin fun Ajaero
Àkọlé àwòrán, Ilumọọka agbẹjọro, Femi Falana, lo n sẹ aṣoju aarẹ ẹgbẹ NLC