Ìdí tí ẹgbẹ́ ASUU tún fi ń dúnkòokò ìyanṣẹ́lódì mọ́ ìjọba

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yunifasiti lorilẹede yii, iyẹn Academic Staff Union Of Universities, (ASUU) tun ti dunkooko lati yanṣẹ lodi lẹẹkan si i.
Idunkooko naa n waye pẹlu bi ASUU ṣe kede pe ijọba apapọ Naijiria kọ lati mu adehun ti awọn jọ ṣe lati ọdun 2009 ṣẹ.
Tẹ o ba gbagbe, lati ọdun 2003 ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti yii ti n ṣe ipade atilẹkunmọri ṣe pẹlu ijọba apapọ, ohun ti ASUU si n wi lati igba naa ni pe ki ijọba ṣe afikun owo to ya sọtọ fun awọn yunifasiti, ki igbaye-gabdun awọn oṣiṣẹ ileewe le waye.
Ẹgbẹẹ ASUU tun pade pẹlu ijọba apapọ Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn,oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, lẹyin ti wọn ti ṣepade lẹẹmeji ọtọọtọ pẹlu minisita eto ẹkọ, lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ kan naa.
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe afikun owo ti wọn ya sọtọ fun eto ẹkọ ninu iṣuna ọdun 2024, pẹlu erongba lati gbọ ohun ti ASUU n wi, sibẹ, ẹgbẹ naa taku pe ida mẹẹẹdogun (15%) ni kijọba apapọ ya sọtọ fun eto ẹkọ.
Lọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹjọ, 2024 yii, Minista fun eto ẹkọ, Tahir Mamman, ṣalaye lorii tẹlifiṣan Channels, pe gbogbo iṣoro to le fa iyanṣẹlodi ni ijọba n wa ọna lati yanju.
Lati ọdun mẹwaa sẹyin, ọdun 2023 nikan ni ẹgbẹ ASUU ko yan iṣẹ lodi.
Ninu iṣakoso to kọja, oṣu mẹjọ ni ASUU fi daṣẹ silẹ. Iyanṣẹlodi naa bẹrẹ lọjọ kẹrinla, oṣu keji ọdun 2022, o si pari lọjọ kẹrinla oṣu kẹwaa, 2022. Eyi ni igba ti iyanṣẹlodi naa pẹ ju.
Kootu to n gbọ ẹjọ ileeṣẹ ati ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun lo paṣẹ pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ nigba naa, ṣugbọn ẹgbẹ ASUU sọ pe awọn ko ti i yanju ọrọ awọn pẹlu ijọba apapọ.
Wo àwọn ìgbà tí ìyanṣẹ́lódì ASUU ti wáyé nítorí àdéhùn wọn pẹ̀lù ìjọba àpapọ̀
Ẹgbẹ ASUU yanṣẹlodi ni 2009, 2010, 2011, 2013, 2014, 2016, 2017, 2018, 2020 ati 2022.
Iyanṣẹlodi wọn n ṣe akoba fun ẹka ẹkọ giga lorilẹede Naijiria, pẹlu bi awọn akẹkọọ ṣe n fi akoko ṣofo lai ri nnkan kan ṣe lawọn asiko naa.
Ni 2009, ẹgbẹ ASUU yanṣẹ lodi fun oṣu mẹrin nitori adehun ọdun 2007 to wa nilẹ laarin ẹgbẹ naa ati ijọba apapọ.
Oṣu marun-un ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yunifasiti fi yanṣẹlodi ni 2010.
Ni 2011, wọn yanṣẹlodi fun oṣu mọkandinlọgọta (59 days), nitori ijọba ko mu adehun ọdun 2009 ṣẹ.
Wọn tun daṣẹ silẹ fun oṣu mẹfa nigba ti wọn n beere afikun ọdun ifẹyinti awọn oṣiṣe fasiti. ASUU fẹẹ kijọba sọ ọ di aadọrin ọdun, ki wọn si ṣafikun owo ẹka ẹkọ kuro ni ida mẹẹẹdogun, ki wọn sọ ọ di ida ogun ninu eto iṣuna.
Ni 2014, ASUU yanṣẹlodi nitori ijọba apapọ ko tẹle adehun ti wọn jọ ṣe.
Oṣu kọkanla ọdun 2016 ni ASUU daṣẹ silẹ fun ọsẹ kan.












