Oore wo ni ìrìnàjò Tinubu sí China yóò ṣe fún Naijiria?

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ Aarẹ Naijiria ti tan imọlẹ si irinajo ti Aarẹ Bola Tinubu fẹẹ lọ lorilẹede China lọsẹ to n bọ.

Ajuri Ngelale, olugbani-nimọran pataki fun Tinubu lori eto iroyin, lo ṣiṣọ loju irinajo naa l’Abuja lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, 2024.

O ṣalaye pe yatọ si awọn anfaani nla ti lilọ si China naa yoo mu wa fun Naijiria, yoo tun fi ẹsẹ ọrọ aje mulẹ daadaa laaarin Naijiria ati China.

Ngelale sọ pe Aarẹ Tinubu yoo de awọn ileeṣẹ nla-nla ni China, lara wọn ni Huawei Technologies ati ileeṣẹ ọkọ oju irin China, China Rail and Construction Corporation, (CRCC).

Eyi lo ni yoo ran abala Ibadan si Abuja lọwọ lati pari kia, ninu iṣẹ ọkọ oju irin to ya kankan, ti wọn n ṣe lati Eko si Kano.

Wo àwọn ààfààní míràn tí ìrìnàjò náà yóò mú wá fún Naijiria

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Ngelale to gba ẹnu Aarẹ Tinubu sọrọ, sọ pe Aarẹ yoo ṣepade pẹlu awọn olori ileeṣẹ nla mẹwaa ni China.

Lara awọn ẹka ti ipade naa yoo kan bo ṣe sọ ni :ẹka ibaraẹnisọrọ, epo rọbi ati afẹfẹ idana, alumi ti i ṣe irin (alluminium), idasilẹ ebute okun, okoowo ati ọrọ sisọ ninu afẹfẹ.

Gẹgẹ bi Olugba-Aarẹ Tinubu nimọran lori iroyin ṣe wi, o ni oore ti awọn eeyan yoo foju ri lẹsẹkẹsẹ, ati ti ọlọdun pipẹ ni irinajo aarẹ si China naa yoo mu ba Naijiria.

Yoo kan awọn olokoowo keekeeke pẹlu, yoo si jẹ oore nla fun ọrọ aje Naijiria lapapọ bo ṣe sọ.

“Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, yoo gbera lọ si Beijing, ni China lọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹsan-an ọdun 2024, lati darapọ mọ ipade ati awọn eto ti yoo ṣe ọrọ aje Naijiria ati awọn eeyan ibẹ lanfaani.

‘’Awọn oore ẹsẹkẹsẹ pẹlu ti ọjọ iwaju si ni.’’

Ajuri Ngelale lo sọ bẹẹ.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS náà yóò ṣèpàdé

Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe Aarẹ Tinubu ni Aarẹ ECOWAS,(Economic Community of West African States) to so awọn orilẹede Iwọ-Oorun Africa pọ, awọn alaṣẹ ilẹ okeere mi-in naa yoo darapọ mọ ipade ti wọn pe ni Forum on China-Africa Cooperation(FOCAC).

Nibi ipade naa ni wọn yoo ti sọ awọn ọrọ to kan China ati Africa.

Aarẹ Tinubu yoo kopa labala ipade alaafia ati aabo ilu, nibi ti yoo ti sọ iṣoro ai si aabo to n koju Naijiria.

Ngelale tẹsiwaju pe Aarẹ Tinubu yoo tun tọwọ bọ awọn iwe adehun lẹyin ajọsọ ọrọ, pẹlu Aarẹ China, Xi Jinping, ti orilẹede China.

Awọn adehun naa yoo da lori ọgbin, idagbasoke ọrọ aje ati nini ajọṣepọ to gunmọ pẹlu China.

Ipade naa yoo tun jẹ ki Tinubu ati Jinpin sọrọ lori aabo ilẹ yii pẹlu awọn ilẹ okeere.