Mo ti tọwọ́ bọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí kò mọ́ l'áyé, àmọ́... - Seun Egbegbe

Oríṣun àwòrán, Seun Egbeegbe@ Instagram
Olajide Kareem, ti ọpọ mọ si Seun Egbegbe ti sọrọ lori oniruuru nnkan to ti ọwọ bọ nile aye.
Gbajumọ abani gbe sinima jade ni Egbegbe, ko to o di pe o lọ si ẹwọn fun ẹsun jibiti ati ole jija.
Lẹyin ọdun mẹfa to ti ọgba ẹwọn de, Seun Ẹgbẹẹgbẹ ti ṣalaye awọn iwa to n hu ko too lọ si ẹwọn ọhun, ati iriri rẹ ninu ọgba ẹwọn naa.
Nibi ifọrọwerọ kan ti Ẹgbegbe ṣe pẹlu Biola Bayo, lori eto ‘Talk to B’, lọsẹ to kọja lo ti ṣalaye pe oun hu iwa ibajẹ to pọ nigba kan ri, ṣugbọn oun ko ba wọn gba ẹmi eeyan ri.
‘Obìnrin tí mo bá gbé sùn láàárọ̀ kọ́ ló máa sùn tì mí lálẹ́ ‘’

Oríṣun àwòrán, @Talk to B
Nigba to n ṣalaye awọn iwa to ti hu sẹyin, Seun Egbegbe sọ pe, ‘’ọmọ ti mo ba gbe sun laaarọ kọ, oun kọ lo maa sun lọsan-an. Ọpọlọpọ nnkan idọti ni mo ti ṣe tẹlẹ ki n le fi ri owo.
‘’Ṣugbọn gbogbo nnkan ti mo ṣe nigba yẹn, nnkan kan ti mi o ṣe ni pe mi o gba ẹmi eeyan, mi o dẹ ni i ba wọn ṣe e laye.
‘’Gbogbo nnkan ti mo ṣe nigba yẹn, ki i ṣe pe ẹnikan ti mi si i, afẹ aye ni. Ṣugbọn gbogbo ẹ naa wa da lonii.
‘’Nigba ti mo wa lẹwọn, mi o ni anfaani si obinrin fun ọdun mẹfa, mi o ku.
‘’Ninu ọgba ẹwọn ti mo wa, yara kan naa ni wọn fi emi ati Mompha si, pẹlu Ayo Fayoṣe ti EFCC mu nigba yẹn.
‘’Yara kan wa lọgba ẹwọn ti wọn n pe ni ‘Welcome cell’. Bi wọn ba gbe eeyan ogun (20) wa sibẹ, nigba ti yoo ba fi di ọjọ keji, ẹ le gbọ pe eeyan meji ti ku lara wọn.Fun odidi ọdun kan, wọn o gbe ẹnikankan lọ si kootu ninu wa, a kan wa lẹwọn nibẹ naa ni.
‘’Awọn ijọ Baba Adeboye, Ridiimu, gbiyanju gan-an. Gbogbo ọjọ Sannde ni wọn maa n ba wa gbe ounjẹ wa. Ẹlẹwọn ẹgbẹrun mẹta, wọn si maa fun gbogbo wọn pata ni irẹsi jọlọọfu pẹlu ẹran meji ati omi inu ike.’’
‘’Nǹkan kò dẹrùn fún mi nígbà tí mo jáde lẹ́wọ̀n’’
‘’Bi mo ṣe wa yii, ijade mi, nnkan o dẹrun fun mi rara. Mo mọ nnkan ti mo le ṣe, ọjọ ti mo ti jade, ti mo ba fẹẹ ra mọto 100m laarin ọsẹ kan, ma a ra a. Ṣugbọn mi o fẹẹ pada si ọna yẹn mọ.
‘’Ọkunrin kan wa lẹwọn, ori ẹja lo gbe e debẹ. O ṣa iyawo ẹ wẹlẹwẹlẹ, o ko o sinuu baagi, o waa ti kẹkẹ to gbe e si lọ sile awọn ana rẹ, ibẹ lo lọọ gbe ara iyawo ẹ si. O ṣi wa lẹwọn di bayii. Ori ẹja ni wọn maa n pe e lẹwọn.
‘’Ọgba ẹwọn ki i ṣe ibi-ire rara, ojoojumọ ni awọn eeyan n ku nibẹ. Nigba ti mo wọbẹ, mo sọ fun Ọlọrun pe to ba jẹ pe loootọ lo wa, wọn o gbọdọ gbe oku mi jade nibẹ’’
Nigba to n sọrọ nipa bi awọn obi rẹ mejeeji ṣe ti dagba, omi bọ loju Seun Ẹgbẹẹgbẹ, o si gbadura pe k’Ọlọrun jẹ ki baba ati iya naa jere oun.
Báwo ni Seun Egbegbe ṣe d’èrò ẹ̀wọ̀n ?
Ọdun 2017 ni Seun Egbegbe di ero ọgba ẹwọn, lẹyin ti ọlọpaa mu un pe o purọ gba owo lọwọ awọn abani-paarọ owo (Bureau De Change) ogoji, niluu Eko.
Owo naira ti iye rẹ to N39,098,100, $90,000 ati £12,550 ni wọn fi ẹsun kan Olajide Kareem ti awọn eeyan mọ si Seun Egbegbe, pe o lu jibiti rẹ.
Wọn lo gba a laarin ọdun 2015 si 2017, bẹẹ lo tun ni i ṣe pẹlu foonu olowo nla ti wọn n pe iPhone.
Gẹgẹ bi oun funra rẹ ṣe wi, apapọ ẹsun ti wọn fi kan an jẹ marundinlaadọta (45 counts), ṣugbọn ẹyọ kan lo pada gbe e de ọgba ẹwọn.
Kootu fi aaye beeli ẹgbẹrun marun-un naira silẹ fun un Seun Egbegbe nigba naa, pẹlu awọn oniduuro meji ti wọn jẹ ọga lẹnu iṣẹ ọba.
Egbegbe ko ri eto beeli naa ṣe, o wa lẹwọn titi di ọdun 2022, nigba ti kootu tu u silẹ, iyẹn lẹyin ọdun marun-un ati oṣu mẹjọ to ti lo lọgba ẹwọn.
Adajọ Oluremi Oguntoyinbo paṣẹ ẹwọn ọdun meje fun Seun Egbegbe tẹlẹ ni, pẹlu iṣẹ aṣekara. Ṣugbọn nigba ti akọsilẹ rẹ fi han pe o ti pẹ ju ninu ẹwọn, to n reti idajọ, o tu u silẹ pe ko maa lọ.
Ọjọ kẹwaa, oṣu keji ọdun 2017 ni igbẹjọ Egbegbe bẹrẹ, ko too jade lẹwọn l'oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.














