Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Bruno Labbadia, olùkọ́ni tuntun fún Super Eagles

Oríṣun àwòrán, nff
Ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, NFF, ti kede pe oun ti fọwọ si adehun pẹlu olukọni, Bruno Labbadia, lati di olukọni agba fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles.
Akọwe agba fun NFF, Mohammed Sanusi, sọ ni owurọ kutu ọjọ Iṣẹgun pe, igbimọ oluṣakoso ajọ naa ti buwọlu aba ti igbimọ to n mojuto idagbasoke ati idari gbe wa siwaju rẹ, lati yan Ọgbẹni Bruno Labbadia, gẹgẹ olukọni agba fun Super Eagles.
Bruno Labbadia ni olukọni kẹtadinlogoji ti yoo dari Super Eagles.
Taa ni Bruno Labbadia?
Ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 1966 ni wọn bi Bruno Labbadia, ni orilẹ-ede Germany.
O kawe gba iwe ẹri gẹgẹ bi oṣiṣẹ adojutofo.
Gẹgẹ bi agbabọọlu, o gba bọọlu fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Darmstadt 98, Hamburger SV, FC Kaiserslautern, Bayern Munich, FC Cologne, Werder Bremen, Armenia Bielefeld ati Karlsruher SC.
O ti ṣiṣẹ olukọni pẹlu Hertha BSC, VfL Wolfsburg, Hamburger SV, Bayer Leverkusen, ati awọn mii.
Bakan naa lo ni iwe aṣẹ ajọ FIFA gẹgẹ bi olukọni.
O gba ami ẹyẹ DFB-Pokal lọdun 1989 – 90, ati bundesliga ni 1993 - 94
Labbadia ni ọmọ orilẹ-ede Germany kẹfa ti yoo jẹ olukọni fun super Eagles - Karl-Heinz Marotzke (1970 ati 1974), Gottlieb Göller (1981), Manfred Höner (1988-1989), Berti Vogts (2007-2008) ati Gernot Rohr (2016-2021).
Ipenija nla ti Labbadi gbọdọ kọkọ mojuto ni kiakia ni lati mura Super Eagles silẹ fun ifẹsẹwọnsẹ Africa Cup of Nations qualifiers, pẹlu Benin Republic, eyi ti yoo waye lọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, niluu Uyo.
Omiran yoo tun waye pẹlu Rwanda ni ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an bakan naa, ni Kigali.
Ifẹsẹwọnsẹ mẹrin miran yoo tun waye ninu oṣu Kẹwaa ati oṣu Kọkanla.












