Bí Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Interpol ṣe mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Black Axe ní Naijiria

Ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to wọ iboju
    • Author, Charlie Northcott
    • Role, BBC Africa Eye
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri agbaye ti parapọ lati gbe ogun ti ọkan ninu ẹgbẹ okunkun ni iwọ-oorun Afirika, eyi ti wọn n pe ni Black Axe.

Operation Jackal III ni awọn ọlọpaa yii gunle ni awọn orilẹede kan laarin oṣu Kẹrin ati oṣu Keje ọdun 2024.

Iṣọkan fun gbigbe ogun ti ẹgbẹ okunkun waye nipasẹ ile-iṣẹ ọlọpaa agbaye ti Interpol, ti ọwọ si ti tẹ ọọdunrun eeyan to ni ajọsepọ pẹlu ẹgbẹ okunkun Black Axe ati awọn ẹgbẹ okunkun miiran.

Interpol pe ipalara nla ni akanṣe iṣẹ naa jẹ ni agbo iwa ọdaran ni Naijiria, ṣugbọn o ṣe ikilọ pe imọ ijinlẹ ati ibaṣepọ to ni l'agbaye ṣi mu ẹgbẹ okunkun naa jẹ ewu ni awujọ agbaye.

Bi awọn ọlọpaa se n mu awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun

Oríṣun àwòrán, Interpol

Fun apẹẹrẹ, awọn alaṣẹ orilẹ-ede Canada sọ pe ọwọ oun tẹ ipejọpọ awọn kan to n ko owo pamọ lọna ti ko ba ofin mu, eyi ti wọn lo ni ajọṣepọ pẹlu Black Axe. Owo naa ni wọn lo ju biliọnu marun-un Dọla lọ, lọdun 2017.

Oṣiṣẹ agba ninu ajọ Interpol to wa fun iwa ọdaran ni ẹka owo nina, Tomonobu Kaya sọ fun BBC pe oriṣiriṣi ilana to duro o re ni awọn ikọ naa fi n ṣe iṣẹ wọn.

Gẹgẹ bi abọ iwadii kan ti Interpol fi sita ni ọdun 2022, "Black Axe ati awọn ẹgbẹ okunkun mii ni wọn wa nidi iwa ibajẹ lilu eeyan ni jibiti lori ayelujara kaakiri agbaye ati awọn ẹsun mii ti o jọra.

Ọgbẹni Kaya sọ pe awọn ilana tuntun nipa fifi owo ransẹ ati cryptocurrency ni o bọ sọwọ awọn ẹgbẹ yii, ti wọn si ti wa di olokiki fun awọn itanjẹ ori ayelujara to n gba ọpọlọpọ-miliọnu dola.

O sọ pe “awọn ẹgbẹ ọdaran wọnyii lo kọkọ bẹrẹ si lo imọ ẹrọ igbalode - ti ọpọ awọn ileeṣẹ abanifoworanṣẹ kekeeke to n dide si mu ko rọrun fun wọn

Operation Jackal III ti ṣiṣẹ labẹlẹ fun ọpọ ọdun, ti wọn si ti gba owo toto $3m pada.

Bakan naa ni wọn ti apo asunwọn owo to le ni ẹẹdẹgbẹrin pa ni awọn ile ifowopamọ.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe ni wọn kẹkọ jade ni fasiti, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ lasiko ti wọn n kẹkọọ lọwọ.

Ẹgbẹ okunkun yii jẹ ibi ti awọn iwa ọdaran bii fifi eeyan ṣe owo ẹru, aṣẹwo, ati ipaniyan kaakiri agbaye.

Iwa-ọdaran ori ayelujara, nibi ti wọn ti n lu awọn ileeṣẹ ati eeyan ni jibiti, ni orisun gboogi ti owo n gba wọle fun ẹgbẹ okunkun ọhun.

Ọpọ igba ni awọn ọlọpaa ti ṣe akanṣe iṣẹ lati ọdun 2022.

Ọpọ ọmọ ẹgbẹ Black Ax ati awọn ọmọ ẹgbẹ onijagidijagan miiran ni ọwọ ti tẹ pẹlu irinsẹ ti wọn fi n ṣiṣẹ lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa se kọlu.

Aworan bi wọn se n wa nnkan lẹyin ti wọn se ikọlu

Oríṣun àwòrán, Interpol

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iṣẹ nyii ti fun ileeṣẹ ọlọpaa ni anfani lati ni ọpọ imọ nipa awọn ẹgbẹ okunkun naa, ti wọn si ti pin fun awọn akẹgbẹ wọn ni awọn orilẹede yooku.

"A nilo lati ni data ati lati ṣa awọn awari wa jọ lati awọn orilẹ-ede wọnyi lati ṣe iranlọwọ lati mọ ọna ti a lo gbe ogun ti iwa ibajẹ yii," Ọgbẹni Kaya sọ.

Pelu ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ọwọ ti tẹ, awọn amoye ni igbsgbọ pe igbesẹ ko ti to lati wu gbongbo ẹgbẹ okunkun ni iwọ oorun Afrika.

"A ni lati dena de awọn ẹgbẹ, ko si bi a se a le palẹ wọn mọ," Dokita Oluwole Ojewale, Alakoso Agbegbe iwọ-oorun Afirika lati Institute for Security Studies sọ fun BBC.

Orilẹeede Naijiria, bi ti ọpọ iwọde ti waye ni bi ọsẹ diẹ sẹyin, , jẹ ọkan ninu orilẹede ti ọrọ-aje ti o tobi julọ ni Afirika, ṣugbọn ọpọlọpọ eeyan bi 87 milionu lo n gbe pẹlu osi, gẹgẹ bii Banki Agbaye ṣe ṣalaye. Oun naa jẹ ọkan gboogi to jẹ igbanisiṣẹ akọkọ fun Black Axe.

Interpol sọ pe o n ṣe idanilẹkọ fun awọn alakoso Naijiria ati awọn oṣiṣẹ ọlọpaa. Ṣugbọn iwa ibajẹ, ati awọn ẹsun ti ajọsepọ laarin ẹgbẹ okunkun Black Axe ati awọn alaṣẹ , jẹ awọn idiwọ nla.

Dokita Ojewale sọ pe “Awọn oloṣelu gan-an lo n se onigbọwọ fun awọn ọmọkunrin wọnyi .

“Bi ijọba se ti ja ọpọ araalu kulẹ orilẹ-ede naa lo fa ti ọpọ eeyan fi fẹ darapọ mọ awọn ẹgbẹ [Black Axe].”

Pẹlu arọwọto agbaye lọwọlọwọ yii, Interpol's Jackal Operations ni ipilẹṣẹ wọn ni Ilu Ireland.

Lẹyin ọpọ ikọlu ileeṣẹ ọlọpaa nipasẹ Garda National Crime Bureau Crime Bureau (GNECB) ni ọdun 2020, ọwọ ba diẹ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe, eyi lo ṣokunfa bi ikọlu naa se tan ka.

"Wọn wa labẹ lẹ, ti wọn ko pariwo rara," Michael Cryan sọ, oṣiṣẹ GNECB, ẹni to lewaju ikọlu naa.

"Iye owo ti wọn gbe pamọ ni Ireland je ohun to yani lẹnu," O fi kun.

Aworan awọn foonu ti ọlọpaa gba jọ

Oríṣun àwòrán, Interpol

Àkọlé àwòrán, Interpol released a picture of mobile phones that were seized as part of a raid in South Africa

Ọlọpaa ṣe idanimọ awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun kan ti wọn ajọsepọ pẹlu ẹgbẹ okunkun Black Axe ni Ilu Ireland ati pe wọn ti wọn ọpọ eeyan mii fun ẹsun jibiti ati iwa-ipa ori ayelujara.

Det Supt Cryan sọ pe “Awọn adigunjale ile-ifowopamọ ti pari iṣẹ wọn pẹlu ẹrọ kọnputa agbeka,” Det Supt Cryan sọ.

O siro €200m ($220m; £170m) ti wọn ti ji lori ayelujara ni Ireland ni odun marun un seyin..

"Eyi kii ṣe ẹsun lasan … Awọn eeyan yii lati mọ pe igbesẹ awọn yii lewu pupọ,” o sọ.

Isẹ Ileeṣẹ ọlọpaa Ireland laarin Oṣu kọkanla ọdun 2023 ṣafihan pe cryptocurrency – eyi ti wọn fi n ranṣẹ lati ori ayelujara kaakiri agbaye – ti di ohun elo patakiti ẹgbẹ okunkun Black Axe n lo fi ji owo pamọ.

Owo to ju € 1m ni awọn ohun-ini crypto ni wọn gba lakoko iṣẹ kan.

Interpol ti se ifilọlẹ imọ ẹrọ tuntun lati ti fi gbe ogun ti awọn iwa yii, ryi ti wọn pe ni Global Dekun Intervention of Payments (I-GRIP).

Imọ ẹrọ yii, eyi ti o jẹ ki awọn alaṣẹ ni awọn orilẹ-ede yooku gbe ẹsẹ le awọn apo owo kaakiri agbaye nji ẹsẹ kẹsẹ, ti wọn si fi da owo toto $ 40m kan duro ti wọn fẹ fi gba okowo Singapore kan ni oṣu to kọja.

Ọgbẹni Kaya ti Interpol sọ pe imọ-ẹrọ bii eyi yoo jẹ ki o nira fun awọn ọdaran lati gbe owo kọja awọn aala pẹlu aibikita.

Igbiyanju pataki kan wa ni ọna lati ṣajọ ati pinpin imọ lori Black Ax ati awọn ẹgbẹ Iwo-oorun Afirika miiran nipasẹ awọn ọlọpaa kaakir agbaye.

“Ti a ba le ṣajọ awọn data yii a le gbe igbesẹ,” o sọ.

Àkọlé fídíò, Black Axe: Ninu ẹgbẹ okunkun Black Axe