Ó má ń wù mí kí n kọ́lé sí Lekki bíi àwọn ẹgbẹ́ mi, àmọ́ àlá àti ìgbà kékeré kò jẹ́ - Ibrahim Chatta

Àkọlé fídíò, Láti kékeré mi ní mó tí sọ fún ará mi pé èmi náà yóò ní ibí kan tí wọ́n ti ń ṣe sinima
Ó má ń wù mí kí n kọ́lé sí Lekki bíi àwọn ẹgbẹ́ mi, àmọ́ àlá àti ìgbà kékeré kò jẹ́ - Ibrahim Chatta

Gbajugbaja oṣere tiata, Ibrahim Chatta ṣo pe gbogbo igba lo ma n wu oun lati ṣe awọn nkan meremere bi ile kikọ, gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ rẹ yooku.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBc ni agba oṣerekunrin naa ti sọ pe akanṣe iṣẹ kikọ abule nla kan ti awọn eeyan yoo ti le maa ya sinima, ni ko fi aaye gba oun.

Ọgbẹni Chatta ṣalaye pe lati igba kekere ni oun ti ni ala lati kọ iru abule bẹẹ ti awọn oṣere akẹgbẹ rẹ yoo ti ma ni anfaani lati se ere sinima wọn ni ilana aye atijọ.

O ni, nigba to oun dawọ le kikọ Africhatta, abule to kọ́ fun ere ṣiṣe, ọpọ ibeere lo ni oun bi ara oun pe ṣe nnkan yii lo kan ninu ọrọ oun.

Agbala Africhatta, eyi to wa niluu Oyo, jẹ ọkan lara aye to wa fun awọn oṣere lati se sinima wọn, to si pese awọn ohun eelo ti yoo mu ko da bi aye atijọ.

Awọn ile alamọ, ẹṣin, ọja abaye ati awọn ohun aaye atijọ lo wa ni Africhatta.

Bakaa ni o tun kọ ile itura fun awọn to ba wa ya sinima lati ni aye to dara fun oorun lẹyin ti wọn ba pari iṣẹ wọn

Ibrahim Chatta

Bawi ni o ṣe bẹrẹ kikọ ile sinima naa?

Agbaala Africhatta niluu Oyo Alaafin

Oríṣun àwòrán, Instagram/IbrahimChatta

Gẹgẹ bi a ṣe mọ pe iṣẹ irinajo ni iṣẹ sinima, Ibrahim Chatta ni oun lọ ṣiṣẹ ni ilu kan fun ọpọlọpọ ọjọ, ti oun si fi owo nla gba ile itura lati sun.

“Aye ti a wa yii gan-an-gan, nigba ti mo fẹ raa, mo fẹ ṣiṣẹ fun bii ọjọ mejilelogoji, lẹyin iṣẹ yẹn mo fẹ bẹrẹ iṣẹ mii to maa to bii oṣu mejidinlogun.

“Mo wa ro pe, ṣe aduru oṣu mejidinlogun, owo ti yoo bọ ni ara mi fun yara temi nikan, mo dẹ maa n rera nipa ibi sisun lalẹ, ibi ti maa ki ori mi bọ.

“Mo wa wo pe o da, ṣugbọn ti mo ba san owo ile itura fun ọjọ mejilelogoji lẹyin oṣu kan, ma tun san owo oṣu mi.

“Mo wa siro owo yẹn pe o pọ gan an, mo wa ni ti mo ba sun ibi nkọ?

“ Mo wa pe awọn onilẹ adugbo yii wa pe, ẹ fun mi ni aye kan ti mo fẹ ra, ti mo ba n ṣiṣẹ ninu ọdọ yin, ma maa sun si, yoo din mi ni owo.

“Mo wa ni ti mo ba pari iṣẹ tan nkọ, ṣe ma kan fi ilẹ lẹ ni, mo ni ma kọ ile kan, ti ma si ma mojuto nnkan oṣin pe ilẹ ko sha gbudọ ṣofo.

Eeka ilẹ meji ni Chatta kọkọ ra, to si bẹrẹ si ni sin ẹṣin ati awọn ẹranko miran nibẹ.

Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni kọ oriṣiriṣi ile atijọ, ati igbalode fun iṣẹ sinima yiya.

Lara awọn ere sinima to ti jẹ anfaani abule naa ni Jagunjagun ati Bashorun Gaa.

Yatọ si sinima ṣiṣe, abule Africhatta tun jẹ ibudo ti ẹbi le lo fun isinmi ati irinajo igbafẹ.

"O maa n dun pe o yẹ ki n ti kọja ibi yii, ka ni mo bẹrẹ rẹ ni akoko ni"

Aworan Ibrahim Chatta

Ibrahim Chatta ni o maa n dun oun pupọ pe oun ko tete gbe igbesẹ lori nini aye sinima to jẹ ti oun sugbọn oun gbagbọ pe oorun to wa nita si to aṣọ ọ gbẹ.

“Nigba ti mo kọkọ bẹrẹ, igba mii wa ma da joko wi pe ki lo n ṣe yii?

“Gbogbo ẹgbẹ rẹ n kọ ile si Lekki. O maa n wu emi naa, orisirisi nnkan wa ti a maa n ṣe ti o maa n wu mi.

“Ṣugbọn ninu ohun ti wọn ba n sọ, lo maa n mu mi tẹsiwaju.

“Mo ṣe awari pe ẹ pe lati tan iṣoro, eeyan le pa owo lati ibẹ.