Ọlọ́pàá pa lára àwọn ọmọ ìjọ wa nílùú Abuja - Shiites

Olori ijọ IMN, Ibrahim El-Zakzaky.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Olori ijọ IMN, Ibrahim El-Zakzaky.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọ Islamic Movement of Nigeria (IMN) ti awọn eeyan mọ si Shiites, ti sọ pe awọn ko kọlu awọn ọlọpaa lọjọ Aiku, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024, niluu Abuja.

Shiites sọ pe awọn ọlọpaa gan-an ni wọn da awọn lọna ti wọn si yinbọn mọ awọn.

Malam Abdullahi Mauhammad Musa, ọkan lara awọn olori ẹgbẹ naa lo sọ eyi di mimọ.

O ni ijọ Shiites ti kede tẹlẹ pe awọn yoo wọde gẹgẹ bi iṣe wọn lọdọọdun.

" A n lọ si ọja Wuse ni nigba ti awọn ọlọpaa bẹrẹ si i yinbọn si wa. Awọn kan ti wa niwaju tẹlẹ, igba ti a tun de Berger, awọn ọlọpaa ibẹ naa tun bẹrẹ si i yinbọn fun wa, wọn si pa ẹnikan.

‘’A o di ọna pe ki ẹnikẹni ma kọja, wọn kan ṣina ibọn fun wa ni, oni kọ ni wọn ti n pa wa bẹẹ. Awọn ọlọpaa lo pa eeyan, awọn ijọ wa ko gbe nnkan ija lọwọ’’

Ikọlu awọn agbofinro ati ijọ IMN ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Eyi to lagbara ju ninu ikọlu naa waye ni 2015, nigba ti awọn agbofinro pa olujọsin pupọ ninu awọn Shiites, lasiko ti wọn n ja fun olori wọn, Ibrahim El-Zakzaky.

Ni 2019, ile-ẹjọ fofin de ijọ Shiites pẹlu ẹsun pe ẹgbẹ onijagidijagan ni, wọn si tun n ko awọn eeyan jọ lati lodi si ofin .

Ọlọ́pàá méjì kú, mẹ́ta míì dákú níbi ìkọlù tó wáyé láàrin ẹgbẹ́ mùsùlùmí Shiites àtàwọn ọlọ́pàá l’Abuja

Aworan ọkọ to jona

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja ti i ṣe olu ilu orilẹede Naijiria ti sọ pe ẹgbẹ Islamic Movement of Nigeria ti ọpọ mọ si Shi'ite ti ṣe ikọlu si ọlọpaa marun un niluu Abuja lọjọ Aiku nibi ti ọlọpaa meji ti dero ọrun tawọn mẹta mii si daku rangbọndan.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja, SP Josephine Adeh, Anipr, fi sita ni o ti ṣalaye wi pe orita Wuse niluu Abuja lawọn ọlọpaa naa wa tawọn ẹgbẹ Shiites ti wọn jẹ ọmọlẹyin Sheik Ibrahim El -Zakzaky ti ṣe ikọlu si wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

SP Adeh sọ ninu atẹjade naa pe ọlọpaa mẹta to daku nibi ikọlu ọhun ti n gba itọju nile iwosan bayii.

Bakan naa ni o tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ Shiites tun dana sun ọkọ ọlọpaa mẹta.

‘’Lẹnu iṣẹ lawọn ọlọpaa yii wa tawọn ọmọ ẹgbẹ Shiites ti ṣe ikọlu si wọn lagbegbe Wuse.

Ọpọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Shiites yii lo ko ada ati ọbẹ lọwọ, nigba ti awọn mii ninu wọn ko ado oloro agbelẹrọ dani.

Ni bayii, ọwọ ti tẹ awọn kan ninu awọn to ṣiṣẹ laabi yii,’’ SP Adeh ‘salaye.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ilu Abuja sọ pe kọmiṣọna ọlọpaa, CP Benneth C.Igweh ti bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu naa.

SP Adeh ni kọmiṣọnna ọlọpaa ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn ti ọwọ ti tẹ ni yoo foju wina ofin.

Ẹwẹ, iwe iroyin Daily Trust tun sọ pe ọkunrin kan to jẹ oniṣowo naa ku nibi iṣẹlẹ ọhun.

Iwe iroyin naa fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Amiru ni ọta ibọn ba laya nigba tawọn ọlọpaa ti n le awọn oluwọde ẹgbẹ Shiites.

O ṣoju mi koro kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ pe wọn gbe ọkunrin naa lọ sile iwọsan, amọ, eleeru ti sun igi.

Awọn musulumi Shiites ni a gbọ gbe wọn n ṣe iwọde ti wọn pe orukọ rẹ ni Arbaeen eyi to waye ni ogoji ọjọ lẹyin ipade Ashura.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post