Iṣẹ́ márùn ún tó lè sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀ lọ́jọ́ iwájú àtàwọn iṣẹ́ tí yóò parun láìpẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Oleg Karpyak
- Role, BBC News Ukrainian
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ọpọlọpọ iṣẹ ti awọn eeyan n ṣe lode oni ni opin yoo de ba lọjọ iwaju, nnknan meji pataki lo si le ṣokunfa eyii gẹgẹ bii iwadii kan ti ajọ World Economic Forum ṣe.
Ohun akọkọ ni idagbasoke imọ erọ, ti ekeji si jẹ bi awọn orilẹede ṣe n gabjumọ ohun ti wọn n pe ni “green economy.”
Wọn ni kii ṣe iyatọ kekere ni imọ ẹrọ bii ‘AI’ yoo mu ba bi awọn eeyan ṣe n ṣiṣe lọjọ iwaju.
Amọ iroyin ayọ to wa nibẹ ni pe bi imọ ẹrọ ati ọlaju tuntun yii yoo ṣe fopin si awọn iṣẹ kan naa ni yoo tun pese awọn iṣẹ tuntun mii.
Awọn oluwadii World Economic Forum sọ pe nnkan bii ida mẹrin bi awọn eeyan ṣe n ṣiṣẹ lonii ni iyipada yoo ti de ba ni nnkan bii ọdun marun un si asiko yii.
Fun idi eyii, ẹnikẹni to ba fẹ ṣaṣeyọri nidi rẹ gbọdọ maa ṣe idanilẹkọọ ko si ni imọ kun imọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn iṣẹ to dara ju

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ iwaju, awọn onimọ gbagbọ pe iṣẹ ti yoo pa owo wọle julọ ni eyii ti wọn ko pọ si ẹka ‘STEM.’
STEM ni awọn imọ to wa labẹ ẹka sayẹnsi, imọ ẹrọ ati iṣiro.
Nitori naa ti o ba n woye awọn imọ ti ọmọ rẹ gbọdọ fi oju si daadaa nile ẹkọ, awọn ni iṣiro, imọ ijinlẹ kọmputa atawọn imọ ijinlẹ sayẹnsi miran.
Imọ miran to tun dara ni eyii ti wọn pe ni ‘analytical thinking.’
Amọ ṣa, eyii n tumọ si pe ọmọ rẹ ni lati jina si awọn nnkan to le gba akoko rẹ bii ere aṣeju ati lilo ọpọlọpọ akoko lori ayelujara.
Wọn ni kikọ nipa ede Gẹẹsi naa ko buru.
Imọ nipa ibaraẹnisọrọ yoo wulo fun awọn to ba fẹ ya si ẹka AI lọjọ iwaju.
Nitori ko si bi awọn ẹrọ ṣe le gbọn to, awọn eeyan yoo nilo lati maa ba ara wọn sọrọ ki wọn si maa ba ara wọn ni irẹpọ, eyii to ṣoro fun ẹrọ lati ṣe laye ara rẹ.
Gẹgẹ bi iroyin kan lati ọwọ ileeṣẹ LinkedIn, ibaraẹnisọrọ jẹ ọkan gboogi lara awọn imọ to wulo julọ laye ode oni.
Imọ ẹrọ tuntun
Lai si aniani, imọ ‘information technology’ ni yoo leke tente lara awọ iṣe ti yoo ja owo julọ lọjọ iwaju.
Bẹẹ naa ni imọ AI ko ni gbẹyin, yoo si fun ọpọ eeyan lanfani lati pa ọpọ owo wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lapapọ, awọn iṣẹ to ni ṣe pẹlu AI yoo niyi lọjọ iwaju.
Amọ awọn onimọ ti gba awọn eeyan nimọran ki wọn ma ri awọn ẹrọ AI bii ohun to fẹ gba isẹ lọwọ wọn, bikoṣe eyii ti yoo mu ki isẹ wọn rọrun.
Awọn iṣẹ mii ti yoo tun lamilaka ni ‘cyber security’ ati imọ ‘blockchain.’
Awọn iṣẹ ti yoo mu adinku ba lilo epo bẹntiro
Awọn iṣẹ kan ti yoo din lilo epo bẹntiro ku ti wọn n pe ni ‘green jobs’ naa ti bẹrẹ si n gberasọ lawọn orilẹede kan.
Ajọ World Economic Forum sọ pe awọn iṣẹ naa ni ọjọ iwaju ọpọ iṣẹ lagbaye.
Awọn orilẹede to ti bẹrẹ si n ṣe eyii ni awọn to ti dagba soke daadaa, amọ ilẹ mii bii Japan ati China ti n tẹle wọn lẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn isẹ yii le jẹ nipa eto ọrọ aje, imọ sayẹmsi, oṣelu tabi iṣẹ to ni ṣe pẹlu ọrọ ayika, nibi ti wọn yoo ti maa lo batiri eyii ti kii yọ eefin si ayika.
Bakan naa ni ọrọ ọhun kan awọn to n ya ile tabi bi arin ilu yoo ṣe ri.
Awọn oṣiṣẹ eto ilera
Nibi ti aye n lọ bayii, ọpọ ni yii ilo awọn oṣiṣẹ eto ilera.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun idi eyii, iṣẹ awọn eleto ilera ko ni kuta lọjọ iwaju.
Awọn dokita yoo nilo lati maa kọ nipa imọ ẹrọ ati bi wọn yoo ṣe lo awọn ẹrọ tuntun.
Imọ AI yoo tun wulo ni ẹka eto ilera.
Awọn oniṣe ọwọ
Awọn oniṣe ọwọ bii awọn to n tun ọkọ ayọkẹlẹ ṣe, awọn to n kọ ile atawọn to n ṣisẹ mọnamọna ko ni kuta lọjọ iwaju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ si awọn wọnyii, awọn agbẹ yoo ni ọpọ ojuṣe laisko naa pẹlu.
Awọn iṣẹ ti yoo parun
Awọn iṣẹ kan wa ti yoo parun bi aye ṣe n laju si.
Eredi iparun awọn isẹ ọhun ko ni ṣẹyin bi ẹrọ igbalode yoo ṣe maa mu nnkan rọrun, lara awọn iṣẹ ti yoo parun ni
- Awọn to n da awọn onibara lohun nile itaja
- Awọn to n ṣakoso ọọfisi (ọpọ lo n ṣiṣẹ lati ile bayii)
- Awọn to n tẹ iwe lori kọmputa tabi awọn atumọ ede
- Awọn oniṣiro
- Awọn to n ṣiṣẹ ti ẹrọ rọbọti le ṣe lai sinmi
Awọn to n sọ itan
Iṣẹ kan gboogi ti yoo niyio lọjọ iwaju ni awọn to n sọ itan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ti yoo ṣoro ki iṣẹ wọn tete wa sopin ni awọn onkọwe, awọn akewi, awọn oṣere tiata, olorin atawọn elere idaraya mii.












