Ọwọ́ ọlọ́pàá tí tẹ afurasí tó ṣekú pa èèyàn mẹ́ta níbi àjọ̀dún

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ọlọpaa orile-ede Germany ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin afurasi kan to ṣeku pa eeyan mẹta, to si tun ṣe awọn mẹjọ miran leṣe pẹlu ọbẹ, niluu Solinge.
“Ọkunrin ti a ti n wa fun gbogbo ọjọ lọwọ wa ṣẹṣẹ tẹ, to si ti wa ni ahamọ wa,” Herbert Reul, minisita feto abẹle ni Ariwa Rhine-Westphalia, sọ fun ileeṣẹ amọhunmawora ARD lọjọ Abamẹta.
Ko ṣalaye lẹkunrẹrẹ, ṣugbọn ileeṣẹ iroyin ayelujara ti Bild and Spiegel kọ iroyin pe afurasi naa to wa ninu aṣọ to kun fun ẹjẹ lo jọwọ ara rẹ silẹ
Ọkunrin meji, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ati ẹni ọdun mẹtalelọgọta, to fi mọ iya agbalagba ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni wọn gun pa lasiko ajọdun, eyi ti Chancellor Olaf Scholz ṣapejuwe gẹgẹ bi “iṣẹlẹ aburu”.
Ọgbẹni Reul, minisita agbegbe naa sọ fun iroyin ARD Tagesthemen pe, oun ni ọkunrin “ti a ti n furasi”.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọrọ abẹle naa jẹ ko di mimọ pe funra ọkunrin ọhun lo jọwọ ara rẹ.
Eyi ni igbakẹta ti wọn yoo fi kele ofin gbe awọn eeyan lọjọ Abamẹta, lori ikọlu fifi ọbẹ gun awọn eeyan to jẹ kayeefi ni Germany.
Ṣaaju, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti mu ọkunrin kan si agbegbe to wa fun awọn to nilo aabo (refugee centre) to sunmọ ibi iṣẹlẹ ikọlu naa.
Bild kọ iroyin pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo (SEK) kọlu buba naa, nibi ti ọwọ ti tẹ afurasi ọhun.
O ni ile naa wa ni iwọn ọọdunrun mita (300m, iyẹn 984ft) si Fronhof – aarin gbungbun ọja Solingen nibi ti wọn ti gun awọn eeyan lalẹ ọjọ Ẹti.

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/Shutterstock
Wọn mu ọkunrin naa lẹyin bi wakati diẹ ti wọn mu ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun kan. Awọn alakoso sọ pe kii ṣe afurasi ti wọn n wa - ṣugbọn wọn fẹsun kan an wi pe o mọ nipa ikọlu to ṣẹlẹ.
Ẹgbẹ ẹlẹsin Islam kan lọjọ Abamẹta gba idalẹbi ikọlu naa.
Wọn ko tete fi ẹri silẹ, ko si foju han nipa iru ibaṣepọ ti wọn ni pẹlu ẹni to ṣe ikọlu naa.
Ọkunrin naa lo kan deedee bẹrẹ sii gun awọn eeyan lai woju ẹnikẹni nibi ajọyọ ayẹyẹ idasilẹ ọtalelọgọta (650years) ọdun ti ilu Solingen.
Ohun to ṣẹlẹ ninu gbagede lọjọ naa jẹ eyi to “ba ni lẹru” pupọ, eyi to ṣoro lati ṣawari ẹni to ṣiṣẹ buruku naa, awọn ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
Wọn tun fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin naa gbero lati gun awọn eeyan lọrun ati ikọfun.
Ọkùnrin kan gún èèyàn mẹ́ta lọ́bẹ pa níbi àjọ̀dún

Oríṣun àwòrán, AP
Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ si ni wa arakunrin kan to gun eeyan mẹta lọbẹ pa tí awọn mẹjọ miran si tun farapa yannayanna nibi ajọdun kan to waye niluu Solingen lorilẹede Germany.
Iṣẹlẹ ọhun lo waye lasiko ayẹyẹ kan to waye niluu naa nirọlẹ ọjọ Ẹti to kọja. Iroyin sọ pe awọn agbofinro ti n wa arakunrin to ṣe iṣẹ laabi naa bayii
Ileeṣẹ iroyin kan ni orilẹede Germany, Bild sọ pe ọkunrin kan ti wọn ko da mọ lo ṣa dede bẹrẹ si ni gun awọn eeyan lọbẹ ẹnikan to n kọja lọ.
Wọn ti bẹrẹ sii wa ọkunrin naa bayii, pẹlu bi awọn ọkọ baluu agberapa ṣe n fo kaakiri ilu lati mọ ibi to gba.
Ilu naa ni iroyin fi to wa leti pe wọn n ṣayẹyẹ idasilẹ ọdun ẹgbẹta le laadọta (650years) ti wọn da a silẹ.
Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye gan an?
Awọn alakoso ilu naa ti sọ fawọn eeyan lati kuro lagbegbe ọja Fronhof, pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe ṣagbekalẹ eto lati rọwọ to afurasi ọhun, lẹyin ikọlu to waye ni deedee agogo mẹwaa alẹ (21:00 BST).
Awọn ikọ iṣẹlẹ pajawiri nibi ikọlu naa la ri ti wọn n ṣe itọju awọn to farapa, ileeṣẹ iroyin sọ ọ.
Lẹyin rẹ lawọn ọlọpaa gbe ogoji ọkọ oluwadii dide lati ṣawari afurasi naa, gẹgẹ bi Bild ṣe kọ ọ jade.
Awọn oṣiṣẹ aabo ti wọn pe SEK (Special Task Force) officers ni wọn n dari awọn ọkọ ọhun.
Wọn ti di awọn ọna, wọn si ti sọ fawọn olugbe agbegbe naa lati duro sinu ile wọn, pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe bẹrẹ iwadii wọn.
Philipp Müller, ọkan lara awọn awọn ṣagbatẹru ayẹyẹ naa sọ pe awọn ikọ ayẹyẹ ọhun n lo n sare doola ẹmi eeyan mẹwaa, ileeṣẹ iwe iroyin Solinger Tageblatt kọ ọ jade bẹẹ.
“O ba awọn eeyan lẹru, ṣugbọn alaafia ni wọn fi kuro ni gbagede,” Ọgbẹni Müller ṣalaye.
Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, Lars Breitzke sọ fun iwe iroyin ọhun pe oun mọ pe nnkan ko fararọ nigba toun ṣakiyesi pe oju akọrin ti yipada lori itage.
“Lẹyin naa ni ẹnikan ṣubu nitosi mi,” o sọ bẹẹ.
Afurasi ọhun ni igbagbọ wa pe o gun ẹni naa ni ọrun, ileeṣẹ iroyin German kọ ọ jade.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Alexander Kresta ninu ọrọ rẹ ti ileeṣẹ iroyin German gbe jade, lo ti sọ pe “ohun ti a ṣi lero bayii ni pe ẹnikan ṣoṣo ni” lẹyin to ti ba oriṣiriṣi eeyan sọrọ.
Awọn ọlọpaa naa tun sọ pe awọn “ko ni imọ kankan nipa ibi to wa”, tabi mọ bo ṣe ri.
Ninu atẹajde to gbe soju opo Facebook, Mayor ti Solingen, Tim Kurzbach sọ pe: Ni aṣalẹ yii, gbogbo awa ti a wa ni Solingen ni ọkan wa poruru, to si dẹru ba wa pẹlu ibanujẹ nla. A fẹẹ ṣajọyọ ilu wa papọ, ṣugbọn ni bayii inu ikẹdun la wa fun awọn to ti ku ati awọn to farapa.
“O ba mi lọkan jẹ wi pe ikọlu waye ni ilu wa. Omije bọ loju mi nigba ti mo ronu nipa awọn ti a padanu. Mo gbadura fun awọn to ṣi n jijakadi fun ẹmi ara wọn. Paapaa julọ aanu mi lọ sọdọ awọn ti wọn ni imọ iriri yii, aworan yoo ti jẹ ẹru nla fun wọn.”
Nigba to n ba BBC sọrọ lalẹ ọjọ Ẹti, igbakeji olootu Solinger Tageblatt, Björn Boch jẹ ko di mimọ pe “ọjọ mẹta gbako lo yẹ ki wọn fi ṣajọyọ ọhun, ti wọn si n reti ẹgbẹrun marundinlọgbọn eeyan lalaalẹ.
“Niṣe ni wọn kan ko awọn eeyan jọ niluu yii,” o sọ bẹẹ, to si ṣagbelewọn pe “awọn ẹgbẹrun diẹ eeyan” ni wọn wa nibi ayẹyẹ ọjọ Ẹti ọhun.
Wọn ti wa fopin si ayẹyẹ ọhun.
Solingen – ilu to wa lẹkun ariwa Rhineland-Westphalia, to si gbajumọ fun iṣẹ irin (steel industry) - ẹgbẹrun lọna ọgọjọ lawọn eeyan to n gbe nibẹ. O jinna ni maili (25km) mẹẹdogun si Düsseldorf ati ariwa ila-oorun Cologne.















