Ki ló fa gbas-gbos láàrín Naijiria àti South Africa tí wọ́n fi ń pe ọkọ̀ láti orílẹ̀èdè kan sí òmíràn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ talo lajulọ kan ti waye laarin awọn ọdọ ọmọ Naijiria ati South Africa lori ayelujara ninu eyii ti wọn ti n pe awọn awakọ lati gbe wọn bo tilẹ jẹ wọn ko nibi kankan lati lọ.
Ija na bẹrẹ lasiko ti awọn ọmọ South Africa n pe awọn awakọ Bolt ni Naijiria pe ko gbe awọn lọ irinajo amọ ti wọn yoo wọgile irinajo naa lẹyin ti awakọ Bolt ọhun ba ti kurọ nibi to wa lati lọ ba ẹni to fẹ gbe, lai mọ pe ọna jinjin rere ni South Africa ni ẹni to pe oun wa.
Eredi igbesẹ ọhun ko ṣẹyin ọna ati mọọmọ fi iya jẹ awọn awakọ Bolt ni Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọwọngogo epo n bẹ lode ni Naijiria, bẹẹ ni ati ri epo naa ra gan tun ti di wahala.
Amọ lẹyin ti ọkunrin kan lati South Africa kede ọrọ naa lori ikanni X rẹ lawọn ọmọ Naijiria yari, ti awọn naa si bẹrẹ si n pe awọn awakọ ni South Africa, lati mọọmọ fi akoko awọn naa ṣofo.
Yatọ si awọn awakọ ti wọn n pe lati Naijiria ni South Africa, awọn ọmọ Naijiria tun n ra awọn nnkan elo ile bii tẹlifiṣọn, ẹrọ to n fọ aṣọ, ati bẹẹ lọ lọna ati gbẹsan.
Wayi o, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ri ọrọ naa bi apara lasan, ọpọ awon mii woye pe iṣẹ oojọ awọn ẹni ẹlẹni ni apara naa n ṣe ipalara fun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5
Ki ni Bolt sọ?
Ileeṣẹ akero Bolt ti sọ pe oun ti fofin de akanti gbogbo awọn to lọwọ ninu apara naa.
Wọn tun ti wọgile anfani lati pe awakọ lati orilẹede kan si omiran, eyii to jẹ eku ẹda to mu ki ijọgbọn naa rọrun fun awọn to lọwọ ninu rẹ.
Ọkan lara awọn adari Bolt, Yahaya Mohammed ni “a mọ ipa ti ọrọ naa ti ko lara awọn awakọ wa ni Naijiria ati South Africa, afojusun wa ni lati ri pe ko si wahala kankan, ati pe awọn eeyan n ba wa dowopọ pẹlu irọrun.”
Ifigagbaga laarin Naijiria ati South Africa
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ifigagbaga yoo maa waye laarin Naijiria ati South Africa.
Lara awọn ibi ti wọn ti maa n gbena woju ara wọn ni eto oṣelu, orin kikọ ati ere idaraya.
Fun apẹrẹ, gbogbo igba ti ifẹsẹwọnsẹ ba waye laarin Naijiria ati South Africa lo maa n gbona girigi.
Ni ti orin kikọ nkọ? Awọn ohun to ti fa ariyanjiyan laarin orilẹede mejeji ni awọn orin bii Amapiano, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wayi o, awọn ọmọ Naijiria maa n ri ara wọn gẹgẹ bii ẹgbọn agba si south Africa nilẹ adulawọ.
Amọ o jọ bii ẹni pe orilẹede mejeji nilo ibaṣepọ to da mọran laarin ra wọn wọn fun idagbasoke to lamilaka.