Mínísítà tó gbéná wojú Ààrẹ Eritrea kú sẹ́wọ̀n

Berhane Abrehe

Oríṣun àwòrán, United Nations

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita eto iṣuna orilẹede Eritrea nigba kan ri, Berhane Abrehe, ti ku sinu ọgba ẹwọn.

Awọn ẹbi oloogbe ọhun, to jẹ ọkan gboogi lara awọn to maa n gbena woju Aarẹ orilẹede naa lo fi ikede ọhun sita.

Fun ọpọ ọdun ni ẹni ọdun mọkandinlọgọrin naa fi sin orilẹede ọhun gẹgẹ bii minisita eto iṣuna amo wọn yọ ọ bii jiga lẹyin ede aiyede to waye laarin oun ati Aarẹ Isaias Afwerki.

Ọdun mẹfa lẹyin naa ni wọn fi si ọgba ẹwọn lẹyin to juwe Aarẹ ilẹ naa bii ‘Baṣọrun Gaa’ to gbọdọ kọwe fi ipo silẹ.

Awọn mọlẹbi rẹ ṣalaye fun BBC pe ijọba lo fi to awọn leti pe o ti jade laye.

Ijọba ilẹ naa ti kede pe iboji ti wọn maa n sin awọn eekan ilẹ naa si ni wọn yoo sin oloogbe ọhun si.

Wayi o, ijọba ko tii gbe oku rẹ fun awọn ẹbi rẹ, bẹẹ ni ko mẹnuba bi iku rẹ ṣe waye.

Wọn ko gbe lọ sile ẹjọ, bẹẹ ni ko yọju siwaju adajọ kankan ki ijọba ilẹ naa to fi si ọgba ẹwọn to ku si.

Lati ọdun 1991 ti Aarẹ Isaias Afwerki ti gba iṣakoso ilẹ naa, ko ṣe eto idibo, bẹẹ ni ko gbe agbra silẹ.

Isaias Afwerki tun fofin de awọn ẹgbẹ oṣelu, ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan atawọn ileeṣẹ iroyin ti kii ṣe ti ijọba.

Lẹyin ọdun mejila ti oloogbe naa ti n ṣe minisita fun Aarẹ Isaias Afwerki ni ija wọn bẹrẹ.

Ija naa waye latari pe o rọ Aarẹ ọhun ko maa jẹ ki gbogbo araalu mọ bi awọn ṣe n n owo ilu.

Lẹyin iwe rẹ to kọ, ninu eyii to ti juwe Aarẹ Aarẹ Isaias Afwerki gẹgẹ bii Basorun Gaa ni wọn fi si ọgba ẹwọn to ti jade jade laye yii.