Olùwọ́de #EndSARS mẹ́fà gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́rin ní àtìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileẹjọ Majisreeti agba kan lagbegbe Ikẹja ni ilu Eko ti da ẹbi fun awọn eeyan mẹfa kan ti wọn n jẹjọ fun dida omi alaafia ilu ru lasiko iwọde ##ndSARS to waye lọdun 2020.
Lẹyin to dawọn lẹbi tan ni adajọ to gbọ ẹjọ naa da wọn silẹ ki wọn maa lọ si ile wọn.
Awọn olujẹjọ naa: Daniel Joyinbo (ẹni ọdun mọkanlelọgbọn), Adigun Sodiq (ẹni ọdun mejidinlọgbọn), Kehinde Shola (ẹni ọdun mejilelọgbọn), Salaudeen Kamilu (ẹni ọdun mọkandinlọgbọn), Sodiq Usseni (ẹni ọdun mẹtalelọgbọn), and Azeez Isiaka (ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn) ati Azeez Isiaka ti kọkọ ke sinile ẹjọ naa pe ko gba awọn laaye lati gba ẹbu wọn lẹbi lẹyin ti wọn ṣe adehun gba idalẹbi ki idajọ rẹ le rọrun (plea bargain) pẹlu ijọba ipinlẹ Eko to pe wọn lẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin to gbe awijare wọn yẹwo, Adajọ majisreeti Bọla Ọṣunsanmi da wọn lẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, amọṣa o ki wọn nilọ o si tu wọn silẹ pe ki wọn maa lọ lalaafia.
O ni ni wọn igba ti wọn ti lo nnkan bii ọdun mẹrin ni atimọle, iyẹn naa to gẹgẹ bi ijiya ẹṣẹ ti wọn ṣẹ.















