Ó lé ní èèyàn 1,000 tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ìwọ́de ìlú le – Amnesty International

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International, ti sọ pe o le ni ẹgbẹrun kan ọmọ Naijiria ti ọlọpaa fi si atimọlẹ lẹyin ti wọn kopa ninu ifẹhonuhan ilu le to waye ni ibẹrẹ oṣu yii.
Amnesty International sọ pe inu ọgba ẹwọn lawọn eeyan naa wa kaakiri Naijiria.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ lo ti fi ikede naa sita.
Ti ẹ ko a gbagbe, lati ọjọ kinni si ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ni ifẹhonuhjan ilu le milẹ titi kaakiri Naijiria.
Lara awọn ibi ti iwọde naa ti halẹ julọ ni iha ariwa, nibi ti awọn kan lara awọn oluwọde ti gbe asia orilẹede Russia lọwọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn to pinlẹ iwọde ọhun sọ pe ko ni si wahala lati ọwọ awọn oluwọde, rogbodiyan bẹ silẹ ni ariwa Naijiria, nibi ti awọn oluwọde ti lọ ja ṣọọbu oniṣọọbu, ti awọn mii si ji ẹru ẹlẹru ko.
Lẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ lasiko iwọde naa, ọga agba ọlọpaa Naijiria, Kayode Egbetokun kede pe awọn fi ṣikun ofin mu awọn kan to gbe asia Russia lọwọ lasiko iwọde lawọn ipinlẹ bii Kano, Kaduna, ati Zamfara.
Lara awọn ti ọlọpaa mu ni ọmọ orilẹede Poland meje wa lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iwọde ọhun.
Wayi o, Amnesty International ti sọ pe nnkan bii ọgọrun eeyan ni ọlọpaa ti ko lọ sile ẹjọ lori iwọde naa, ti ọpọ si wa ni atimọle.
Ajọ naa ti fẹsun kan ijọba Naijiria pe o n tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ.
O ti wa ke si ijọba Naijiria lati tu awọn ti wọn ti mọle silẹ nitori ẹtọ araalu ni lati fẹhonuhan labẹ ofin.















