Ìjà UFC fún Afrika, ta a ni yóò borí láàárín Du Plessis àti Adesanya?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Ben Miller
- Role, BBC Sport Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Idije Ija (UFC) ti gbe ariyanjiyan sita laarin Dricus du Plessis ati Israel Adesanya saaju ija wọn to jẹ akọkọ iru rẹ fun Afrika, ti yoo waye ni lọjọ Aiku ni owurọ kutu.
Adesanya, ti o ma n sọrọ nipa "ewe rẹ to rẹwa" ni ilu Eko ṣaaju ki o to lọ si New Zealand ni ọmọ ọdun mẹwaa, ti fi ẹsun kan Du Plessis pe ko ni ibọwọ fun awọn to pe ni ' Ọba Afrika'.
Orukọ ọba yii ni wọn fun ẹni ọdun marundinlogoji Kamaru Usman ati Francis Ngannou nigba ti awọn mẹtẹẹta gba bẹlẹti UFC.
"N jẹ awọn bẹliti ti ẹ gba lọ si Afirika ?" Du Plessis fọhun pada, nigba to di olubori UFC akọkọ tọ jẹ ọmọ South Africa ni Oṣu Kini.
Ẹni ọgbọn ọdun naa gbagbọ pe Adesanya, Usman ati Ngannou gbe ni ilẹ okere, ti wọn si tun kọ iṣẹ wọn nibẹ ti ja wọn kuro nipo Oba ti wọn fun ara wọn.
Lẹyin ti Du Plessis lu Robert Whittaker ni Oṣu Keje ọdun to kọja, o kọju si Adesanya pe ija ilẹ Afrika ti ya
Adesanya, fesi pada pe lilu Du Plessis ṣe pataki ju gbogbo bẹliti to ti gba saaju.
Alatako rẹ ni oun gan ni Ọba Afrika nitori oun n gbe mi Afrika
Awọn onija ọjọọla fun Afrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Ile-ẹkọ Wellness Martial Arts Academy ti o wa ninu papa iṣere National Stadium ni Lagos, olukọni John Anene ri bi awọn onija se ngbiyanju lati tẹle awokọse Adesanya ati Usman.
Ni bayi, o sọ pe, MMA n ni ilọsiwaju sugbọn ki ṣe rere ni Naijiria, pẹlu bi ko se si ohun lati kọ awọn onija lati di ilumọka.
“Awọn ohun elo jẹ ipenija fun pupọ ninu wa,” Anene sọ fun BBC Sport Africa.
"Ṣugbọn ṣe a ni awọn elere idaraya ti o le gbe wa larugẹ? Bẹẹni, a ni ọpọlọpọ awọn eniyan to lagbara nibi."
Ileeṣẹ to n se aanu ti Ngannou gba kalẹ, to si si ni orilẹede Cameroon jẹ ohun igbaradi MMA akọkọ ni ọdun 2019, ati Usman kede awọn ero rẹ ni ọdun 2022 lati ṣẹda ohun elo kan ni Ile-ẹkọ giga ti Eko.
Du Plessis n gbaradi ni CIT Performance Institute ni Pretoria, nibiti olukọni Stephan de la Rey sọ pe aṣeyọri rẹ ti ni ipa pupọ ni ere idaraya.
O ti fihan pe eeyan tuntun to sẹsẹ de le se aṣeyọri ni MMA.
“Iye awọn ọdọ ti n bọ sita nitori ti rẹ lo ya ni lẹnu,” De la Rey sọ.
Nkazimulo Zulu, ẹni to ti gba ami ẹyẹ meji fun South Africa, sọ pe Du Plessis n fun ni latilẹyin ti ara fun awọn elere idaraya ni CIT.
Zulu ni ipinnu lati di Olubori UFC ati to si n rọ ijọba lati ṣe iranlọwọ, pe MMA le di nla bi ere idaraya rugby ni South Africa.
“A kan nilo ijọba wa lati ṣe idokowo ni ere idaraya nitori a yoo ni ọpọlọpọ awọn olubori,” o sọ fun BBC Sport Africa.
“Ibi Idaraya yii ti fihan pe a le gbe awọn akọni onija dide fun gbogbo agbaye.
"O n gba ọpọlọpọ awọn ọdọmọkunrin lọwọ ohun ti ko da ti wọn se ni titi. Mo ni ibinu pupọ ṣugbọn MMA ti kọ mi ni ibawi."
UFC ni ifojusun nla fun ija yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images
UFC rii Afirika bi ọja nla pẹlu awọn ololufẹ ere sugbọn awọn alakoso ere idaraya naa ko ti gbe ere naa wa si ilẹ Afrika ni ọdun mọkanlalogun ti wọn ti sẹda rẹ.
Ipade Du Plessis ati Adesanya ni Perth ni ipari ose yii yoo jẹ ija kaadi UFC tuntun ti yoo waye ni Australia yoo gbalejo, ati pe idije naa ti ṣabẹwo si Asia, Europe, South America ati Aarin Ila-oorun Middle East.
Australia n gbalejo ere-idaraya rugby kan pẹlu South Africa ni kutukutu ọjọ Satidee, ati pẹlu ajọsepọ ti Super Sport, ọkan ninu awọn alabaṣiṣẹpọ igbohunsafefe UFC ni Afirika.
Awọn alakoso ti ni ija miiran yoo waye ni South Africa ti Du Plessis ba bori Adesanya.
"O jẹ nkan ti Dana ati ẹgbẹ ti sọrọ nipa ni ọdun to kọja, ati pe dajudaju ipinnu wa fun pe oja naa lati waye aipẹ," Alakoso UFC David Shaw sọ nipa awọn ero wọn fun Afirika.
“A ti rii idagbasoke awọn ololufẹ wa ni Afirika, pẹlu South Africa ati Nigeria jẹ meji ninu awọn orilẹ-ede to ṣe pataki.
"Adesanya jẹ irawọ nla - kii ṣe ni Afirika nikan ṣugbọn ni gbogbo agbaye.
"A n nireti lati gba ija nla wa si Afrika, eyi ti yoo ni ipa nla fun agbegbe naa.”
UFC 305: Nina ọwọ soke fun Afrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn asọtẹlẹ lori tani yoo ṣẹgun da lori iru ere idaraya ti o wa - botilẹjẹpe awọn ẹlẹgbẹ Du Plessis ati Adesanya jẹ ololufẹ awọn onija mejeeji.
Ti Adesanya ba gbe ọwọ rẹ soke pe oun lo bori, yoo ya ila si aya rẹ to n safihan ilẹ adulawọ paapa orilẹede Naijiria.
Ti Du Plessis ba ṣẹgun ija yii, yoo jẹ mẹwaa to ti bori ni lera wọn, ti yoo si di ọmọ Africa to bori nigba igbalejo UFC akọkọ ti Afirika.
Anene ni imọlara idojukọ lori Du Plessis ati Adesanya lori Afirika jẹ ilana ọja - ṣugbọn o jẹ eyi ti o dara.
“Ọpọlọpọ yoo mọ nipa MMA ni Afirika nipasẹ ija yii,” o sọ.
Bokang Masunyane, sọrọ lori Du Plessis pe
“O lẹwa nitori pe o n gbe nibi ati pe o n ja lati Afirika.
"Oju ti wa ni ọpọ awọn onija lati afrika, eyi to jẹ ohun iyanu."
















