Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá Emefiele oní-mílíọ̀nù dọ́là méjì míràn ($2.04m)

Oríṣun àwòrán, Godwin Emefiele/Screenshot
Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki ijọba gbesẹ le miliọnu meji ($2.04m) awọn dukia miran ti gomina ile ifowopamọ agba, CBN tẹlẹ, Godwin Emefiele.
Onidajọ Akintayo Aluko lo gbe aṣẹ naa kalẹ l’Ọjọbọ, ọsẹ yii lori ẹsun jibiti ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC fi kan Emefiele.
Lara awọn dukia naa ni ti Prime Real Estate to wa ni Lekki ati Ikoyi, nipinlẹ Eko, ati pẹlu ti ileeṣẹ nla kan to wa lagbegbe Agbor nipinlẹ Delta.
Aluko sọ pe eyi yẹ lati le dena tita awọn dukia ti wọn fura si wi pe o ra nipaṣẹ owo to ri nidi iwa jibiti.
Adajọ naa sọ pe:- “Awọn dukia to wa ninu iwe ẹsun yii ni wọn fura si pe wọn ra nipa owo jibiti ati alumọkọrọyi,”
Awọn dukia to wa ninu iwe ẹsun naa ni:-
- ile meji to wa loju kẹtadinlogun-keji (17b), adugbo Hakeem Odumosu, Lekki Phase 1, l’Ekoo;
-ilẹ to wa ni iwọn 1,919.592 sqm lagbegbe Oyinkan Abayomi Drive ni Ikoyi;
- ile kan to wa lojule karundinlaadọrin-akọkọ (65a), adugbo Oyinkan Abayomi Drive, Ikoyi;
-ile oni-yara mẹrin to wa lojule kejila-akọkọ, opopona Probyn, Ikoyi;
-ile itaja nla to wa lori pulọọti mejilelogun, Agbor, ipinlẹ Delta;
- ile mẹjọ to wa lopopona Adekunle Lawal, Ikoyi ati ile nla kan to wa lojule keji-akọkọ (2a), opopona Banki, Ikoyi.
Ki tun ni ilé ẹjọ́ tun gbẹsẹ lé?
Bakan naa ni dukia miran ti ile ẹjọ tun paṣẹ lati gbẹsẹ le ni iwe ẹri ipin idokowo ti ileeṣẹ Queensdorf Global Fund Limited Trust, eyi ti wọn tọpinpin rẹ si Emefiele.
Agbẹjọro EFCC, Rotimi Oyedepo, to gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ ninu ẹjọ ti nọmba rẹ jẹ FHC/L/MISC/500/24, sọ fun ile-ẹjọ pe Emefiele ra awọn dukia naa ninu owo to ko jọ nidi iwa jibiti.
“Awọn owo ti a n sọ yii ni idaniloju wa wi pe wọn ko jọ nipa iwa jibiti ati awọn ọna ti ko ba ofin mu.
“A n rọ ile ẹjọ lati gbọ ẹbẹ wa lati dena ṣiṣe awọn dukia naa baṣubaṣu,” Oyedepo sọ ninu iwe ẹbẹ














