Wo àwọn àpẹẹrẹ tí o fi lè mọ́ pé o ti ní ìpòrúru ọkàn àti bí o ṣe lè ṣẹ́gun rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ogun pọ laye to n koju ọmọ eniyan, o kan wulẹ yatọ sira wọn ni.
Ọpọ igba lo jẹ pe awọn eeyan yoo ni idaamu ọkan ati irẹwẹsi nitori awọn ohun kan ti wọn n la kọja lojoojumọ aye.
Ṣugbọn to ba ti waa di pe eeyan wa ninu idaamu ọkan fun ọpọlọpọ ọsẹ tabi oṣu, awọn dokita jẹ ka mọ pe ẹni naa ti ni iporuuru ọkan ti wọn n pe ni ‘Depression’ niyẹn.
Bo tilẹ jẹ pe nnkan kekere lo jọ loju awọn ẹlọmi-in, ti wọn yoo maa ni aini suuru lo n fa iporuuru ọkan, sibẹ, awọn onimọ nipa rẹ sọ pe aisan to lagbara ni.
Wọn ni aisan to n ba ọpọlọ eeyan ja teeyan ko ni i ranti awọn nnkan mi-in mọ ni iporuuru ọkan ati idaamu.
Wọn lẹni to n ṣẹlẹ si ko si ni ikapa lori rẹ bo ti wu ko kere mọ.
Dokita Dayyaba Shaibu to n tọju aisan ọpọlọ nileewosan nla kan l’Abuja, ṣalaye ohun tawọn eeyan tọkan wọn n poruru n la kọja fun BBC.
Eyi lohun ti Dokita la kalẹ bii apẹẹrẹ.
Ìbànújẹ́ aláìnídìí
Nigba ti ọkan ba poruru, Dokita Dayyaba ṣalaye pe ẹni to n ṣẹlẹ si yoo ba ara rẹ nipo ibanujẹ lai nidii.
Ẹni to n koju iporuru ọkan yoo kan ṣaa mọ pe ibanujẹ n gori ẹmi oun lọ ni.
" Ẹ maa ṣakiyesi pe ẹni ti aisan yii n ṣe yoo padanu idunnu.
Ohun to n dun awọn eeyan yooku ninu le mu inu tiẹ bajẹ, to bẹẹ to le ma fẹẹ ba awọn eeyan ṣe lawujọ mọ."
Bẹẹ ni Dokita Dayyaba ṣalaye.
Yíya ara-ẹni sọ́tọ̀ láwùjọ èèyàn
Lẹyin ti ẹnikan ba ti ni iporuru ọkan, apẹẹrẹ mi-in to maa n jade lara wọn ni pe wọn yoo ya ara wọn sọtọ lawujọ awọn eeyan.
" Ẹni to ti mọ lara tẹlẹ lati jokoo ti ẹnikeji rẹ ti wọn yoo jọ maa sọrọ, ẹ maa ri i pe o tẹ ẹ lọrun ko da jokoo loun nikan ninu yara rẹ bayii ti irẹwẹsi ọkan de.
‘’To ba si tun da wa loun nikan naa, ara ko tun ni i rọ ọ to bẹẹ naa.
‘’Koda, ki gbogbo ile maa jade lọ, ẹni ti ọkan rẹ poruru yoo loun ko lọ, oun fẹẹ da wa nile ni."
Àì rí oorun sùn tàbí àpọ̀jù oorun
Dokita Dayyaba ṣalaye pe ọ̀kan ninu apẹẹrẹ iporuru ọkan ni aisun to tabi apọju oorun.
" Pupọ awọn eeyan to n koju iṣoro yii, ẹ maa ri i pe ninu ki wọn ma le sun to bo ṣe yẹ, tabi ki wọn si maa sun ni gbogbo igba ju bo ṣe yẹ lọ."
Àì fẹ́ láti jẹun tàbí àjẹjù oúnjẹ
Ai nifẹẹ lati jẹun, tabi keeyan maa jẹun ajẹju tun jẹ apẹẹrẹ kan fawọn ẹni tọkan wọn poruru.
Eyi lẹ fi maa ri i pe ẹni naa le maa rù tabi ko maa sanra ju bo ṣe yẹ lọ.
"Ko rọrun lati tọju aisan yii, itọju rẹ maa n pẹ, ẹni to n koju rẹ yoo ni lati lo oogun fun igba pipẹ ko too le lọ.
‘’Onisuuru eeyan ti nnkan ki i su lo le maa ba iru ẹni bẹẹ sọrọ titi ti yoo fi bọ ninu idaamu ọkan to wa.’’ Bi Dokita ṣe wi.
Èrò láti pa ara ẹni
Latari ibanujẹ ọkan ati yiyago fawọn eeyan yooku lawujọ, awọn ti ọkan wọn gbọgbẹ maa n ro pe aye awọn ko nitumọ.
Bi wọn ba ti n ro o bẹẹ ni yoo maa wa si wọn lọkan lati kuku pa ara wọn.
Pipa ara ẹni yii jẹ ero kan to ṣoro lati mọ idi ẹ, ṣugbọn o maa n wa sọkan eeyan bii ọna abayọ lati pari ogun to n ja ni.
Loootọ lo ṣoro lati mọ idi tẹnikan yoo fi gbero lati pa ara rẹ, awọn ẹni to gbiyanju ẹ nikan ni wọn mọ ohun to n lọ lọkan wọn.
Kí ló ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn àti ìpòrúru gan-an?
Dokita Dayyaba sọ pe ẹnikẹni ni irẹwẹsi ati iporuru ọkan le mu, bo si ṣe n ṣe ọmọde lo n ṣe awọn agbalagba.
Ṣugbọn o, Dokita yii sọ pe iporuru ọkan pọ laarin awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn ṣẹṣẹ n balaga.
Awọn onimọ nipa ilera sọ pe bi ijamba kan ba ṣẹlẹ si eyan, bii keeyan padanu olufẹ.
Bii kiṣẹ bọ lọwọ eeyan lojiji, abi ki ọmọ bibi maa fun eeyan ni ibanujẹ pẹlu awọn isọro aye mi-in.
Wọn ni gbogbo ẹ le fa irẹwẹsi, idaamu ati iporuru ọkan .
Bi Oluwa ṣe da wa gẹgẹ bi ẹlẹran ara naa jẹ idi kan teeyan fi le ni idaamu ọkan nigba ti adanwo ba de.
" Awọn eeyan kan wa t’Oluwa da amumọra mọ wọn pupọ.
Bi ohun to buru ba ṣẹlẹ si wọn, wọn aa gba kamu, wọn aa maa ṣaye wọn lọ bii pe nnkan kan ko ṣe.
Ohun to ṣẹlẹ si wọn naa ko ni i de ookan aya wọn, ko si ni i daamu ọkan wọn.
" Ṣugbọn awọn mi-in ko ri bẹẹ. Oluwa da wọn lẹni ti ọkan rẹ fuyẹ, ti ko si ni ara adanwo.
Iru wọn lo ṣee ṣe ki wọn ni iṣoro iporuru ọkan ju." Dokita Dayyya lo sọ bẹẹ.
O ni ṣugbọn akitiyan aṣeju, keeyan gbe nnkan saya ju le di aarẹ si eeyan lara.
Ṣé ìpòrúru ọkàn gbọ́ ìtọ́jú ṣáá?
Beeyan ba ri iranlọwọ to yẹ lasiko to yẹ, ipororu ọkan gboogun bi Dokita Dayyaba ṣe sọ.
" B’ẹnikan ba bẹrẹ si i fi apẹẹrẹ aisan yii han, ohun akọkọ ni lati mu un lọ sileewosan.
Oogun wa fawọn eeyan to n ni iporuru ọkan, ilana si wa fun itọju wọn pẹlu.
" A maa n pese oogun fun wọn, awọn dokita si wa ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn tọju awọn onirẹwẹsi ọkan lọ.
Awọn dokita naa lo maa n fun wọn lamọran lorii bi wọn yoo ṣe lo aye wọn."
Awọn eeyan to sunmọ onirobinujẹ eeyan naa nkọ, bii ẹbi wọn.
Dokita sọ pe ki wọn fifẹ han wọn.Ki wọn ma ṣe ta wọn nu.
Eyi pẹlu itọju ti wọn ba n gba yoo maa mu ọkan wa balẹ titi ti alaafia yoo fi de tan.














