Ilé ẹjọ́ buwọ́lu ìyọ̀nípò Ganduje, ariwo sọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC

Ile ẹjọ giga to n joko niluu Kano ti buwọlu iyọnipa Gomina tẹlẹ nipinlẹ Knao ati alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Abdullahi Ganduje gẹgẹ bii alaga ati ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Usman Na'abba buwọlu ipe Dokita Ibrahiom Sa’ad pẹlu ọmọ ẹgbẹ meji to wa lati wọọdu ti Ganduje ni ijọba ibilẹ Dawakin Tofa , Laminu Sani ati oludamọran nipa ofin Haladu Gwanjo ti wọn wa lara awọn eeyan mẹsan an to kede iyọnipa Ganduje lọjọ Aje.

Ile ẹjọ palaṣẹ fun awọn igun mẹrin ti ẹjọ naa kan, ẹgbẹ oṣelu APC, Igun NWC, ẹgbẹ oṣelu APC ni Kano ati Ganduje to pe ki wọn aṣẹ ile ẹjọ to waye ni ọjọ kẹdogun oṣu kẹrin , titi igbẹjọ yoo fi waye ni ọgbọnjọ oṣu kẹrin.

Adajọ Na.abba tun wa palaṣẹ fun igun APC NWC nipinlẹ Kano lati ma ṣe igbiyanju tako igbesẹ awọn olori wọọdu to yọ Ganduje ni gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ.

Tinubu sọ fun mi pe emi si ni alaga APC- Ganduje

Alaga APC ti ile ẹjọ ni ko lọ rọọkun ni ile Abdullahi Umar Ganduje ni ijọba Kano ko ni agbara kankan lati pe fun iyọnipo oun nitori Aarẹ Tinubu ti fi oun lọkan balẹ pe ko si iyọnu.

Ganduje sọ eyi ninu fọnran kan to wa lori ayelujara nibi to ti n ba ọpọ eeyan sọrọ to ṣe abẹwo si ni ile rẹ niluu Abuja.

O ni “Laana, mo ri Aarẹ Bola Tinubu, mo dẹ ṣalaye gbogbo ohun to sẹlẹ fun un, to si dupẹ lọwọ mi.’

Ganduje ni Aarẹ Tinubu ti ni ki oun lọ fọkan balẹ pe oun ni oun ni ipo alaga ẹgbé oṣelu APC lorilẹede Naijiria.

Àwọn tó ní kí Ganduje lọ rọọ́kún nílé kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ APC - Abdullahi Abbas

Aworan Abdullahi Ganduje

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Ganduje/Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kano ti sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ lori bi wọn ṣe jawe lọ rọọkun nile fun Gomina tẹlẹri nipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje, ẹni to tun jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu naa lapapọ.

Lọjọ Aje, ọsẹ yii ni ikun kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Dawakin Tofa, iyẹn nibi ti Ganduje ti jade kede pe awọn ti jawe lọ rọọkun nilẹ fun baba naa.

Ko pẹ ti ikede naa bọ sita ni awọn agbaagba ẹgbẹ APC ni Dawakin Tofa naa sọrọ sita wi pe ala ti ko le ṣe ni ikede ọhun, ati pe ko le fẹsẹ mulẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Kano, Abdullahi Abbas nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn to kede pe ki Ganduje lọ rọọkun nile ni wọn kii ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa.

Abbas sọ pe awọn to gbe ikede naa sita lo jẹ pe wọn sunmọ awọn oloṣelu to jẹ pe ẹgbẹ NNPP to n ṣakoso.

O ni awọn ti ṣagbeyẹwo iwe awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn wa lati agbegbe ti Ganduje ti wa, to si ni ko si eyi to jẹ oloye ẹgbẹ ninu wọn.

“Mẹtadinlọgbọn ni awọn to wa lati agbegbe kọọkan, a si yẹ wọn wo, a rii pe ko si eyi to jẹ oloye ninu wọn.”

Bakan naa lo sọ pe Haladu Gwanjo to kede pe ki Ganduje lọ rọọkun nile ti sọ pe oun yoo gba ile-ẹjọ lọ lati lọ ja fun ẹtọ ohun.

Abdullahi Abbas ninu ọrọ rẹ sọ pe “Eleyi ko ni nnkan ṣe pẹlu ẹgbẹ ti wa, ipinu ti ijọba Kano ati ẹgbẹ oṣelu wọn gbe kalẹ leyi, a si rii pe ọna lati fi tabuku Ganduje ni.”

Ṣé lóòótọ́ ni APC jáwé lọ rọọ́kún nílé fún Ganduje?

Aworan

Oríṣun àwòrán, APC Nigeria/X

Igun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni ijọba ibilẹ Dawakin Tofa nipinlẹ Kano ti jawe lọ rọọkun ni ile fun Gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, ẹni to tun jẹ alaga fun ẹgbẹ oṣelu naa, Abdullahi Ganduje

Haliru Gwanzo ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni wọọdu Ganduje nijọba ibilẹ Dawanki Tofa lo kede igbesẹ yii lasiko ti wọn n b awọn akọroyin sọrọ niluu Kano

Ẹsun siṣe owo ilu mọkumọku ni wọn fikan Ganduje

Bakan naa, Gwanzo ni fọnran kan to ṣafihan gbigba riba owo dọla wa lara ẹsun ti wọn fikan Ganduje, eyi to wa ni iwaju ileẹjọ giga ipinlẹ Kano lo fa ti awọn fi gbe igbesẹ naa

Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ gbe igbesẹ lati da Ganduje duro lẹyin ti ọpọ ọmọ ẹgbẹ dibo pe ki wọn yọ nitori ko ti wẹ ara rẹ mọ ninu ẹsun gbigba riba to wa ni iwaju ile ẹjọ

Ẹwẹ, igbimọ to n seto ipinlẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC ni Kano naa ti kede lọ rọọkun ni ile fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni wọọdu Ganduje ti wọn kede idaduro rẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ fihan pe Ganduje si ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria.