Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 46 tó ń da omi àlááfíà Ilorin rú

Oríṣun àwòrán, NPF Ilorin
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasí ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da omi alaafia ilu Ilorin, nipinlẹ Kwara ru.
Awọn afurasi yii ni wọn to mẹrindinlaadọta, ti iwadi ọlọpaa si fi han pe, mẹrinla ninu wọn lọwọ si ipaniyan ati rogbodiyan to ṣẹlẹ ninu ilu naa ni kopẹ kopẹ yii.
Gẹgẹ bi ohun ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, DSP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun ṣalaye, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun bẹrẹ wahala wọn lagbegbe Ile-Fiimu, Bọ́láńtà ati opopona Ẹmir niluu Ilọrin.
Ọlọpaa ni agbegbe naa ni wọn ti pa gende ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Farooq Adelodun, ẹni ọdun mẹrindinlogoji lati Agboole Eleran.
Alukoro ọlọpaa ni iwadii fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ayee kan, Abubakar Gobir, wa lara awọn to sọsẹ yii.
O tẹsiwaju pe lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin yii kan naa, ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii tun gbe wahala wọn de Ile-Alawo, lagbegbe Center Igboro ni Ilorin bakan naa.
Agbẹnusọ naa sọ siwaju si pe awọn afurasi ọhun tun ṣa onikẹkẹ maruwa kan Abdullahi Alao, pa.
Afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn pa Faruq ní Ilorin, Ọlọ́pàá ní kí kalùkú lọ ṣọ́ra

Oríṣun àwòrán, Kwara Policr
Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti seku pa gende kunrin kan, Adelọdun Faruq, ti agboole Ẹlẹ́ran, lagbegbe Ile Fiimu, niluu Ilọrin ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.
Ko si eeyan kan to le sọ idi ti wọn fi pa Faruq ni pato sugbọn awọn ti ọrọ naa soju wọn sọ pe o seese ki oloogbe naa jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn si ti ni ara wọn sinu tẹlẹ.
Ọkan lara olugbe agbegbe naa to ni ka fi orukọ bo oun lasiri to ba ikọ BBC News, ṣọrọ sọ pe ẹnu lo koba Faruq.
O ni ni kete ti awọn ẹruku naa de ti wọn si n tanna woju awọn ara adugbo ni Faruq fi ohùn silẹ fun wọn pe "ẹyin wo lẹ n tanna yẹn? Ta ni ẹ n wa?" pe eyi lo ṣokunfa ti wọn fi yinbọn lu u, to si ku loju-ẹṣẹ.
Kini Olọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?
BBC News ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara sọrọ iyẹn, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, o si fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
O ni ati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye ni awọn ti bẹrẹ iwadii lati mu awọn to sisẹ laabi ọhun.
Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, sọ pe, ni bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni iṣẹlẹ naa waye.
O salaye pe awọn mọlẹbi oloogbe ko fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti ti wọn fi lọ sin oku ọkunrin naa ni ilana ẹṣin musulumi latari pe wọn ni oku musulumi ki i pẹ nilẹ.
Adetoun tẹsiwaju pe pẹlu ohun ti awọn tọrọ naa ṣoju wọn wi ati ọna ti wọn gba pa gende kunrin naa, o fihan pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn ró idán ọwọ wọn ṣugbọn iwadii si n lọ lọwọ lati mu awọn to wa nidi iṣeku-pani ọhun.
Bakan naa lo sọ fawọn Obi ati Alagbatọ ki wọn kilọ fun awọn ọmọ wọn.
Ki wọn ma sọ ara wọn di irinṣẹ Esu, ki wọn jinna si agbegbe ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n rodan yii, tori pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ yoo fimu kata ofin.
Adetoun, tun rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa, paapaa ju lọ, awọn eeyan Ilọrin, lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹsọ alaabo lati gbe igbesẹ kiakia, ki ọrọ a n rẹ ara ẹni danu bii ila yii le wa sopin.
O ni ọlọpaa nikan ko le da a ṣe, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ki i ṣe ẹmi airi, awujọ eeyan naa ni wọn n gbe, fun idi eyi, bi awọn eeyan ba ti kẹẹfin iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn maa fi to awọn ẹsọ alaabo leti












