Ìjàmbá iná wáyé ní oríkò iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná, okùnkùn birimù gbalẹ̀

Oríṣun àwòrán, JOHN ONYE/PHEDC
Àjọ tó ń rí sí pínpín iná mọ̀nàmọ́ná ní Nàìjíríà, ìyẹn Transmission Company of Nigeria, (TCN) ní àwọn ti bomi pa ìjàmbá iná tó wáyé ní ẹ̀ka Afam Power Generating Station èyí tó ṣokùnfà bí ẹ̀rọ tó ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná ṣe dẹnu kọlẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé.
Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ náà fi sórí ìkànnì ayélujára X wọn ní ìjàmbá iná kan ló wáyé ní aago mẹ́ta kú ìṣẹ́jú mọ́kàndínlógún ooru ọjọ́ Ajé tó sì ṣokùnfà àwọn ohun tí wọ́n fi ń pèsè iná ní Afam lll àti Afam Vl.
Adarí ẹ̀ka ètò ará ìlú ti iléeṣẹ́ TCN, Ndidi Mbah sọ pé ìjàmbá iná náà ló jẹ́ kí àwọn pàdánù mẹ́gáwáàtì tó dín díẹ̀ ní irinwó, tó sì fa òkùnkùn birimù káàkiri àwọn agbègbè tó yẹ kí ẹ̀rọ náà pèsè iná fún.
Mbah sọ àsọdájú rẹ̀ pé ẹ̀rọ náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà àti pé àwọn ní ìfarajìn láti ri dájú pé àwọn ń pèsè iná ọba
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣáájú ni ìròyìn ti gbòde pé Iléeṣẹ́ tó ń rí sí pínpín iná mọ̀nàmọ́ná ti kéde pé ẹ̀rọ tó ń pèsè iná mọ̀nàmọ́ná tún ti dẹnu kọlẹ̀ àti pé òun ló fa ìdí tí àwọn ènìyàn kò fi ní iná káàkiri.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde láti ẹ̀ka Independent System Operator (ISO), nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú méjìdínlógún ooru ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ẹ̀rọ tó ń pèsè iná náà dẹnu kọlẹ̀.
Wọ́n ní ẹ̀rọ náà ti Okpai, Geregu àti Ibom kò máa pèsè ju mẹ́gáwáàtì 64.70 àmọ́ tó tún ti gbéra sí mẹ́gáwáàtì 266.50 báyìí lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Ẹgbẹ̀rún mẹ́rin mẹ́gáwáàtì ni Nàìjíríà máa ń pèsè ṣáájú àkókò yìí ṣùgbọ́n tó máa ń já ní gbogbo ìgbà látàrí afẹ́fẹ́ gáàsì tí kìí tó ní ọ̀pọ̀ ìgbà.
Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná tẹ̀ka Jos tí àdárí ètò gbogbo fi ránṣẹ́ sí àwọn aníbàárà wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé ni wọ́n ti ṣàlàyé ìdí tí àwọn èèyàn fi wà nínú òkùnkùn birimù.
Láti inú oṣù Kejì ọdún 2024 ni iná mọ̀nàmọ́ná ti ń ṣe ṣégeṣège ní Nàìjíríà tí ọ̀pọ̀ ilé sì ti ń wà ní òkùnkùn.
Iléeṣẹ́ amúnáwá IBEDC ṣàlàyé ìdí tí ilé yín fi wà nínú òkùnkùn birimù
Ileeṣẹ to n pese ina ba ni ẹ́ka ilẹ̀ Yoruba, Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC) ti tẹnu bọ alaye lori idi ti okunkun birimu fi gbalẹ lawọn ipinlẹ alabara to wa labẹ akoso rẹ.
Wọn ni o sunmọ ẹgbẹrun meji iṣelẹ jiji eroja ipese ina ọba gbe to waye laarin oṣu kini ibẹrẹ ọdun yi.
Eleyi ni ileeṣẹ naa sọ pe o ṣokunfa okunkun birimu tawọn eeyan ipinlẹ Oyo, Ogun, Osun, Kwara, and parts of Kogi, Niger, ati Ekiti .
Ninu atẹjade kan ti agbẹ́nusọ ileeṣẹ naa, Busolami Tunwase fi sita, o sọ pe ọpọ onibara awọn lo ti n kerora ooru ati ipenija alaafia mii ti aisi ina ọba mu ba wọn.
Pataki lara ohun to sọ pe o n fa idiwọ ipese ina mọnamọna yi ni airi gaasi gba lọdọ ileeṣẹ to n pese rẹ, eyi tawọn le fi pese ina ọba.
Ijọba ko le maa san owo iranwọ mọ lori ipese ina ọba, gbese wa pọ lọ́dọ̀ ileeṣẹ́ to n pese gaasi fun ipese ina ọba - Minisita
Atẹjade agbẹ́nusọ naa tun fikun pe, atunṣe tawọn ileeṣe to n pin ina, TCN, n ṣe lori oju opo wọn lati oṣu Kini ọdun titi di oṣu Kẹta, wa lara ohun to fa aisi ina lawọn agbegbe kọọkan.
Laarin oṣu meloo kan ni ọrọ ina ọba ti dẹnukọlẹ̀, ti awọn araalu si n ke gbajare pe ki ijọba wa nnkan ṣe si.
Minisita fun ipese ohun amusagbara lorileede Naijiria, Adebayo Adelabu laipẹ yii, sọ pe ijọba ko ni le maa san owo iranwọ mọ lori ipese ina ọba.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja, o ni gbese pọ lọrun ijọba, ni paapa owo tawọn yoo san fawọn ileeṣẹ́ to n pese gaasi ti wọn yoo lo lati fi pese ina ọba.
Minisita Adelabu ko ṣẹṣẹ maa tẹnu mọ ọrọ yiyọ ẹkunwo lori owo ina ti araalu n san.
Eleyi to tun sọ laipẹ yi ni pe ileeṣẹ ina nilo 2.9 triliọnu Naira lati le fi san ẹkunwo owo ina mọnamọna ni ọdun 2024.
O ṣalaye pe owo ti wọn ya sọtọ ninu owo iṣuna, kere lati san owo yii tori pe ko ju 450 biliọnu Naira ti o wa nilẹ.
Yatọ si eleyi o ni ijọba jẹ awọn ileeṣẹ to n pese gaasi ti wọn fi n peelo ina ọba ni owo to le ni biliọnu kan dọla.
Ti a ba fi eleyi kun gbese N1.3 triliọnu ti o ni awọn jẹ ileeṣẹ to n pese ina taa mọ si awọn GenCos, gbese naa di pupọ .
Bi Minisita naa ṣe n ke gbajare lara ilu ati ileeṣe ina mọnamọna n figbe ta.
Agbẹnusọ IBEDC tọrọ aforijin lọdo awọn alabara rẹ amọ ko sọro nipa eto gba ma binu kankan fun awọn ti ko ri ina ọba.
Kaka bẹẹ o di ẹbi ru awọn araalu kan to ni wọn n ji ina awọn lo ati awọn mii ti ko san owo ti wọn jẹ ileeṣẹ naa ni gbese ati pe eleyi naa lapa lara idiwọ to mu kawọn ma le pese ina mọnamọna.
O tun s ọ pe awọn wo ọna mi tawọn yoo fi ma pese












