"Àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò kú ikú Ọlọ́run, ooru mọ́tò kọ́ ló pa wọn, ogun ilé olórogún ni"

Laipẹ́ yii la mu iroyin wa fun yin nipa iṣẹlẹ kayeefi kan to waye niluu Ilorin, nipinlẹ Kwara, nigba ti awọn ọmọ kekeke mẹta, ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa ṣadeede ku sinu ọkọ ayọkẹlẹ kan.
Inu ile baba awọn ọmọ naa to wa lagbegbe Sango, ni ijọba ibilẹ ila orun Ilorin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara, ni ìṣẹ̀lẹ̀ naa si ti waye.
Awọn ọmọ naa, Maryam, ọmọ ọdun mẹwa; Nudrah, ọdun mẹjọ ati Mohammed ọmọ ọdun meji.
Nibayii, BBC Yoruba ti kan si iya awọn ọmọde naa lati mọ bi isẹlẹ ọhun se ri lara rẹ.
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin nipa ohun ti baba awọ̀n naa, Abdukadir Adeola Jimoh, sọ fun BBC Yoruba.
O ni pe oun binu, oun si sọrọ odi si Ọlọrun nigba ti awọn ọmọ oun mẹta ku lọjọ kan naa.
Jimoh Abdulkadir ati Silifat Folashade to n gbe ni ojule Kẹjọ, Boluke Line, Zango-Kulende ni ilu Ilorin, olu ilu Kwara ni a gbọ pe oru mu wọn pa sinu ọkọ ti baba wọn gbe kalẹ.
Abdukadir ni koda, ṣe ni oun pa irun kiki ti nigba naa ti oun si n beere idi ti o fi jẹ oun ni ajalu naa re lu.
Awọn ọmọ mi ko ri idunnu lati ara baba wọn, n ko si fẹ ki wọn ba ibanujẹ pade lati ara mi, ni mo se maa n tẹ wọn lọrun - Abdulkadir Sade
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, iya awọn ọmọ mẹtẹẹta to ku sinu mọto naa, Abdulkadir Silifat Sade salaye pe awọn ọmọ naa kọ lati jẹ irẹsi, ti wọn si ni spagetti ni awọn fẹ jẹ.
O ni gbogbo ohun ti wọn ba fẹ ni oun maa n se fun wọn nitori pe wọn ko ri idunnu lati ara baba wọn, ti oun ko si fẹ ki wọn tun ba ibanujẹ pade lati ara oun.
“Spagetti ti wọn ni awọn fẹ jẹ yii ni mo lọ mu ni sọọbu am nigba ti mo de, n ko ri wọn mọ.
Emi kii lọ si sọọbu lọjọ Sunday amọ ohun ti wọn beere pe awọn fẹ jẹ, ni mo lọ wa fun wọn.
Mo n pariwo kiri kaakiri adugbo, ẹnikan lo wa sọ fun mi pe ki n lọ wo agbala wa daadaa nitori pe awọn ọmọ mi kii jare sere kaakiri.
Bi mo se n wa wọn kiri ninu agbala wa, ni mo ri asọ ọkan ninu mọto ti ọkọ mi gba kalẹ, ti awọn mẹtẹẹta si ti sun silẹ́.”
Sade ni nigba ti wn yoo fi gbe awọn ọmọ naa jade, wọn ti di oku.

“Wọn fi iku awọn ọmọ mi mẹtẹẹta da mi loro ni nile olorogun, apa ọkan ninu wọn ti bo kanlẹ”
Bakan naa lo tẹsiwaju pe oun ko gba pe iku ọdọ Ọlọrun lo pa awọn ọmọ oun nitori pe kii se ooru inu mọto ti wọn ku si lo pa wọn.
“Awọn ọmọ naa ko lo to wakati kan ninu mọto naa, ti wọn fi ku, to ba jẹ pe wọ̀n se ayẹwo ohun to pa wọn ni, o seese ko jẹ majele ni.
Mo si gba pe kii se iku ati ọdọ Ọlọrun lo pa awọn ọmọ naa, o lọwọ aye ninu tori mo ti n koju wahala ile ologun yii, ọjọ ti pẹ.
Wọn sọ pe ẹmi mi gan ni wọn n wa, ti wọn ko si gba. Se wọn ko ba tiẹ fi ọkan silẹ fun mi ninu awọn ọmọ naa, bo ti ẹ jẹ kekere ni.
Wọ̀n da mi loro, wọn fi iya jẹ mi amọ emi ti gba fun Ọlọrun o”

Awọn ọlọpaa ri kẹmika to ṣe e se ko jẹ majele, wọn si ti lọ ṣe ayẹwo rẹ - Jimoh Abdulkadir
Baba awọn ọmọ mẹta to ku sinu mọto naa, Jimoh Abdulkadir, sọ fun BBC Yoruba pe ohun to sẹlẹ yii, ko tọ si oun, sugbọn Ọlọhun pinnu lati gbe ka iwaju oun ni."
O ni oun gba fun Ọlọhun, oun si ni ireti ninu iwadi awọn ọlọpaa wi pe, wọn yoo foju aṣebi han to ba jẹ eniyan lo sokunfa iku awọn oun.
"Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, wọn si ṣeleri lati ṣawari ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, ti yoo si fimu kata ofin.
Oriṣiriṣi ami ti awọn ọlọpaa ri nigba ti wọn de ile wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye pọ diẹ, wọn ri awọn bata ni ọna to jasi palọ.
"Wọn tun ri kẹmika to ṣe e se ko jẹ majele, wọn si ti lọ ṣe ayẹwo lori rẹ lati mọ ohun ti o jẹ ati iru isẹ to le ṣe.
"Bakan naa ni wọn gba ọrọ kalẹ lẹnu wa to le ran wọn lọwọ pẹlu iwadii wọn."

"Foomu jade lẹnu awọn ọmọ mi nileewosan, eyi to mu ifura dani"
Ọgbẹni Abdukadir sọ pe foomu jade lẹnu awọn ọmọ oun nileewosan, eyi to mu ifura da ni.
O tun fi kun un pe laarin isẹju diẹ ti iya wọn fi kuro nile to tun pada, oru o ti le mu awọn ọmọ pa sinu ọkọ ti ejo ko ba lọwọ ninu.
O ni alaye ti iyawo oun, to jẹ iya awọn ọmọ naa ṣe ni pe, oun lọ ọ mu nnkan ti awọn ọmọ naa yoo jẹ ni ṣọọbu to ti n ta ọja.
Igba ti yoo fi pada sile laarin iṣẹju diẹ ni wọn ri oku awọn ọmọ.






