'Mo bínú sí Ọlọ́run, mo dá ìrun dúró nígbà tí ọmọ mi mẹ́ta jáde láyé lọ́jọ́ kan ṣoṣo'
'Mo bínú sí Ọlọ́run, mo dá ìrun dúró nígbà tí ọmọ mi mẹ́ta jáde láyé lọ́jọ́ kan ṣoṣo'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baba awọn ọmọ mẹta ti ooru mu pa sinu ọkọ niluu Ilorin, ti sọrọ lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Ọgbẹni Abdukadir Adeola Jimoh, sọ fun BBC pe oun binu, oun si sọrọ odi si Ọlọrun nigba ti awọn ọmọ oun mẹta ku lọjọ kan naa.
Awọn ọmọ naa, Maryam, ọmọ ọdun mẹwa; Nudrah, ọdun mẹjọ ati Mohammed ọmọ ọdun meji, ti wọn jẹ ọmọ arakunrin Jimoh Abdulkadir ati arabinrin Silifat Folashade tan n gbe ni No 8 Boluke Line, Zango-Kulende ni ilu Ilorin, olu ilu Kwara ni a gbọ pe oru mu wọn pa sinu ọkọ ti baba wọn gbe kalẹ.
Abdukadir ni koda, ṣe ni oun pa irun kiki ti nigba naa ti oun si n beere idi ti o fi jẹ oun ni ajalu naa re lu.
"Ohun to sẹlẹ ko tọ si mi, sugbọn Ọlọhun pinnu lati gbe ka iwaju mi."
O ni oun gba fun Ọlọhun, oun si ni ireti ninu iwadi awọn ọlọpaa wi pe, wọn yoo foju aṣebi han to ba jẹ eniyan lo sokunfa iku awọn oun.
"Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, wọn si ṣeleri lati ṣawari ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, ti yoo si fimu kata ofin.
Oriṣiriṣi ami ti awọn ọlọpaa ri nigba ti wọn de ile wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye pọ diẹ, wọn ri awọn bata ni ọna to jasi palọ.
"Wọn tun ri kẹmika to ṣe e se ko jẹ majele, wọn si ti lọ ṣe ayẹwo lori rẹ lati mọ ohun ti o jẹ ati iru isẹ to le ṣe.
"Bakan naa ni wọn gba ọrọ kalẹ lẹnu wa to le ran wọn lọwọ pẹlu iwadii wọn."
Ọgbẹni Abdukadir sọ pe foomu jade lẹnu awọn ọmọ oun nileewosan, eyi to mu ifura da ni.
O tun fi kun un pe laarin isẹju diẹ ti iya wọn fi kuro nile to tun pada, oru o ti le mu awọn ọmọ pa sinu ọkọ ti ejo ko ba lọwọ ninu.
O ni alaye ti iyawo oun, to jẹ iya awọn ọmọ naa ṣe ni pe, oun lọ ọ mu nnkan ti awọn ọmọ naa yoo jẹ ni ṣọọbu to ti n ta ọja.
Igba ti yoo fi pada sile laarin iṣẹju diẹ ni wọn ri oku awọn ọmọ.

Iṣẹlẹ kayeefi kan waye niluu Ilorin, nipinlẹ Kwara, nigba ti awọn ọmọ kekeke mẹta ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa ṣadeede ku sinu ọkọ ayọkẹlẹ kan.
Agbọ pe iṣẹlẹ naa waye ni ile baba awọn ọmọ naa to wa lagbegbe Sango, ni ijọba ibilẹ ila orun Ilorin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara.
Ọkan lara awọn eeyan agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, Ahmed Arikewusola ṣalaye fun BBC Yoruba pe inu ile awọn ọmọ naa ni iṣẹlẹ laabi ọhun ti ṣẹlẹ ni nnkan bii ago meji ọsan.
O fikun pe lati igba ti baba awọn ọmọ naa ti fẹ iyawo keji ni alaafia o ti jọba mọ ninu ile wọn.
O tẹsiwaju pe lootọ ni awọn mọlẹbi ti pari ija laarin idile naa amọ nnkan ko da bii ti atijọ mọ.
Arikewusola fi kun pe ija naa le to bẹẹ ti iyale fi kọ lati lọ sibi ayẹyẹ isọmọlorukọ iyawo keji.
Bi iku awọn ọmọ naa ṣe waye
Ọgbẹni Arikewusola sọ siwaju si pe lẹyin ti baba awọn ọmọ naa lọ sibi isọmọlorukọ tan ni wọn bẹrẹ si n wa awọn ọmọ rẹ mẹta ọhun.
Amọ o ṣeni laanu pe lakoko ti wọn n wa awọn ọmọ mẹtẹẹta naa, wọn ti korajọ sinu ọkọ baba wọn, ti wọn si ti ilẹkun ọkọ ọhun mọ ara wọn
A gbọ pe lẹyin ọpọ wakati ti wọn ti n wa wọn ni iya wọn ri bata wọn nidi ọkọ, to si fi tipatipa ṣi ilẹkun ọkọ naa, ko to ri awọn ọmọ naa ti oru ti bo wọn ninu ọkọ.
Wọn gbe wọn lọ sile iwosan kan to wa lẹgbẹ ile wọn, nibi ti dokita ti gba wọn niyanju pe ki wọn maa gbe wọn lọ ile iwosan nla UITH.
Ile iwosan UITH yii ni awọn dokita ti kede pe awọn ọmọ naa ti gbẹmi mi.
Ẹwẹ, wọn ti sin oku awọn ọmọ naa bayii ni itẹ awọn Musulumi to wa niluu Ilorin.
Abẹwo BBC sile awọn obi awọn oloogbe naa fi han pe wọn ti mu iya wọn lọ si ọdọ iya rẹ, ti wọn si ti mu baba wọn lọ ọdọ awọn obi tiẹ naa.














