Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àsopọ̀ BVN àti NIN tí báńkì ń bèèrè báyìí

Ni bayii, awọn ileeṣẹ ifowopamọ lorilẹede Naijiria ti kede pe kawọn eeyan lọ so nọmba BVN ati NIN ti i ṣe ti nọmba idanimọ wọn pọ ni banki.
Aṣẹ yii lo wa ọdọ ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa, CBN.
Asẹ naa tẹsiwaju pe awọn onibaara to ba kuna lati ṣe asopọ yii yoo koju iṣoro aile gba owo tabi sanwo jade lati akanti banki wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo ti n kọminu lori aṣẹ CBN yii, ti wọn si n ke sita pe awọn ti so o pọ lasiko iforukọsilẹ, sugbọn CBN ko ṣetan lati yi aṣe asopọ BVN ati NIN yii pada.
Àṣẹ wo ni CBN pa gan-an?
Lọjọ kinni oṣu kejila ọdun 2023, ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa, CBN, paṣẹ fawọn banki pe ki wọn ti akanti onibaara ti ko ba ni nọmba BVN ati NIN, ki wọn gbe adagadodo si akanti irufẹ eeyan bẹ lati ma le gbowo jade sita.
Oṣu kẹrin ọdun 2024 yii ni CBN ni yoo bẹrẹ.
Bakan naa ni aṣẹ naa ni awọn ti ki i saba lo akanti wọn fowo rẹpẹtẹ le lo BVN abi NIN nikan fun asopọ, nigba ti awọn ti wọn n lo akanti wọn fun karakata ati lilo owo pupọ yoo nilo BVN ati NIN lati so mọ apo akanti wọn.
Bawo lo ṣe le so NIN ati BVN rẹ mọ akanti rẹ ni banki ?
Eyi ni i ṣe pẹlu ileefowopamọ ti o ba n lo.
Awọn banki kan fi anfaani silẹ fawọn onibaara wọn lati ṣe asopọ yii lori ayelujara.
Bẹẹ lawọn mi-in yoo fi nọmba kekere ( short code) ranṣẹ, tabi ki wọn fi lẹta ta a mọ si ‘email’, ranṣẹ si onibaara lati ba oṣiṣẹ banki to ba wa loju opo sọrọ lori ilana naa.
Ohun to ṣe pataki ni pe ki kaluku lọ si banki rẹ, ko si beere ilana to daa to si rọrun ju lati so awọn nọmba mejeeji pọ mọ akanti wọn.
Anfani wo ni asopọ BVN ati NIN yii yoo mu wa?
Oṣu kẹta yii ni asopọ naa yoo wa sopin gẹgẹ bi CBN ṣe palaṣẹ.
Awọn banki si ti n fi atẹjiṣẹ ṣọwọ sawọn onibaara lati ja a kunra, ko too wa sopin.
Ṣugbọn ki gan-an ni anfaani igbesẹ yii.
Akọṣẹmọṣẹ nipa eto ọrọ aje ati inawo, Mata Irene David-Arinze, ṣalaye fun BBC pe igbesẹ naa yoo fọ ẹka iṣuna Naijiria mọ tonitoni.
O ni ipo ti ẹka yii wa lasiko iṣakoso Godwin Emefiele, to jẹ gomina CBN tẹlẹ, ti ba nnkan jẹ gan-an, atunṣe pataki si ni lati wayi ni kiakia.
Irene sọ pe asopọ yoo jẹ ki CBN mọ bi nnkan ṣe n lọ lẹka ọrọ aje Naijiria
Yoo jẹ ki oju awọn onimagomago han sode pẹlu iṣẹ ọwọ wọn.
O ni o le pẹ kawọn eeyan too maa ri ipa ti asopọ yii ni, ṣugbọn ọsan yoo so didun nigbẹyin.















