Àwọn ajínigbé jí èèyàn 30 gbé lọ lásìkò tí wọ́n ń kírun lọ́wọ́ ní Zamfara

Awon ajinigbe

Oríṣun àwòrán, NPF

Ko din ni eeyan ọgbọn ti iroyin fidi ẹ mulẹ, pe awọn ajinigbe ji gbe lọ nipinlẹ Zamfara lasiko ti wọn lọ kirun aarọ l’Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keji ọdun 2024 yii.

Ijọba ibilẹ Tsafe niṣẹlẹ naa ti waye lasiko ti awọn eeyan naa n kirun lọwọ.

Yatọ si awọn ti wọn ji gbe, iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ọhun tun de awọn ilu mi-in nijọba ibilẹ Dansadau.

A gbọ pe wọn pa ọpọlọpọ eeyan nibẹ, wọn ji awọn mi-in gbe titi to fi mọ awọn obinrin.

Bakan naa ni awọn ilu bii Dankurmi, Fari Ruwa, Tungar Kawo, Dan Ma'aji atawọn mi-in n koju ijinigbe ati ikọlu gidi.

Yatọ si ijinigbe, wọn n fi ẹran jẹ oko wa

Gẹgẹ bi awọn olugbe agbegbe yii to ba BBC sọrọ ṣe wi, wọn ni awọn janduku naa n ji awọn gbe nikan kọ, wọn tun maa n da awọn ẹran wọn wọnu oko lati jẹ oko awọn run.

‘’ Bi a ba sọrọ lori eyi, wọn maa yinbọn pa ẹni to ba sọrọ yẹn ni’’

A ki i lọ soko nigba ojo, inu ira la ti n dako tiwa. To ba wa di igba ojo yẹn, wọn maa waa fiya jẹ wa, wọn aa pa awọn eeyan wa, wọn aa ji wọn gbe. Eyi ko jẹ kawọn eeyan ṣiṣẹ oko mọ.

" Gbogbo ohun ta a gbin ni wọn ko lọ. Tẹlẹ, bi wọn ko ba rowo gba labule, wọn aa bẹrẹ si i pa awọn eeyan ibẹ ni’’

Bẹẹ ni agbẹ kan to ni ka forukọ bu oun laṣiiri ṣalaye fun BBC.

Ọkan ninu awọn olugbe ilu Farinruwa, nijọba ibilẹ Maru, sọ fun BBC pe ikọlu ṣi n lọ lọwọ niluu oun.

O ni Awọn to ṣi alupupu ija wọbẹ yoo to aadọta (50).

Àlàyé Ìjọba Zamfara rèé lórí ìkọlù ọ̀hún

Gomina ipinle Zamfara, Dauda Lawal

Sulaiman Bala Idris, agbẹnusọ funjọba ipinlẹ Zamfara, sọ pe ijọba ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ologun Naijiria leti.

O ni ijọba Zamfara ti bẹrẹ igbesẹ akin lori ijinigbe, ipaniyan ati jijẹ gaba lori oko oloko wọnyi.

Nipa ijinigbe ọgbọn eeyan to ṣẹlẹ yii, ijọba ipinlẹ naa sọ pe iwadii ti bẹrẹ pẹrẹwu.

O tojọ mẹta ti ipinlẹ Zamfara ti n koju iṣọro aabo, eyi to ni i ṣe pẹlu ijinigbe, didana-sun ile ati dukia awọn eeyan, bẹẹ naa ni wọn n ji ẹran wọn gbe sa lọ.

Ijọba ipinlẹ Zamfara ṣe agbekalẹ ikọ ologun ti yoo maa koju idaamu yii, ṣugbọn ikọlu ko yee pọ si i.