Àsìkò ti tó láti pín ìjọba Nàìjíríà, tó bá máa yanjú ìṣòro wa- Wole Soyinka

Aworan Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Others

Agba onkọwe Ọjọgbọn Wole Soyinka tí pe fun pinpin ìjọba lorilẹede Naijiria lati jẹ ki onikaluku gbajumọ idagbasoke to kan wọn.

Soyinka sọ eyi nigba to sọrọ níbi ayẹyẹ Aadọta ọdun ileeṣẹ iroyin The Punch, o ni ọrọ atunto ilu ni ko ti ṣe anfani kankan fun orilẹede Naijiria.

"Ọrọ atunto ilu ni itumọ rẹ yatọ fun onikaluku sugbọn eyi ti a mọ yii ni ko ṣe anfani kankan fun wa boya nípa eto ọrọ aje tabi idagbasoke."

Soyinka tẹsiwaju pe pinpin ìjọba nìkan ọna abayọ si ọwọngogo ounjẹ to gbode lorilẹede Naijiria.

O ni gbogbo ipade atunto ilu to ti waye tẹlẹ lorilẹede Naijiria lo jẹ ìtanjẹ lasan, ti ko si se anfani kankan.

'Ìjọba gbọdọ fòpin sí gbígbe wa rin irinajo'

Soyinka tẹsiwaju pe ẹka ìjọba pata gbọdọ dẹkun riri awọn araalu gẹgẹ omugọ lati tí fi le tẹfẹ arawọn ati jẹ ki araalu jina si ìjọba.

Soyinka o ṣeese koko ki ìjọba sumọ pẹkipẹki si araalu.

"Asiko ti to fun ijọba lati dẹkun gbigbe wa rin irinajo lati le jẹ ki ijọba sumọ awọn araalu.

"A o fẹ ki orilẹede Naijiria tu sugbọn o ti n tu labẹ lẹ. Ẹ jẹ ki orilẹede tu, kí awọn eeyan sì wa. N ko fẹran ọrọ atunto ilu rara.

"Oye ye awọn oloselu tí wọn ko ba si ni ipo sugbọn wọn yipada ti wọn ba de ìjọba. Nkankan naa ni pẹlu atunto ilu ti a n sọ yii. Asiko ti to lati se ayẹwo sì.

O tẹsiwaju wa pinpin ìjọba ni ọna abayọ fun idagbasoke lorilẹede Naijiria.

"Awọn oloselu mọ anfani pinpin ìjọba yii sugbọn wọn yoo kọyin si ipe naa ti wọn ba depo."

Soyinka ni pinpin ìjọba yoo agbara sumọ araalu tí ayipada rere yoo si jẹ yọ nipasẹ idagbasoke.