Amúgbálẹ̀gbẹ́ Olùsọ́ ìjọ Sẹ̀lẹ́ CCC gún ọ̀gá rẹ̀ pa l'Osun

Aworan alukoro olopaa

Oríṣun àwòrán, Yemisi Opalola

Olusọ Morris Fadehan ijọ Celestial Church of Christ, Grace of Comfort parish to wa ni agbegbe Omitoto niluu Ile-Ife ri iku ojiji he lọwọ he amugbalẹgbẹ rẹ.

Amugbalẹgbẹ rẹ ọhun, Lekan Ogundipe ni a gbọ pe o gun Olusọ Fadehan pa.

Afurasi Ogundipe ni a gbọ pe o ṣa dede wọ inu Sọọsi lọ nibi ti Olusọ ti n gbadura lọwọ ti o si fi asọ bo o loju to si bẹrẹ si fọ ago mọ lórí.

Lẹyin naa ni iroyin sọ pe o bẹrẹ si fi ọbẹ gun Olusọ naa titi ti o fi ku.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Osun, Arabinrin Yemisi Opalola ti fìdi Isẹlẹ naa mulẹ.

O sọ fun BBC Yoruba pe otitọ ni isẹlẹ naa waye ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹrindinlogbọn Osu Keji ọdun 2024 yii.

Opalola salaye wi pe, ninu iwadi ti awọn se làwọn ti ri pe, lẹyin ti afurasi naa sisẹ laabi ọhun tan lo lọ sọdọ awọn agbaagba ìjọ naa lati lọ sọ fun wọn wi pe ina ti jo Ologbe Morris Fadehan ninu Sọọsi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa tun tesiwaju wi pe, fun ìyàlẹ́nu, afurasi naa jẹ wọ wi pe, oun nikan loun sisẹ laibi naa.

Ati wi pe, lẹyin igba ti oun gun Oloogbe Fadehan lọbẹ tan loun dana sun un.

Arabinrin Opalola sọ wi pe, afurasi naa ti wa ni kolo awọn bayii fun idajọ ododo.

Arabinrin Opalola ti gba gbogbo olugbe Ipinlẹ ọsun ni imọran lati wa ni oju ni alakan fi sọri, ati wi pe, ki wọn ṣọra fun ija to le gba ẹmi ọmọ lakeji.