Kọ́lá Oyewọ tú pẹrẹpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ nípa àìsàn tó fẹ́ẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Kunle Afod/Youtube
Gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Alagba Kọla Oyewọ ti sọ pe kani kii ṣe ifẹ Ọlọrun ni, oun ko ba ti dẹni akọlẹbo tipẹ lori aisan nla to sọ pe o ku diẹ ko ran oun lọ sọrun aremabọ.
Kọla Oyewọ lo tu aṣiri nla yii lasiko ti gbajumọ oṣerekunrin nni, Kunle Afọd lọ ṣabẹwo si nile rẹ to wa niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun.
Agba oṣere naa sọ pe aisan kan ti wọn n pe ni ‘Prostate Enlargement’ lo kọlu oun, to si ku diẹ ko gba ẹmi oun, ṣugbọn to ni ọpẹlọpẹ Ọlọrun.
Kunle Afọd ni oun ko tete mọ pe Baba naa wa lori idubulẹ aisan, to si ni idi niyẹn toun ko fi yọju si. O sọ pe igba toun yoo fi gbọ, iroyin ayọ pe ara rẹ ti pada ya lo tẹ oun lọwọ.
Ninu ọrọ rẹ, o ni “Bọda Peter Fatomilọla lo mu wa lọ si ile Bọda Kọla Oyewọ nigba to jẹ pe adugbo kan naa ni wọn jọ n gbe. Igba ti a de ile wọn, mo ni lati pe e gẹgẹ bi orukọ ti a ma fi n pe wọn ‘Labaluyẹgẹ’.
“Inu wa dun lati ri wọn, bẹẹ ni inu awọn naa dun lati ri wa nigba ti a debẹ. Ṣugbọn nigba ti a bẹrẹ ọrọ, a ko mọ pe bo ṣe ri niyẹn.”
Alagba Kọla Oyewọ to ti kopa ninu ọpọlọpọ iṣẹ tiata ṣalaye ohun ti oju rẹ ri, to si nigba ti aisan naa de ipele kan, oun gba kamu.
“Aisan kekere kọ lo ṣe mi o, o pọ, ṣugbọn Ọlọrun ti gbakoso bayii. Aisan ti wọn n pe ni ‘Enlarge Prostate’ ni mo ni, mo si le ka eeyan mẹfa ti mo mọ, ti awọn naa ni aisan yii.
“Ṣe ẹ kuku mọ pe mi o figba turaka, mi o si fi ọrọ ara mi ṣere, afigba to di inu oṣu keje, ọdun 2019. O ti maa n ṣe mi tipẹ to jẹ pe mi o maa n ṣoro fun mi lati tọ.
“Igba miran wa to jẹ pe ti mo ba fẹẹ tọ, to jẹ pe to ba ku diẹ ki n wọ baluwẹ, maa ti tọ sara.
“Mo ọ si ọsibitu lori ẹ, nigba to ya wọn tọwọ bọ inu mi, wọn wa jẹ ki n mọ pe ile itọ mi lo ti fẹẹ di pa. Wọn pe kini yẹn ni ‘Enlarge prostate’, wọn ni kini yẹn lo ti n tobi.
“
Lọjọ kan ni mo wa mọto de lati Ilara Mokin ti mo ti n ṣiṣẹ. Gbogbo igba ti mo n sọ yii, ara mi le koko daadaa.
“Bi mo ṣe n bọ lọjọ yẹn, mo wa ni lati ya si ọsibitu, lọdọ dokita mọlẹbi wa. Oun lo fun mi ni iwe pe ki n lọ ṣe ayẹwo ni Fajuyi, lọdọ awọn to n ṣe ayẹwo.
“Igba ti modebẹ, iyẹn ko omi inu ọra meji fun mi ki n mu, mo ba mu omi yii. O wa ni ki n sun sori bẹẹdi wọn.
“Niṣe lo n ṣe e bi igba ti wọn ba n ṣe ayẹwo fun alaboyun. Lo ba tun mu iwe yẹn, o kọ awọn nnkankan sii, lo ba tun lẹ iwe naa pa.

Oríṣun àwòrán, Kola Oyewo
“O ni ki n lọ mu iwe naa fun dọkita to ran mi wa. Igba ti mo de ọdọ tiẹ naa, to ja iwe yẹn, o ni aanu ni mo ri gba nitori pe aisan gbẹmigbẹmi lo ṣe mi yii.
“O wa ki n nnkan bọ nnkan ọmọkunrin mi, ko wọle, bẹẹ ni mo n sunkun.
Igba yẹn lo ṣẹṣẹ wa sọ fun mi pe awọn maa gbe nnkan to wa ni ikun mi jade, ati pe iṣẹ abẹ ni wọn maa ṣe fun mi.
“O ni ki n lọ dagbere nile, iyawo mi naa si wa lori aisan nigba yẹn.
Mo ṣaa sọ fun un pe wọn ni ki n wa ṣiṣẹ abẹ ni, a ko si mọ ohun ti yii ṣẹlẹ o. Niṣe la jọ bu sẹkun
“Ọdun 2017 ni iyawo mi ti wa lori aisan rọpa rọsẹ. Igba ti mo pada de ọsibitu, wọn la ikun mi, wọn si ki okun kan sinu mi, wọn ni ibẹ ni maa maa ba tọ.
Nko nilo nnkan ọmọkunrin mi mọ
“Wọn ni ki n ma ba a tete ku, nitori pe o maa n gba ẹjẹ eeyan, ati pe nigba ti wọn maa yẹ ẹjẹ mi wo, o ti lọ silẹ.
Wọn eyi ti wọn maa tun ṣe fun mi, mi o ni le ba obinrin lajọṣepọ mọ, loju ẹsẹ ni mo ti sọ fun wọn pe ko si nnkan ti mo tun fẹ fiyẹn ṣe mọ.
“Mo ti bimọ, awọn ọmọ mi ti bimọ.
Awọn ọmọ mi meji lo tẹlẹ mi lọ.
Wọn ṣa yọ koro ẹpọn mi mejeeji kuro.
Gbogbo awọn to tẹle mi lo ni wọn n sunkun nitori pe ko sẹni to mọ ibi to maa ja si.
“Lẹyin yẹn ni wọn tun ni ki n lọ ya ‘Xray’, kani mo mọ, mi o nii ṣe, nitori pe o le gidi gan an.
Ọjọ keji ni mo lọ gba esi rẹ.
“Ibẹ ni wọn ti wa sọ fun mi pe mo maa tun ni lati ṣe iṣẹ abẹ miran, bi mo ṣe yari niyẹn pe ko si nnkan to jọ.
Latigba naa ni wọn ti gbe ọra ti mo fi n tọ si mi lara.
Mo si ti lọ si lokeṣan lẹyin igba yẹn.”
Bakan naa lo sọ pe Folukẹ Daramọla wa sọdọ oun lati ṣabẹwo soun, ṣugbọn to loun sọ pe oun ko fẹ ko lọ maa pariwo oun sita lati tọrọ owo.
This article contains content provided by Google YouTube. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Google YouTube cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of YouTube post















