Tinubu kò lè pidán tí yóò mú àyípadà rere bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà lásìkò yìí - Wòlíì Ayọdele

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele ti sọ pe Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu kii ṣe opidan to le ri ojutu si iṣoro to n koju araalu latari ipo ti eto ọrọ aje Naijiria wa.
Wolii Ayọdele ṣalaye pe ki eto ọrọ aje Naijiria to le bẹrẹ sii dara diẹ diẹ, yoo to fẹẹ to ipari ọdun to n bọ.
Gbajugbaja Wolii Ayọdele lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọṣhọ Oluwatosin fi sita laipẹ yii, to si tun ṣalaye pe nnkan yoo tubọ maa buru sii bi ijọba ba kọ lati ṣe ohun to yẹ lasiko.
O ni ko si ohun meji to fa bi ijakulẹ ṣe ba eto ọrọ aje to kọja bi ijọba ṣe kọ lati tẹle amọran to le mu ọna abayọ wa si iṣoro to n koju araalu bayii.
“Ẹ ma jẹ ka tan ara wa jẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP lo ti ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ, ṣubọn eyi to pọ ju lo wa lati ọwọ APC.
“Idalabi yii si wa lori Tinubu nitori pe nitori ori rẹ ni nnkan ti bajẹ. Ki awọn ọmọ Naijiria tete mọ pe nnkan ko nii dara lọdun yii.
“Tinubu ko le pidan kankan, ati pe bi nnkan yoo ba fẹẹ dara, yoo fẹẹ to ipari ọdun to n bọ.
“Bi a ba tẹsiwaju lati maa gbadura, ti ijọba ko si gbe igbesẹ to yẹ, ohun kan naa lo ṣi maa ja si. Bi apẹẹrẹ, ijakulẹ nla ni eto ounjẹ iranwọ ti ileeṣẹ ẹṣọ aṣọbode gbe kalẹ, nitori pe kii ṣe ohun ti wọn ro tẹlẹ.
“Ki lo tiẹ de to fi jẹ pe asiko yii ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ sii pin awọn irẹsi yii fawọn araalu? Awọn eyi ti wọn ti n gba lati ọjọ pipẹ sẹyin nkọ?
“Ki lo de ti wọn ko pin wọn sawọn ipinlẹ kaakiri orileede yii lai jẹ pe atọwọdọwọ ni wọn fi ṣe, ki wọn si ṣe ohun to tọ?”
Ohun ti yoo ṣẹlẹ loṣu mẹjọ si asiko yii yoo ya awọn eeyan lẹnu
Ṣaaju aisko yii ni Wolii Ayọdele ti pe ijọba apapọ Naijiria si akiyesi lati ma ṣe gbe eto iranwọ ti wọn fẹẹ ṣe faraalu gba ọdọ awọn gomina, bi ko ṣe awọn oludasilẹ ileeṣẹ to n pese ounjẹ labẹle.
Wolii Ayọdele ni ijakulẹ ni yoo jẹ fun awọn gomina nitori pe wọn ko nii tẹle amọran, ati pe ohun ti yoo ṣẹlẹ laarin oṣu mẹjọ si asiko yii yoo jẹ iyalẹnu f'awọn ọmọ Naijiria.
“Awọn naa yoo tun kuna bi wọn ba kọlati tẹle amọran. Wọn ko gbọdọ fun ẹnikẹni lowo iranwọ nitori pe iwa ajẹbanu lo maa pada bọ si.
“Ẹ jẹ ki wọn lo awọn owo yii fun eto ọgbin, ki wọn si ja owo ounjẹ rẹ wa silẹ fun araalu. Ijọba ko ni eto kankan fun araalu, niṣe ni wọn pe awọn ajọ aladani ati oluranlọwọ mọra, ki wọn gba iṣẹ yii ṣe, ko si ma ṣe jẹ pe awọn ileeṣẹ ijọba lo maa ṣe e.
“Eyi yoo ja dọla danu, ki wọn si fopin si kiko awọn nnkan wọle, dipo bẹẹ ki wọn jẹ ka maa lo awọn ohun ti wa ti a n ṣe nibi.
“Eyikeyi ninu awọn ti wọn ko ba fẹẹ fọwọsowọpọ ni ki wọn pa ti sẹgbẹ kan. Ohun ti mo n ri loṣu mẹjọ si asiko yii yoo ja awọn araalu laya.
“A nilo lati lọ sinu eto ọgbin nitori pe ijọba ko le tẹsiwaju lati maa na owo ti ko ni lọwọ.”















