Tinubu ṣetán àmúlò àbájáde ìgbìmọ̀ Oronsanye tó dàbá àtúntò ìṣàkóso ìjọba

Aworan aarẹ Tinubu ati afihan abajade iwadii igbimọ Oronsanye

Oríṣun àwòrán, BBC/This Day

Igbimọ alaṣẹ orileede Naijiria labẹ idari aarẹ Bola Tinubu ti pinnu lati ṣe amulo aba to wa ninu abajade igbimọ Oronsanye.

Igbimọ Ooransanye yi jẹ eleyi ti ijọba to wa lori oye labẹ Goodluck Jonathan gbe kalẹ lati mu atunto ba awọn ileeṣẹ ijọba ati ajọ orisi ti wọn ni agbana ni wọn jẹ fun ijọba.

Bayo Onanuga to jẹ ọkan latra awọn agbẹnusọ aarẹ Tinubu lo fi ikede yi soju opo rẹ ni Twitter X.

O sọ pe lẹyin ọddun mejila ti igbimọ yi gbe abajade rẹ kalẹ fun ijọba, o ni bayii ọpọ awọn ileeṣẹ ijọba ni wọn yoo parẹ ti wọn yoo si da awọn mii papọ mọ ara wọn.

Igba akọkọ kọ ni yi ti ijọba apapọ Naijiria yoo mẹnu ba ọrọ abajade igbimọ yi.

Atẹjade naa ko sọ bi ijọba ṣe fẹ gba ṣamulo awọn aba to wa ninu abajade igbimọ yii.

Ta ni Oronsanye,ki lo rọ mọ abajade igbimọ rẹ?

Aworan Stephen Oronsanye

Oríṣun àwòrán, This Day

Stephen Oronsanye ti wọn forukọ rẹ pe ori igbimọ yi jẹ olusiro owo to si fi igba kan jẹ olori ileeṣẹ ijọba Naijiria.

Ọdun 2012 ni igbimọ to dari rẹ ṣe agbekalẹ aba lori ọna ti ijọba le fi mu atunto ba ẹka ileeṣẹ ijọba ati awọn ajọ labẹ ijọba.

Ọdun kan sẹyin igba yi ni 2011 ni Aarẹ Goodluck Jonathan gbe iṣẹ yi le igbimọ naa lọwọ.

Lati igba naa titi di asiko yi, ijọba Jonathan to gbe igbimọ yi kalẹ ati ti Aarẹ Buhari to tẹlẹ, ko si eleyi to ṣe amulo patapata aba ti igbimọ yi da lori ọna abayọ si owo gọbọi ti ijọba n na lori awọn ileeṣẹ ti o da silẹ.

Oju iwe ẹgbẹrin ni wọn gbe aba igbimọ yi si to si jẹ pe pataki ninu rẹ ni pe wọn daba ki ijọba pa awọn ileeṣẹ kan rẹ ki wọn si da awọn mi papọ tori iṣẹ kanna ni wọn jijọ n ṣe.

Lara aba naa ti a ri ni pe:

  • Ki wọn di awọn ileeṣẹ ijọba 263 to wa nilẹ ku si 161
  • Ki wọn pa ileeṣẹ 38 rẹ
  • Ki wọn da awọn 52 papọ mọ ara wọn
  • Ki awọn mẹrinla si pada si ẹka ileeṣẹ labẹ ileeṣẹ ti wọn ti sọ wọn di ajọ ileeṣẹ ijọba.

Lara awọn ajọ ti ọrọ yi yoo kan la ti ri ajọ ICPC,EFCC ati Code of Conduct Bureau ti igbimọ Oronsanye naa daba pe ki wọn sọ wọn di ajọ kan ṣoṣo.

Eredi pataki awọn atunto ti igbimọ yi daba ni pe wọn yoo mu adinku ba iye owo ti ijọba n na lori awọn ileeṣẹ wọnyi.

Ki lo de to fi pẹ to bayii ki wọn to ṣamulo aba igbimọ Oronsanye?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi egungun ẹja ni aba ti igbimọ Oronsanye yi da jẹ lọrun awọn ijọba to gbe iṣẹ le lọwọ.

Nigba ti aarẹ Buhari wa lori oye, o tun gbe igbimọ alabẹ ṣekele kalẹ ti o ni ki wọn tun yẹ aba igbimọ yi wo.

Koda igbimọ to gbe kalẹ yi naa tun gbe iwe aba ṣekele kan jade ṣugbọn titi to fi kuro lori oye, a ko ri wi pe ijọba Buhari ṣamulo aba igbimọ Oronsanye.

Awọn onwoye sọ pe mimu aba yi ṣẹ yoo milẹ titi ni iṣakoso ijọba Naijiria tori pe ọpọ awọn ileeṣẹ ni ọrọ naa yoo fọwọ kan.

Lapẹrẹ, aba naa s pe ki wọn pa awọn ajọ alalaaji ton ṣeto irinajo silẹ mimọ fawọn musulumi ati ajọ ton ṣto irinajo silẹ mimọ fawọn Kristẹni naa.

Dipo ki wọn jẹ ajọ to da duro lọtọ, aba ti Oronsanye mu wa ni pe ki wọn dawọn pada sabẹ ileeṣẹ ọr ilẹ okere Naijiria ti wọn wa tẹlẹ.

Bi eleyi ba waye, awọn to dipo alagbara mu tẹlẹ ko ni lagbara mọ ti eleyi si le bi awọn to n ṣe atilẹyin fun ijọba lọna kan tabi omiran ninu.

Ọrọ to ba tiẹ ti fọwọ kan ẹsin ni Naijiria jẹ nkan to maa n da wahala silẹ tori naa eyi le jẹ ọkan lara ipenija ti ko jẹ ki wọn ṣamulo aba Oronsanye yii.

Kini Tinubu fẹ ṣe ti yoo yatọ si tatẹyinwa?

Minisita fọrọ iroyin Naijiria to fi ọrọ yi to awọn akọroyin ile ijọba leti sọ pe igbesẹ yi ''ṣafihan akin ati igboya aarẹ Tinubu lati gbe awọn igbesẹ ti ko rọrun lati gbe''

Mohammed Idris sọ pe ohun ti eleyi tunmọ si nni pe awọn ajọ,ẹka ati ọfisi ileeṣẹ ijọba kọọkan ni wọn yoo parẹ.

''Wọn yoo ṣe atunto awọn kan ti wọn yoo si da awọn mii papọ mọ awọn miran.Awọn mii si ni ijba yoo gbe lọ si ibi ti wọn yoo ti lapa gẹgẹ bi ero ijọba''

Hadiza Blaa Usman to jẹ olugbaninimọran pataki si Aarẹ sọ pe tori eleyi, Aarẹ Tinubu ti ṣe agbekalẹ igbimọ ti yoo ṣe amulo awọn aba WỌNYII.

O ni ọsẹ mejila ni igbimọ yi yoo fi ṣe iṣẹ naa.