Tinubu yan Dangote, Elemelu, Soludo sí ìgbìmọ̀ tí yóò ṣe àtúnṣe ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà

Aworan Bola Tinubu pẹlu awọn agbaọjẹ oniṣowo

Oríṣun àwòrán, Office of the SA on Social Media to PBAT/X

Lojuna lati mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba eto ọrọ aje Naijiria, Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti kede igbimọ oludamọran onibẹta sita.

Aarẹ Tinubu ni lara awọn eto lati jẹ ki eto ọrọ aje Naijiria wa loju kan ṣoṣo, ko si ye e foniku-fọla dide mọ.

Igbimọ naa lo kun fun awọn aṣoju latio ijọba apapọ, ipinlẹ ati awọn ileeṣẹ aladani ti wọn peju sibi ipade to waye nile agbara, Aso Rock l’Abuja lọjọ Aiku, to kọja yii.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ Tinubu ni;

“A n ṣe awọn ohun to tọ lati ji eto ọrọ aje wa pada saye. Gẹgẹ bi mo ṣe sọ lọpọ igba, awọn ọmọ orileede yii nikan la ni lati tẹ lọrun.

“Ati pe wọn jẹ wa logun. Lati ori awọn akẹkọọ, awọn iya, awọn baba, awọn agbẹ ati awọn olokoowo.

“Bi a ṣe n jẹ ko ye ara wa pe inu odo kan naa ni gbogbo ti maa pọn omi mu, a ti n wa awọn afikun ọna miran lati ṣe iranwọ fun awọn ọmọ Naijiria to ku diẹ kato fun, ka si fun wọn ni ireti ati ifọkanbalẹ pe eto ọrọ aje wa ti n ji pada.

“Kii ṣe ohun ti a n sọ ni pe a ni gbogbo idahun si ọna abayọ, ṣugbọn ki wọn ba a bu ẹnu atẹ lu wa wi pe a ko gbe igbesẹ rara.”

Lara awọn igbimọ naa lati ileeṣẹ aladani ni; Aliko Dangote; alaga BUA, Abdulsamad Rabiu; gomina CBN tẹlẹ, Gomina Chukwuma Soludo tipinlẹ Anambra ati awọn miran.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa, Dangote jẹ ko di mimọ pe lori eto ọrọ aje, aabo fun ounjẹ ati dida iṣẹ silẹ ni igbimọ ọhun wa fun.

Dangote ni igbimọ naa yoo ṣagbeyẹwo gbogbo ohun to n fa awọn iṣoro ati ipenija wọnyi, ti wọn yoo si wa ọna abayọ sii

Bakan naa, Soludo ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe awọn yoo maa ṣe ipade loore-koore lati gbe awọn ọna abayọ kalẹ fun aarẹ.