Wo ọ̀nà tí obìnrin bá gbà ní Ààfin Deji Akure tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ kò ní r'ọ́mọ bí láyé

Yoruba bọ, wọn ni idalu ni iṣelu, eyi lo difa fun ọna kan ti wọn pe ni ọna ọkunrin ni aafin Deji Akure ti obinrin ko gbọdọ gba.
Oloye Sele ti ilẹ Akure, Taiwo Fagite sọ fun BBC pe eewọ ni fun obinrin lati gba ọna yii.
Oloye Sele sọ pe ''obinrin ko ni anfani lati gba ọna ọkunrin nitori eewọ ni.
Ko ni ri nnkan oṣu rẹ mọ debi wi pe yoo ri ọmọ bi mọ laye.
To ba dẹ jẹ obinrin to dawọ nnkan oṣu duro, igbagbọ wa ni pe ko ni i ni oju ara mọ.''
Oloye Sele ti ilẹ Akure, Taiwo Fagite ni Aafin Deji Akure wa ninu awọn aafin to dagba ju nilẹ Yoruba, o si jẹ ikan ninu awọn aafin to ṣe pataki nilẹ Yoruba.
''Ohun ni a ṣe maa n ki wa ni Akure ni pataki Deji Akure wi pe...ọmọ ọlọna meji ti obinrin ti n gba ti ọtun.
Ọna obinrin lo wa ni apa ọtun yẹn, ọna ọkunrin lo wa lapa osu wa nibi yii.
Ṣugbọn nitori pe aye jẹ aye awa ọkunrin, awọn ọkunrin ni anfani pupọ lati gba ọna obinrin jade si inu aafin ti o si nkan kan to maa ṣe wọn, nitori igbagbọ wa ni pe , Deji Akure, ọkunrin ni.
A ko tii gbọ ninu itan ri ṣa wi pe obinrin kan gba ọna ọkunrin yẹn tori ko si igba tẹ de aafin yii, ti ẹ ko ni ba ẹnikan ni ọna ọkunrin to n ṣọ ọ,'' Oloye Sele lo sọ bẹẹ.
Oloye Sele ni awọn ''n gbiyanju lati daabo bo aafin yii tori o ti wa lati nkan bi ọdun 826 sẹyin, ohun ta n ṣe ni pe ka ro o, ko le duro daadaa, ko ma lọ di wi pe ko maa lọ dẹgbẹ si apa kan kan tori ile yẹpẹ ni.
















