Wo àwọn àwòrán tó jẹ ojú ni gbèsè pẹ̀lú àwọn èèkàn tó wá síbi òkú Iya Sunday Igboho

Aworan Sunday Igboho
Aworan awọn alejo nibi eto isinku iya Sunday Igboho
Aworan awọn alejo nibi eto isinku iya Sunday Igboho
Aworan Sunday Igboho pẹlu Kola Olotu
Aworan awọn alejo nibi eto isinku iya Sunday Igboho

A fẹ́ káwọn bàbá wa tì wá lẹ́yìn lórí àti dá ẹ̀ṣọ́ aláàbọ̀ sílẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá - Sunday Igboho

Aworan Sunday Igboho

Gbajugbaja ajafẹtọ ọmọ Yoruba, Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho ti ke si gbogbo ọba alade ati adari ilu nilẹ Yoruba lati fi agbajọwọ ṣe idasilẹ ikọ ẹṣọ aabo ti yoo maa gbogun ti iṣoro eto aabo nilẹ Yoruba.

Lasiko to n sọrọ lọjọ Abamẹta nibi eto igbalejo fun ayẹyẹ isinku iya rẹ ni gbọngan nla igbalejo Sablak to n bẹ l'opopona Soka niluu Ibadan, Igboho ni, "Nibi ti Naijiria de duro nisin, gbogbo wa la mọ pe Naijiria yẹn, ko si nnkan nibẹ mọ.

Mo wa rọ ẹyin baba wa ti Ọlọrun ko ijọba Naijiria le lọwọ, eto aabo ilẹ Yoruba ṣe pataki gan an."

"Gbogbo awọn Fulani ti wọn dẹru ba wa ninu igbo ti wọn n ba nnkan wa jẹ, o to gẹ. Dide ti a de yii nisin, a fẹ ki ẹyin baba wa, ẹyin ọba wa ki ẹ ṣe atilẹyin fun wa ki a da ikọ ẹṣọ aabo silẹ ki a le mojuto gbogbo ibi to ba yẹki a mojuto, ki oloko le maa re oko, ki olodo dẹ le maa re odo."

Lori awọn to n sọrọ wuyẹwuyẹ sii leti pe ki o sọrọ odi si Tinubu nitori ibi ti nnkan de duro lọwọlọwọ bayii ni Naijiria, Igboho ni oun ko ni bu Tinubu nitori pe aarẹ tuntun to n bẹ lori aleefa lọwọlọwọ bayii kọ lo ba Naijiria jẹ.

O ni, "Awọn kan ni o yẹ ki n maa bu Tinubu, kilode ti maa fi bu Tinubu? Ṣe oun lo ni ki wọn lọ pa mi mọ inu ile?

Ṣe oun lo n ṣe ijọba nigba ti wọn kọ lu mi?

Ṣe ẹnu igba to ti de yii, o ni ki n ma ṣe Yoruba Nation?

Mo ti n ṣe Yoruba Nation ki o to de, a dẹ n tẹsiwaju."

Bakan ni Igboho fi kun ọrọ rẹ wi pe ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede yii, DSS ba fẹ ri oun, ki wọn kọ lẹta ranṣẹ si agbẹjọro oun, Pẹlumi Ọlajengbesi, ajafẹtọmọniyan naa ni oun yoo yọju si ileeṣẹ naa, niwọnba igba ti wọn ko ba ti ni ki oun wa fi ọju han ni ipinlẹ to yatọ si Ọyọ l'ọdọ Ṣeyi Makinde, Eko l'ọdọ Babajide Sanwo-Olu ati ipinlẹ Ogun l'ọdọ Dapọ Abiọdun nitori awọn Gomina wọnyii ko ni gba ki ẹnikẹni gba ẹmi lọrun oun.