Gowon ní kí àwọn ọmọ Nàíjíríà ṣe sùúrù fún Ààrẹ Tinubu

Aworan Aarẹ Tinubu ati Yakubu Gowon

Oríṣun àwòrán, Aso Rock Villa/Facebook

Olori orileede Naijiria tẹlẹri, Yakubu Gowon ti gba gbogbo araalu lati tubọ ṣe suuru fun Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lori awọn ohun to n ṣẹlẹ kaakiri.

Yakubu Gowon lo parọwa yii lasiko to lọ ṣe abẹwo si Aarẹ Tinubu nile agbara, Aso Rock to wa niluu Abuja laipẹ yi.

Gowon nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade ikọkọ toun pẹlu Tinubu ṣe, jẹ ko di mimọ pe o ti ya ju fun aarẹ lati tete ṣe aṣeyọri nla laarin oṣu mẹjọ to de ipo.

Bakan naa lo ni oun ti sọ fun Tinubu lati ma ṣe ariwo ti awọn ọmọ Naijiria n pa, ati bi wọn ṣe n bu ẹnu atẹ lu, sibẹ o ni ijọba n sa ipa rẹ lati le yọ orileede yii kuro ninu iṣoro.

“Mo ro pe ijọba n gbiyanju agbara rẹ lati yọ orileede yii kuro ninu iṣoro, ṣugbọn ni ti awọn ọmọ Naijiria, ẹ ma mikan, wọn le maa bu ẹnu atẹ lu ẹ.

“Awọn to wa nita mọ ju ohun ti a mọ lọ. Mo lero wi pe niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria fun aarẹ ni asiko lati mu ohun gbogbo bọ sipo.

“O ti ya ju lati maa reti esi rere lasiko yii, eyii ni erongba temi.”

Bakan naa, siwaju sii ni Gowon to jẹ ọkan lara awọn agba ati oludasilẹ ajọ idagbasoke ilẹ Iwọ-Oorun Afrika, ti a mọ si Economic Community of West Africa (ECOWAS), sọ pataki idi to fi lọ ki Aarẹ Tinubu.

O ni anfaani nla lo jẹ foun pe Tinubu gba oun laaye lati lọ kii ni Aso Rock, ti awọn si jọ sọrọ to nii ṣe pẹlu itẹsiwaju Naijiria.

“Anfaani lo jẹ, wi pe ni asiko yii, Tinubu fun mi ni anfaani lati fojuriju pẹlu ẹ lati sọ oriṣiriṣi ọrọ, paapaa julọ nipa awọn ohun to n ṣẹlẹ ninu ajọ ẹgbẹ ECOWAS lasiko yii, ti mo ro pe o yẹ ko ni iyanju.

“Ati pe bi mo tun ṣe jẹ ẹnikan to ṣẹku ninu awọn oludasilẹ ECOWAS, mo lero wi pe o yẹ ki n sọ awọn igbesẹ ti wọn lẹ ṣe lati pana wahala to n jẹyọ.

“Lara awọn ohun pataki to gbe mi wa ri aarẹ ree, ti a si jọ ni asọyepọ to lọ daadaa.”

Wo ọ̀nà márùn-ún tí Tinubu le gbà mú ayé rọrùn ní Nàìjíríà

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, @BATofficial

Ileeṣẹ Banki to n ri si idagbasoke Afrika ṣe ikilọ pe bi ọwọngogo se gbode ni awọn orilẹede Afrika paapa lorilẹede Naijiria, le fa ọpọlọpọ rogbodiyan.

AfDB gba awọn orilẹede ni amọran lati gbe igbesẹ ni kiakia eyi ti yoo gbegi dena ewu to wa ni iwaju wọn, ti ara yoo si tu araalu.

Iṣoro ọwọngogo ounjẹ yii fa iwọde ni ipinlẹ Oyo, Niger ati Eko lorilẹede Naijiria,

Orilẹede Naijiria n koju ọpọlọpọ wahala lẹyin ti ijọba yọ owo iranwọ epo bẹntirool ati bi kudiẹkudiẹ se ba owo naira.

Saaju, ijọba ti gbe awọn igbesẹ kan lati mu nnkan rọrun fun araalu - wọn gbe ounjẹ sita, wọn ba awọn ontaja irẹsi ati awọn ọIọja ti wọn ko ounjẹ wọle lati di iye owo ti wọn ta ku.

Ipo wahala ni Naijiria wa ni owo se n gun ounjẹ lojojumọ - Onimọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pẹlu gbogbo eyi, Iṣoro ti awọn ọmọ Naijiria n koju n peleke si ni.

Ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede Naijiria – PDP ti sọ fun Aarẹ Tinubu lati kọwe fipo silẹ ti ko ba le wa oju tu si iṣoro ti orilẹede Naijiria n koju lẹyin to yọ owo epo bẹnitirool.

Ọjọgbọn Garba Ibrahimb Sheka, onimọ nipa ọrọ aje lorilẹede Naijiria, ni ipo ti Naijiria wa bayii lo jẹ ipo wahala nitori naa ni owo se n gun ounjẹ lojojumọ.

O ni owo n to n wọle ko pọ rara, awọn osisẹ ko ri afikun owo oṣu sugbọn ọwọngogo n peleke si, ti isẹ si n ba awọn araalu ja.

Gẹgẹ bi o ṣe salaye,”Awọn eeyan to ni awọn owo lọwọ gan lasiko yii ko si iyatọ lara gbogbo wa.”

Nigba to n sọrọ, Oni Abubakar Aliyu ni iwọde to n waye ni awọn apa ibi kan lorilẹede Naijiria ti fihan pe ijọba ni lati gbe igbesé.

O wa ran Aarẹ Tinubu leti pe iwọde lori ọwọngogo burẹdi lo gba ipo agbara lọwọ Al-Bashir ni orilẹede Sudan.

Onimọ naa sọ pe airi ounjẹ jẹ yii jẹ iṣoro nla fun gbogbo araalu.

Bakan naa o tun ran Aarẹ Tinubu leti ko ranti ileri to se fun awọn araalu saaju ko to bọ sipo pe yoo pese isẹ , fowokun owo oṣu awọn osisẹ sugbọn nnkan ti yiwọ bayii,

Aliyu ni ọna meji ni Aarẹ le gba lati mu igbe aye rọrun fun araalu.

Ọ̀na ti aarẹ Bola Tinubu le gba mu aye dẹrun:

Sisi ẹnu ibode pada lati ko ounjẹ wọle

Aworan

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPE

Onimọ naa ti Tinubu lati jade, sọ fun awọn araalu pe ounjẹ yoo wole lati oke okun, ti yoo si de ọdọ awọn araalu.

Ọgbọn Garba Sheka ni bi ijọba se ti ẹnu ibode pa jẹ ọkan lara ohun to sokunfa rogbodiyan yii nitori awọn agbẹ Naijiria ko le gbin irẹsi ti yoo to fun awọn araalu.

O wa rọ ijọba lati gbe igbesẹ lori sisi ẹnu ibode lati fun ounjẹ ni anfani lati wọle si ọdọ awọn araalu.

Pipese iranlọwọ ni awọn ẹka ijọba

Abubakar Aliyu ni bi ijọba se n igbiyanju lati yọwọ ninu iranwọ to n pese se akoba pupọ fun eto ọrọ aje nitori asiko ti ijọba nilo lati se agbatẹrun awọn ẹka yii ree.

Nibi ọsẹ kan sẹyin ni Ijọba kede pe oun fẹ yọ owo iranwọ ina mọnamọna bi pe o n gba ọpọlọpọ owo lapo ijọba.

Aliyu ni ti ijọba ba fẹ mu igbe aye rọrun, wọn i lati tẹsiwaju ninu sisan owo iranwọ ina mọnamọna, pese owo iranwọ fun ounjẹ, mu adikun ba owo ori ti awọn to n ko ounjẹ wọlw san.

Mimu adikun ba iye owo ti wọn fi se ijọba

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Shamsudden Muhammad ti ile ẹkọ fasiti Bayero niluu Kano ni igbesẹ akọkọ ti ijọba ni lati gbe ti wọn ba fẹ ki ilu rọrun fun awọn araalu ni lati mu adikun ba iye owo ti wọn n lo lati se ijọba.

“O nira fun talaka lati wa ni ipo yii, ki awọn oloṣelu si ma rin irinajo kiri pẹli owo ijọba ninu ọkọ bọgini.

“Ko ki i n se owo kekere ni wọn fi n tun awọn ọkọ yii ṣe ati ti wọn n fi a epo rọọbi si”, o salaye

Ti o ba lọ soke, isalẹ a se pada si

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Shamsudden Muhammed ni “Ibi ti eeyan ba gba lọ soke, ni yoo gba pada.

Gẹgẹ bi o ṣe salaye, o ni gbogbo ilana ati igbesẹ ijọba lo da wahala yii silẹ paapa yiyọ owo iranwọ ati jija owo naira walẹ.

O ni ti ijọba ba fẹ wa ojutu si iṣoro to wa nilẹ yii, awọn igbesẹ ati ilana ti ijọba gbe kalé nilo atunse.

“To si n jẹ pe ohun ti a ta lo sọ bi owo naira yoo se jẹ, owo naira ko le dọgba laye.”

Abubakar ni ijọba ni lati wọ ẹyin ti ibi ti wọn ti n bọ nitori o debi pe igbesẹ ati ilana ti wọn gbe kalẹ ko ipa kankan.

O ni fun apẹẹrẹ ki ijọba da owo iranwọ epo bẹnitirool pada, eyi to ni yoo mu idikun ba inira ti awọn araalu n koju lasiko yii.

O ṣeeṣe ki ijọba da owo iranwọ epo pada?

Dokita Shamsudden ni “ Nigba ti mo ni ki owo iranwọ epo pada, awọn eeyan kan ro pe mo n jawọn. Wọn ni ibo ni owo na waa?

“Ko si nnkan to le mu rọrun ba awọn araaly ayafi ki wọn da owo iranwọ pada.”

Ọgbọn Sheka naa pẹlu Dokita Shamsudden pe owo iranwọ yoo mu irọrun ba awọn araalu lasiko ti nnkan nira yii.

Abubakar Aliyu ni “ Ko ki n ṣe koko pe ki wọn da owo iranwọ epo sugbọn wọn le da pada fun igba diẹ.