Tinubu, a kò fọkàn balẹ̀ mọ, ìlérí tí o ṣe fún wa kọ́ rèé, ebi ń pa wá - Olùwọ́de n‘Ibadan

Aworan

Ogunlọgọ awọn eeyan niluu Ibadan lo tu sita lati ṣe iwọde eyi ti wọn n fi tako bi ọwọngogo ounjẹ ṣe gbode lorilẹede Naijiria.

Bẹẹ ba gbagbe, irufẹ iwọde yii lo ti waye ni awọn ipinlẹ bii Niger ati Kano ninu oṣu yii.

Agbegbe Mokola niluu Ibadan ni iwọde naa ti bẹrẹ, ti wọn si lọ si awọn agbegbe mii lati jẹ ki ohun wọn de oke lọdọ Ijọba.

Ariwo ebi n pa wa ni ọpọ awọn araalu mu bọ ẹnu, ti wọn si n naka abuku si Aarẹ Bola Tinubu pe ileri to ṣe saaju eto idibo fun awọn araalu kọ lo n mu wa si imusẹ yii.

Bakan naa ni wọn jẹ ko ye ijọba pe awọn ko le fọkanbalẹ mọ nitori ebi ti fẹ se awọn lese ni ilu.

Aworan olufẹhonuhan niluu Ibadan

"Gbogbo igbesẹ ijọba Tinubu lo mu inira dani, lati igba to ti bọ sori aleefa ni inira, ebi, airijẹ ti de ba wa"

Ileeṣẹ BBC News Yoruba bọ si igboro ilu Ibadan lati tọpinpin iwọde naa, ti a si bawọn araalu sọrọ lori ohun to jẹ isoro wọn.

Ọkan lara awọn olufẹhonuhan to ba wa sọrọ, salaye pe gbogbo igbesẹ ijọba Tinubu lo mu inira dani, ti ko si gba ibi kankan tẹ araalu lọrun.

“Ijọba ti a dibo fun, ti wọn se ileri fun wa pe awọn yoo ran wa lọwọ, pe inu wa yoo dun sugbọn o ṣe ni laanu pe lati igba ti ijọba yii ti bọ sori aleefa ni inira, ebi, airijẹ ti ba araalu.

“Nitori eyi ni a fi bọ sita lati jẹ ki wọn mọ pe ebi wa ni ilu.

“Ijọba lo ni awọn fẹ gbe ilana wa, wọn gbe ilana tuntun bayii ni ara ni wa.

“Osisẹ ijọba ni mi, mo wa ni ipele kejila, nigba ti Baba mi wa ni ipele kẹwaa, o ti n gbe nnkan rere ṣe sugbọn emi ti mo wa ni ipele kejila, n ko ni nnkan ti mo le tọka si."

Olufẹhonuhan mii to ba wa sọrọ ni gbogbo ounjẹ pata lo ti gbe owo lori, ti ara si n ni gbogbo araalu lasiko ijọba yii.

O fẹsun kan ijọba pe lasiko ti wọn ṣe iponlogo, wọn ko sọ pe ibi yoo se ri ree, ti wọn ko si le fọkan balẹ mọ

Aworan
Aworan
Àkọlé fídíò, Obasa Twins: Àwọn aya wọn ní Tayé ló burú púpọ̀, ó máa ń sọ̀rọ̀ sí ìkejì rẹ̀ bíi ọmọdé ni

Ìwọ́de lórí ọ̀wọ́n oúnjẹ́ bẹ̀rẹ̀ n‘Ibadan, ọlọ́pàá fọnmú

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Arsenalatic

Saaju iwọde to fẹ waye niluu Ibadan, to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo lonii, Ojọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keji ọdun 2024 lori eto ọrọ aje to mẹyẹ ati inira ti awọn araalu n koju.

Iwọde naa ni o fẹ waye ni agbegbe Mokola niluu Ibadan, ni bi ti ọpọ awọn olufẹhonuhan yoo ti pade.

Eyi lo n waye lẹyin iwọde lori inira ti awọn araalu n koju nipa ọwọngogo ounjẹ to ti waye ni awọn ipinlẹ bi Kano, Minna ati awọn mii lori inira ti yiyọ owo iranwọ epo bẹntirool da silẹ lorilẹede Naijiria.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe ikilọ pe awọn ko ni fi aye gba iwọde ti too da eto alaafia ilu laamu.

Iwe ilede nipa ifẹhonuhan

A ko ni fi aaye silẹ fun rogbodiyan lati bẹ silẹ lasiko iwọde - ọlọpaa

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa, Adewale Osifeso fi lede, o se ikilọ fun awọn araalu, paapaa awọn olugbe ipinlẹ Oyo pe awọn ko ni fi aye silẹ fun rogbodiyan lati bẹ silẹ lasiko iwọde NLC ati TUC.

Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo ni awọn bu ọwọ fun ẹtọ araalu to ni wọn ni anfani l;ati ṣe iwọde sugbọn eyi gbọdọ waye ni ilana ti ofin ilu gba kalẹ.

Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ko ti gbọ nkankan lati ẹnu ẹgbẹ oṣisẹ nipa iwọde ti wọn fẹ se.

Ileeṣẹ Ọlọpaa wa rọ obi ati alagbatọ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn lati ma fi aye silẹ fun awọn janduku lati ya wọn lo fi da alaafia ilu laamu.

“Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo bu ọwọ fun eto awọn araalu lati se iwọde alaalafia sugbọn o ṣe koko ko waye ni ilana to ba ofin mu.

“O se koko ki awọn eeyan to n gbero iwọde yii mọ pe o ṣeeṣe ki awọn janduku darapọ mọ wọn."

Ṣe iwọde ẹgbẹ́ oṣiṣẹ yoo waye ni awọn ipinlẹ yoku?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ Ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti jẹ ko di mimọ pe awọn ko ni fi aye gba rogbodiyan kankan lasiko Ti iwọde ọlọjọ meji ti ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria n gbero lati se fi tako iṣoro ọwọngogo to gbode ati bi inira se ba awọn ọmọ Naijiria.

Ikilọ yii lo jade sita lẹyin ti Ileeṣẹ banki AfDB kede pe ọwọngogo owo iye epo ni Naijiria, Ethiopia, Angola ati Kenya le fa ọpọlọpọ wahala ni abẹle.

Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adegoke Fayoade ti ṣe ipade pẹlu awọn olori ẹgbẹ osisẹ ti ọrọ kan.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle pe awọn ẹgbẹ osisẹ ti fi da awọn loju pe iwọde naa yoo waye ni ilana to ba ofin mu.

O fikun pe ikọ ileeṣẹ ọlọpaa yoo wa nilẹ lati ri pe iwọde naa waye ni ilana ti ofin gbe kalẹ.

“A ko ni ibẹru. Kọmisana ti ṣe ipade pọ pẹlu ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC, ti a si ni idaniloju pe ko ni si wahala,

Bakan naa, Kọmisana fun Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abiodun Alamutu ni oun yoo se ipade pọ pẹlu awọn olori ẹgbẹ osisẹ lọjọ Aje lori Iwọde ti wọn gbero lati se.

Alamutu ni eyi ni lati ri pe Ẹgbẹ osisẹ ati ileeṣẹ ọlọpaa wa loju ọna kana lati ri pe awọn janduku ko gba iwọde naa mọ wọn lọwọ.