Àwọn Dókítà ní ọjọ́ díẹ̀ ni á lò láyé àmọ́ a ti pé ọdún méje báyìí - Ìbejì tó lẹ̀pọ̀

Àkọlé fídíò, Awọn ibeji to so papọ yi n ṣe daada ni ile ẹkọ

Nigba ti wọn bi Marieme ati Ndeye,awọn dokita ni ko si ireti pe wọn yoo pẹ laye.

Wọn ti pe ọdun meje bayii awọn si ni ibeji to so papọ to wa ni ilẹ Yuroopu ti wọn gbeeru si.

Wọn yatọ ni iṣeesi amọ wọn nilo arawọn fun igbayegbadun.

Baba wọn Ibrahim sọ pe ''Bi wọn ba ti sọ fun eeyan lati ibẹrẹ pe ko ni pẹ laye, niṣe ni yoo maa gbe igbe aye bẹẹ bẹẹ''

Awọn ibeji ti o so papọ ko wọpọ ni Yuroopu.

Pupọ ni wọn a maa bi wọn ku ti ida mẹta mii ninu wọn a si maa ku laarin wakati mẹrinlelogun ti wọn ba bi wọn saye.

Tori naa iwuri nla lo jẹ fun Ibrahima ati awọn dokita lati ri Marieme ati Ndeye pẹlu awọn ọrẹ to wa bawọn yọ ajọyọ ọjọ ibi ọdun meje wọn.

Ibrahima Ndiaye ati awọn ọmọ rẹ Marieme ati Ndeye

Ẹsẹ meji lo gbe ara Marieme ati Ndiaye duro ṣugbọn ọpa ẹyin ọtọọtọ ati ọkan ọtọọtọ ni wọn ni.

Ni ile ẹkọ wọn ni South Wales, wọn pese itọju gbogbo igba fun wọn ni.

Ibrahima sọ pe ''akikanju ni wọn wọn si ja ireti awọn to ro wọn pin''

''Awọn ọmọ mi mejeeji yatọ si arawọn.Marieme ko lagbaja yatọ si Ndieye ti o yaju ''

''Mi o ni tan ara mi pe o rọrun lati tọju awọn ọmọ yi. Oore ọfẹ nla lo jẹ lati ri igbiyanju wọn lojojumọ''

Marieme and Ndeye dey share one pair of legs and one pelvis but each get spinal cord and heart.

Nigba ti wọn bi awọn ibeji yi ni Senegal lọdun 2016,ọmọ kan lawọn obi wn n reti.Awọn dokita ko lero pe wọn le lo ju ọjọ diẹ lọlaye.

''Mo ti n gbaradi lọkan mi de wi pe wọn ko ni pẹ laye''

Bẹẹ ni Ibrahima sọ fun awọn to fọrọ wa lẹnu wo ninu fiimu BBC kan ti wọn pe akọle rẹ ni ''Inseparable Sisters.''

''Nkan taa le ṣe fun wọn ka duro ti wọn ninu irinajo yi.Lati ilẹ lo ti han kedere siwa pe awọn akikanju laa n ba ṣe pọ ti wọn si wawọ mọ aye gidi gaan''

Marieme ati Ndeye
Àkọlé àwòrán, Marieme ati Ndeye nifẹ si ki wọn maa ba awọn ọrẹ won ṣere nile ẹkọ wọn ni Cardiff

Ọna ti wọn fi le dool ẹmi wọn ni ki wọn ya wọn sọtọ.

Baba wọn ṣalaye pe awọn beere iranwọ ti awn si kangun si ilẹ Gẹẹsi fun itọju ni ile iwosan Great Ormond Street Hospital, London lọdun 2017.

Ero Ibrahima ni pe ilumọọka ile iwosan to ti ya awọn ibeji sọtọ yi yoo le ṣe bẹẹ fawọn ọmọ rẹ ti wọn yoo si pada lọ ba awọn ẹgbọn wọn ni Dakar amọ ọrọ ko ri bẹẹ.

Ayẹwo fihan pe ọkan Marianne ko lagbara lati le ṣe iṣẹ abẹ yi.

Bẹẹ lawọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun si sọ fun wọn pe lai pin awọn mejeeji lọtọ ko ni si eyi ti yoo lo ju oṣu diẹ lọ laye.

Wọn ni yiya awọn ọmọ naa sọtọ ni yoo jẹ ki Ndeye lanfaani lati gbe ile aye.

Eyi tunmọ si pe ki Irahim fun awọn dkita ni iyọnda ki ọkan ninu awọn ibeji naa ku ki ikeji baa le wa laye.

Ọkan baba awọn ọmọ yi ko gbe ti iya awọn ọmọ naa si pada si Senegal lati lọ tọju awọn ọmọ to ku.

Ibrahima duro ti awọn ibeji rẹ ki wọn baa le gba itọju.

Nibẹ ni wọn ti ko lọ si Cardiff

Marieme ati Ndeye

Ibrahima to jẹ ọga ileeṣẹ to n ṣeto irinajo fawọn eeyan ni Senegal sọ pe "O nira lati ma ri awọn mọlẹbi eeyan to ku tori pe ile ni gbogbo ile ati ọna mi wa''

O tẹsiwaju pe'' mi o jẹ ki o daamu ọkana mi pupọ.Ojuṣe mi ni gẹgẹ bi obi lati ri pe eeyan kan wa pẹlu wọn nibi.Iṣẹ ti mo gba niyẹn gẹgẹ bi obi''

Loore koore ni awọn ieji yi nilo itọju tori wọn wa ninu ewu lati ko kokoro aifojuri.

Dokita Gilian Body ọkan lara awọn akọsẹmọṣẹ ni ile iwosan fasiti Wales sọ pe ''Nkan iyalẹnu lo jẹ t ieeyan ba kọkọ bẹrẹ tori pe inu iwe lasan la ti maa n ka nipa awọn nkan wọnyi''

Awọn ẹya ara awọn ibeji yii

O ṣalaye pe ẹsẹ kan ati ibadi kan ni wọn jijọ ni.A sun soke lati aboonu wọn to ṣe pe ẹya ara pọ nibẹ.A ko le sọ pato ṣugbọn a mọ pe o ni awọn ẹya ara kan to ṣe pe awọn mejeeji ni wọn jijọ n lo papọ''

''Ọpa ẹyin meji ọtọọtọ lo sọ pe awọn ọmọ yi ni to si ṣe pe pẹlu bi wọn ṣe sunmọ ara wọn to, wọn ko ni lilo lati sọ fun ara wọn ki wọn to yi ara si ibi to wu wọn.''

Wiwọ aṣọ fn awọn ibeji yi tun jẹ iṣoro mii.

Ibrahima sọ pe ''aṣo meji to jọ ara wọn ni mo ni lati ra. Lẹyin igba naa ni maa tun gbe e lọ si ọdọ telo ki o baa le ṣatunṣe ki o le gba ara wọn''

Ipele kẹta lawọn mejeeji wa nile ẹkọ ti wọn ti n kẹkọ ni Cardiff.

Marieme ati Ndeye

Oríṣun àwòrán, Ibrahima Ndiaye

Ibrahim sọ pe "Mo fẹ ki wọn gbe igbe aye bi awọn ara yoku ki wọn ba awọn ọmọde ṣere ki wọn kun fun ayọ ki wọn si dagba bi awọn to ku''

''Wọn o ni lati sa pamọ tori ile ẹkọ awọn ti ko ni ipenija kankan ni wọn wa taa si fẹ ki o kọ wọn pe oore ọfẹ lo jẹ lati darapọ mọ awujọ wọn''

Ipenija to ku bayii ni ki Marieme ati Ndeye gbera nilẹ ki wọn si maa fẹsẹ wọn rin.

Nkan bi ogun iṣẹju lojumọ ni wọn fi n duro bayii''

Ibrahim fi kun pe ''wọn ti ribi ṣe awọn nkan tawọn eeyan ko tiẹ lero pe wọn yoo le ṣe rara''

Ibrahima Ndiaye

O tẹnu mọ pe ''ti wọn ba sọ fun ẹ lati ibẹrẹ pe ọjọ iwaju rẹ ko daju,eeyan ko ni fi gbogbo ara be igbe aye''

''Mo mọ wipe bo pẹ bo y mo maa gb ipe wi pe nkn laburu ti ṣẹlẹ''

Igba ti yoo jẹ, mi o fẹ mọ. A o maa mu ọjọ kọọkan to ba ti ṣe n wa''