Tanzania: Àwọn Ìbejì tó so papọ̀ dolóògbẹ́ lọ́mọ ọdún 22

Awọn ibeji to so papọ lorilẹede Tanzania, Maria ati Consolata Mwakikuti ti di oloogbe lẹyin ti ọkan wọn kọo lati sisẹ(heart failure).
Awọn obinrin mejeeji naa ni ọkan meji, apa ọtọọtọ, sugbọn wọn so papọ lati idodo titi de isalẹ, pẹlu ẹdọ ati ẹdọfooro
Osu Kejila ọdun to kọja ni wọn fi wọn si ile iwọsan, lẹyin ti wọn ni aisan ọkan, sugbọn wọn ku ni Ọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja.
Iroyin iku wọn naa ti da ọgbẹ ọkan silẹ fun awọn ara Tanzania, ti ọpọlọpọ wọn si n kẹdun iku wọn nitori wọn fẹran awọn ibeji naa lọpọlọpọ.
Aare orilẹede naa, John Magufuli sọ loju opo ayelujara rẹ wipe inu oun bajẹ nipa iku awọn ibeji naa.








