Àwọn agbébọn ṣọsẹ́, wọ́n gbẹ̀san ìkọlù sáwọn Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Ọlọpaa kan ti padanu ẹmi rẹ nibi ikọlu to waye ni agbegbe Nasarawa Zurmin nipinlẹ Zamfara, ti eeyan meji mii si farapa lasiko ti awọn agbebọn sekọlu si agbegbe naa.
Gẹgẹ bii iroyin o tẹ wa lọwọ, awọn agbebọn naa sina bolẹ fun awọn idile ninu ilu naa, ti wọn si tun dana sun awọn ile ọpọ olugbe agbegbe naa.
Iroyin to tẹ BBC lọwọ ni pe isẹlẹ naa waye lẹyin ti awọn osisẹ ẹsọ alabo ti ijọba ipinlẹ naa gbe kalẹ sekọlu si ibi ti awọn agbebọn sa pamọ si, ti wọn si sekupa lara wọn.
Ni ana ọjọ kejidinlogun oṣu keji, ni awọn agbebọn naa gbe igbesẹ lati gba ẹsan, ti wọn si kọlu agbegbe Nasarawar Zurmi, lasiko ti awọn eeyan n gbero lati ki irun irọlẹ.
“A n sọrọ lọwọ ni irolẹ ni agbọ ariwo, awọn agbebọn bẹrẹ si ni sina bolẹ.”
Olugbe agbegbe naa ti ori ko yọ ni awọn agbebọn naa ni wọn mura bi ọmọ ologun ti wọn n dabobo araalu.
“Asọ wọn da bi ti ileeṣẹ ologun, ti awọn eeyan si n ki sugbọn wọn ko kọ bi ara si.
“Wọn morile ileeṣẹ ọlọpaa, wọn sina bolẹ, dana sun ẹnikan ti wọn ri ni ita .
“Wọn dana sunọkọ ati ọkada ti wọn ba ni ita, ti wọn si tun ji awọn ounjẹ gbe lọ.”
Ileeṣẹ BBC gbiyanju lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Zamfara, DSP Yazid Abubakar sugbọn ko gbe ipe rẹ.
Bakan naa, agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Zamfara, Suliaiman Balal Idris naa ko gbe ipe rẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Àwọn jàndùkú ṣekúpa ọ̀gá àgbà CBN tẹ́lẹ̀rí ní Kaduna, jí èèyàn 50 gbé lọ

Oríṣun àwòrán, getty images
Awọn janduku ti ṣekupa eeyan mẹfa o kere tan lagbegbe Kwassam ati Sabon Layin, nijọba ibilẹ Kauru, nipinlẹ Kaduna.
Bakan naa ni wọn ji awọn eeyan gbe lọ, lara wọn ni ọga agba kan ni banki apapọ Naijiria, CBN nigba kan ri Zakariya Markus ati aburo rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko tii fidi iroyin naa mulẹ, atẹjade kan lati ọọfisi ajọ Southern Kaduna Peoples Union (SOKAPU), ti agbẹnusọ rẹ, Josiah Abraks buwọlu sọ pe oru ọjọ Ẹti ni ikọlu ọhun waye.
Abraks sọ pe awọn agbebọn naa tun ji aadọta eeyan gbe lọ ninu ikọlu miran ni abule Sabon Layin lasiko kan naa.
O wa ke si ijọba ipinlẹ Kaduna ataawọ ẹṣọ alaabo lati ji giri ki wọn si kọju ija si awọn janduku ọhun to n da ipinlẹ Kaduna laamu.
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ naa, Uba Sani ti ke si ileeṣẹ ọmọ ogun lati mura si iṣẹ wọn nipinlẹ naa lọna ati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.
Gomina ọhun ni oun ti ran kọmiṣọna to n ri si eto abo, Samuel Aruwan, lati ṣabẹwo si awọn agbegbe ti ikọlu naa ti n waye.
Kerawa, to jẹ agbegbe ti awọn darandaran pọ si ni aringbungbun Kaduna jẹ ọkan lara awọn ibi ti ikọlu lẹmọlemọ awọn janduku agbebọn ti maa n waye.
Amọ awọn to n fara kasa awọn ikọlu naa julọ ni awọn agbẹ to wa lagbegbe ọhun.
Wayi o, ijọba Kaduna ti sọ pe oun yoo tẹsiwaju lati maa daabo bo awọn eeyan ipinlẹ naa.















