Ẹ̀rù baba ẹ̀rù! Àwọn ajínigbé ń fí ejò dẹ́rù ba àwọn tí wọn jì gbé, ejò bu ọ̀pọ̀ jẹ

Aworan afihan ejo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn eeyan to moribọ lọwọ awọn ajinigbe laipẹ yi ti sọ pe niṣe lawọn alaburu yi n fi ejo dẹru ba awọn lahamọ.

Ileeṣẹ iroyin Naijiria nii News Agency of Nigeria,NAN, lo jabọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn to moribọ kọọkan ti wọn si ṣalaye ọrọ yii.

Wọn ni niṣe ni ejo pọ lawọn inu igbo ti wọn gbe awọn salọ si ti awọn ejo yi a si maa bu awọn ajinigbe ati ẹni ti wọn ji gbe jẹ.

Ọkan ninu awọn to ba NAN sọrọ, to si ni ki wọn fi orukọ bo awọn laṣiri sọ pe awọn ajinigbe yi a maa ju awọn eeyan si agbegbe ibi ti awọn ejo yi pọ si.

O ni ''awọn ajinigbe yi mọ ibi tawọn ejo yi pọ si, ti wọn si maa n ju awọn eeyan sibẹ.

Kete ti awọn eeyan ba ti ri ejo naa, ko si nkan ti wọn ba sọ pe ki wọn ṣe, ti wọn ko ni ṣe''

"Ọna ati ri owo gba ni fifi ejo dẹru ba eeyan jẹ"

Ileeṣẹ iroyin NAN tẹsiwaju pe lasiko ti awọn eeyan ba ti ri ejo yi lawọn ajinigbe maa n sọ fun wọn ki wọn pe araale lati fi owo ranṣẹ.

''Ati ile ati ọkọ ati gbogbo dukia ti wọn a ni pata, gbogbo rẹ lawọn eeyan maa n sọ pe ki wọn gbe ta ti wọn ba ti ri ejo ti wọn fi dẹru ba wọn''

Bẹẹ ni ọkan ninu awọn to ba NAN sọrọ ṣe ṣalaye.

BBC ko ribi fidi ọrọ yi mulẹ nipa biba awọn to moribọ sọrọ amọ lọpọ igba ni awọn eeyan jẹri si pe awọn ajinigbe a maa fi iya jẹ awọn ti wọn jigbe lati le fi san owo idoola ẹmi.

NAN tẹswiaju pe awọn agbegbe bi Birnin Gwari ni ipinlẹ Kaduna ati Kala Balge lẹba omi adagun Lake Chad ni Borno jẹ agbegbe ti awọn ejo pọ si daada.

Agbegbe yi naa si ni awọn ajinigbe a maa gbe awọn eeyan pamọ si ju ninu igbo.

Ni ipinlẹ Oyo, ejo pọ ninu awọn igbo Shaki, ni Niger a ri wọn pupọ ni igbo Borgu ati Kagara,Karim Lamido ni Adamawa pẹlu Lau ni Taraba.

"Ejo bu awọn eeyan kan jẹ nigba ti mo wa ni ahamọ"

Eeyan to moribọ lọwọ awọ ajinigbe to ṣalaye nkan toju rẹ ri fun NAN jẹri si wi pe oun ri ti ejo u awọn eeyan jẹ nigba ti awọn wa ni ahamọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ,asiko ooru yi lo buru ju tori awọn ejo naa a maa sa jade ninu iho ti wọn wa lati wa gba atẹgun nita.

''Wọn maa n fi wa silẹ ni ita gbangba ninu igbo ni lalẹ.Lasiko yi si ni awọn ejo yi a maa rin wa lẹsẹ.''

Ẹni yi sọ pe inu igbo kiji to wa ni agbegbe Kagara ni ipinlẹ Niger ni wọn ji oun gbe lọ.

O ni ''nigba ti mo wa lahamọ awọn ejo yi bu awọn eeyan ti wọn ji gbe jẹ. Koda ko yọ awọn ajinigbe naa silẹ ti awọn ejo yi bu jẹ ninu igbo Kagara''

O ni awọn ejo yi pọ ninu igbo lagbegbe yi tawọn araadugbo si sọ wọn lorukọ ''kadangaru kagara'' to tunmọ si alangba Kagara.