Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ wòólì méjì àti babaláwo méjì tó pa ọ̀dọ́bìnrin kan fún ètùtù ọlà

Oríṣun àwòrán, Ogun State police
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn ayederu Wolii ijọ Kerubu ati Serafu meji, Peter Oluwaloṣe ati Jamiu Yusuf, pẹlu babalawo meji ti wọn pe ni Moses Abidemi ati Samuel Monday lori ẹsun ipaniyan.
Lasiko to n foju awọn afurasi ọhun han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta l’Ọjọbọ, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiọdun Alamutu sọ pe awọn eeyan naa lo pa obinrin kan, Sulaimọn Adijat ti wọn ti n wa tipẹ.
Yatọ si awọn mẹrin naa, ọwọ tun tẹ Akinwunmi Ifatosin, Sheriff Agbai ati Osojieahen Alioneitouria lori ẹsun ipaniyan kan naa.
Gẹgẹ bi Alamutu ṣe sọ, deede agogo mẹwaa owurọ ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun 2024 ni wọn wa fi to awọn leti pe wọn n wa obinrin kan, Sulaimon Adijat, ti wọn ko si gburo rẹ.
Alamutu ni iroyin ti awọn gbọ ni pe ẹnikan to n jẹ Adebayọ Olawale Azeez to n gbe ni agbegbe Ajegunle niluu Atan-Ọta lo gbe Adijat jade, to si jẹ pe latigba naa ni wọn ko ti gburo rẹ mọ.
Gbogbo akitiyan awọn mọlẹbi Adijat lati pe e lori foonu lo ja si pabo, nigba ti wọn sọ pe foonu rẹ ko lọ mọ, idi ree ti wọn fi lọ fi to awọn ọlọpaa leti.
Latigba naa ni awọn ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ijinigbe ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ ibi ti Adijat wọlẹ si.
Iwadii awọn ọlọpaa lo jẹ ki ọwọ tẹ awọn meje lori bi Adijat ṣe poora, ti oriṣiriṣi aṣiri si bẹrẹ sii tu sita.
Ọga ọlọpaa, Alamutu jẹ ko di mimọ pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni Sherifff Agbaiati, ọrẹ rẹ, OsojieahenAlioneitouria ni wọn lọ ba Oluwo Samuel Monday ti inagijẹ rẹ n jẹ Oluwo Mandẹla fun etutu ọla.
Wọn ni bi igbesi aye awọn ṣe n lọ ko tẹ wọn lọrun, wi pe awọn nilo lati ṣoogun owo ti wọn n pe ni Oṣolẹ to le fun wọn ni igba miliọnu naira laarin ọjọ meje pere.
Nibẹ ni wọn sọ pe Oluwo Mandela ti sọ pe oun yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira lọwọ wọn ki oun to le ṣe oṣolẹ naa fun wọn.
Lẹyin eyi ni wọn sọ pe Oluwo Mandela ranṣẹ pe Peter Oluwaloṣe lati ba a wa ọdọmọbinrin ti ọjọ ori rẹ wa laarin ọdun mejidinlogun si ogun ọdun, lati le lo ẹya ara rẹ fun oogun owo ti oun fẹẹ ṣe fawọn onibara oun.

Oríṣun àwòrán, Ogun Police/X
Oluwo Mandela ni oun nilo ori, ọyan meji, oju ara ọmọbinrin ati ọrun ọwọ meji ọmọbinrin naa.
Peter to n pe ara rẹ ni Wooli ijọ alaṣọ funfun kan to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lo pe alabaṣiṣẹpọ rẹ to jẹ wooli, iyẹn Jamiu Yusuf ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ẹri Mose nipinlẹ Eko.
Ẹri Mose ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji to kọja okoowo tita ati rira ẹya ara eeyan naa tun pe Abidemi Moses ti awọn eeyan tun mọ si Aṣela, toun jẹ babalawo niluu Atan-Ọta, ipinlẹ Ogun fun ẹya ara obinrin.
Wọn ni Abidemi Moses sọ pe oun yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira lati fi wa ọmọbinrin ti ẹya ara rẹ yoo wulo fun oṣolẹ naa, ṣugbọn ti wọn ni Oluwo Mandela sọ pe ẹgbẹrun lọna oọdunrun naira loun yoo san.
A gbọ pe ọdọ Adebayọ Ọlawale Azeez ti wọn loun ti na papa bora ni wọn sọ pe Abidemi Moses ti n kọ iṣẹ babalawo.
Lẹyin ti idunadura naa wọ tan, ni wọn sọ pe Adebayo Ọlawale Azeez pe Sulaimọn Adijat lọjọ kẹsan, oṣu Kinni, ọdun 2024 wi pe oun fẹ ki wọn jọ jade, ati pe ko jẹ ki awọn pade ni otẹẹli kan niluu Atan Ọta.
Lẹyin ti wọn kuro ni otẹẹli ọhun ni wọn gba igbalẹ Abidemi Moses to wa lagbegbe Igbo Olomi niluu Ado-Odo Ọta lọ.
Nibẹ si ni a gbọ pe wọn ti pa Adijat bi ẹran, ti wọn si yọ awọn ẹya ara rẹ lọ.
Ile Moses la gbọ pe wọn ko awọn ẹya ara naa lọ, nibi ti Oluwo Mandela ati wooli Oluwalose ti n duro de wọn.
Ọluwo Mandela ni wọn lo gba ori, ọyan, nnkan ọmọbinrin, ọwọ meji ati awọn ẹya yooku, to si lọ gun gbogbo rẹ papọ sinu ikoko dudu, nibi ti wọn jo o titi di ọjọ keji.

Oríṣun àwòrán, Ogun Police/X
Wọn ni Wooli Peter Oluwalolese ati Oluwo Samuel Mandela ni wọn jọ pa ẹran agbo ti wọn fi ṣetutu fun ẹmi Adijat ti wọn gba lasiko ti oṣolẹ ọhun n lọ lọwọ.
Lọjọ kẹwaa, oṣu Kinni ni wọn sọ pe Sheriff Agbai ati Osojieahen Alioneitouria lọ gba ipese oṣolẹ naa lọwọ Oluwo Mandela, ko to di pe wọn gbe e lọ si ipinlẹ Edo ti wọn ti wa.
Nigba ti aṣiri maa pada tu sita, wọn ni ko si ayipada kankan ninu igbesi aye Osojieahen Alioneitouria lẹyin to lo ipese naa tan, gẹgẹ bi wọn ti ṣalaye fun wọn.
Ọsẹ mẹta gbako ni wọn fi lo awọn iṣẹ naa, ti wọn sọ pe ko ri ayipada rere kan, wọn lo sọ pe oun ko ri owo toun n fẹ laarin ọjọ meje, idi ree to fi sọrọ jade.
Alamutu to jẹ ọga ọlọpaa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe lẹyin ti aṣiri tu si wọn lọwọ, lawọn lọ sinu igbalẹ Abidemi Moses, nibi ti wọn ti ba baagi obinrin mẹwaa ọtọọtọ, garawa to kun fun ẹya ara eeyan, aake kan, apo simẹnti meji to kun fun egungun eeyan.
O ni awọn mọlẹbi Adijat nigba ti wọn de teṣan ọlọpaa ni wọn ri baagi Adijat ti wọn n wa tipẹ nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Alamutu sọ pe ọpọ ẹri ni awọn ti gba, ti awọn afurasi naa si ti jẹwọ bi wọn ṣe n pa awọn eeyan, o ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju ko to di pe wọn yoo fi oju gbogbo wọn ba ile-ẹjọ.















