Nnkan tó fa ooru gbígbóná tí àwọn ọmọ Naijiria n kojú àti ọ̀nà àbáyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Bi eeyan ba sọ fun mi pe mo maa wẹ lẹẹmẹta lojumọ, mo ma ni irọ lo pa. Amọ mi o mọ nnkan ti mo le ṣe mọ, ooru yi ti pọju''
Bẹẹ ni Tonye Dennis to n gbe nilu Borokiri Port Harcourt ṣe ṣapejuwe ooru gbigbona ti oun ati awọn eeyan mii lorileede Naijiria n koju lẹnu ọjọ mẹta yii.
Laarin oṣu Kini ati oṣu Keji ni awọn ilu to sunmọ eti omi ni Naijiria, asiko yi ni wọn maa n koju ọyẹ ti o jẹ atẹgun gbigbona to n mu eruku wa lati apa ariwa Naijiria si Guusu ilẹ naa.
Amọ ooru ti oju ọpọ eeyan ri lasiko yii kọja ọyẹ ti o maa n saba waye.
O mu ki ọpọ ma le sọ boya ọyẹ lo fa ooru yii ni abi nkan miran.
Ki lo fa ooru gbigbona lasiko yii?

Adari ẹka imọ ayika ni fasiti ipinlẹ Rivers Ọjọgbọn Precious Ede salaye pe iyipada oju ọjọ to waye latari El Nino ati La Nina to wa lati ibi okun lo ṣeeṣe ko ṣokunfa ooru to pọ yi.
O ṣalaye wi pe ọyẹ ni nnkan to wa nita lasiko yii ṣugbọn o dara pọ mọ atẹgun to n bọ lati omi okun lo mu ki ayika mu ooru naa wa.
''Fun awọn ti ko si lagbegbe ti òkun wa, niṣe ni ayika wọn yoo gbona gigi gan-an nitori pe ko si ojo ati pe ko si ọyẹ bakan naa.
Lọpọ igba wọn a maa ri ọyẹ diẹ ti yoo kora jọ, amọ laarin ọjọ meloo kan ni atẹgun to ba si wa lati inu okun yoo si mu ki inira ba awọn eeyan.''
To ba wa di ni alẹ atẹgun ori ilẹ ati ori okun to dapọ mọ ara wọn yoo ma fa inira fawọn eeyan paapa awọn to ba wa leti bebe omi.
O fikun pe ayipada oju ọjọ, Climate change, naa kopa ninu bi oju ọjọ ṣe n ṣe segesege yatọ si bo ti ṣe wa tẹlẹ.
O ni eleyi lo mu ki awọn ibikan maa tutu ju ti tẹlẹ lọ tawọn ibomiran si n gbona ju tatẹyinwa lọ.
Bi ooru ṣe le ṣe akoba fun ara

- Ooyi le ma kọ eniyan, to si le daku, ti ko ba mu omi to
- Bi ọkan ṣe n lọ soke, silẹ, yoo pọ si nitori pe alekun ti ba iṣẹ ti ara n ṣe nitori ooru
- Ara eeyan yoo ṣu u nitori igbona to pọ
- O ṣe e ṣe ki kokoṣẹ eeyan ko wú nitori pe ẹjẹ to n lọ sibẹ pọ si i
- Ori fifọ, bakan naa ni eebi le ma a gbe ọ
Igba wo la o fi farada ooru yi ?
Aisi ina mọnamọna deede ati eruku mu ki ọrọ ooru yii maa daamu ẹmi ọpọ ni Naijiria ti wọn si n beere pe igba wo ni yoo dopin.
Ọjọgbọn Ede sọ pe yoo ṣoro diẹ lati sọ pe igba kan pato ni ooru naa yoo de opin nitori ọrọ oju ọjọ ko ṣe gbẹkẹle.
O ni ''ohun ti a kan le sọ ni pe ti omi okun to yẹ ko maa mu ayika tutu ba pada de, eleyi le mu ki awọn kurukuru oju ọjọ korajọ ti ojo yoo si tẹle.
O ni asiko taa wa yii si jẹ igba to yẹ ka maa reti ojo kan laarin ọsẹ meji amọ eeyan kan ko le sọ pe yoo ri bẹẹ, nitori oju ọjọ le ma ri bẹ''

Nkan taa le ṣe lati fi le ru asiko ooru yi la
Awọn ọmọ kekere ati agbalagba wa ninu awọn to wa ninu ewu ooru lasiko yii botilẹ jẹ pe ara onikaluku yatọ si arawọn.
Lati le koju bi oju ọjọ ṣe ri yii, Ọjọgbọn Ede gba wa lamọran pe:
- Jẹ ki ọna ti atẹgun n gba wọ iyara rẹ pọ daada, ki o si ṣi awọn ferese iyara rẹ nigun kọọkan ki atẹgun baa le wọle daada.
- Mu omi daada. Bi ooru ṣe n mu wa laagun yii, o tumọ sipe omi to wa lara wa lo n jade yẹn. A si nilo omi miran ti yoo rọpo eleyi to n kuro. Amọran Ọjọgbọn ni pe ki awọn eeyan maa mu omi daada ju ti tẹlẹ lọ lasiko ooru gbigbona yi.
- Ma se iṣẹ agbara pupọ ti yoo mu ọ laagun. Amọran naa tun lọ si ọdọ awọn to n ṣe ere idaraya pe ki wọn ṣe pẹlẹ nitori wahala aṣeju le mu inira ba ara wọn.
- Wọ aṣọ fẹlẹ ti yoo jẹ ki atẹgun wọ inu ara rẹ daada.
- Bi o ba wa ni ikapa rẹ, lo ẹrọ amuletutu taa mọ si Airconditioner ti yoo mu ki ayika rẹ tutu daada.












