Afurasi mẹ́tàlá tó pa Ọba Aremu, jí olorì rẹ̀ gbé nípìnlẹ̀ Kwara, di èèrò ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, John Adewoye
Ile ẹjọ Majisireti kan niluu Ilorin, ti paṣẹ pe ki wọn o fi eeyan mẹtala ti wọn fura si pe awọn lo pa Olukoro ti Ikoro, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, Oba Segun Aremu, si ọgba ẹwọn.
Awọn agbofinro gbe awọn afurasi naa lọ sile ẹjọ fun ẹsun ifọwọsowpọ lati hu iwa ọdaran, ipaniyan, ijinigbe, sisọ ayederu akọsilẹ nipa ara wọn.
Awọn eeyan naa, Godwin Jacob, Olowofela Oyebanji, Adefalolu Ayodele, Tewasie Francis, Babatunde Samuel, Godwin Joseph, Issa Number ati Miracle Solomon.
Awọn yooku ni Abraham Kehinde, Muhammed Bello, Muhammed Muhammed, Ahmadu Umaru ati Muhammed Dankai.
Aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa to ko wọn wa sile ẹjọ sọ pe, ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Aremu Simon Adeyemi, lo fi ọrọ iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, nipa iku Ọba Aremu.
“Arakunrin Aremu ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe, niṣe ni awọn afurasi ọhun na imọ si oun, ti wọn si paṣẹ fun pe ko tẹle wọn.
“Eyi waye lẹyin ti ọkunrin naa koju wọn, lasiko to kiyesi irin wọn ni ayika ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin.
“O sọ pe ọmọ-ọmọ oun raaye gba ẹnu ọna ẹyinkule ile salọ, amọ awọn afurasi ọhun pa kabiesi, ti wọn si tun gbe iyawo rẹ ati ẹlomiran salọ.
Eyi lo wa a mu ki onidajọ, Majisireti Monisola Kamson, lati paṣẹ pe ki wọn o fi awọn afurasi naa si ọgba ẹwọn ijọba apapọ to wa niluu Ilorin, titi di ọjọ karun-un, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju.
Ohun to ṣẹlẹ sẹyin


Pasitọ kan, Adeyemi Simon Aremu, ti o jẹ ọmọ ọdun metalelọgọrin to moribọ lọwọ awọn ajinigbe to ṣekupa ọba ilu Koro nipinlẹ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri.
Ni alẹ ọjọ kiini, osu Keji, ọdun 2024, ni awọn ajinigbe yawọ ilu Koro ni ìjọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara, wọn seku pa Ọbalaye ilu naa, Ọgagun fẹyinti Segun Aremu, wọn si tun ji Olori Iyabo Aremu ati ọmọbìnrin kan gbé lọ.
Pasitọ Aremu sọ wi pe oun n jẹun alẹ lọwọ ni awọn gende mẹfa wọle pẹlu ibọn lọwọ ti wọn si ni ki oun ka lọ.
O ni bi wọn ṣe n mu oun lọ ni wọn ri Olori labẹ igi ọsan, ti wọn si pa awa mejeji pọ ati ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Fẹranmi gba inu igbo lọ.
"Nise ni ibọn n ro ti ẹru si n bawa, igba ti mi o ni okun mọ lati tẹsiwaju, wọn bẹrẹ si n wọ mi nilẹ titi a fi de ibikan ti wọn ti ni ki gbogbo wa doju bolẹ.
Ni aafin Onikoro ti ilu Koro, awọn olugbe ilu naa fidi ẹ mulẹ pe, ko si ẹni to le salaye idi ti wọn fi pa Kabiesi, wọn ni ṣe ni awọn ba Kabiesi ninu agbara ẹjẹ lagbala nibi ti o ti n mu ohun mimu ẹlẹrin dodo.
Àwọn ajínigbé ń bèèrè N100m fún ìtúsílẹ̀ Olorí ọba àti èèyàn méjì tí wọ́n jígbé
Ọjọ kẹta ni awọn ajinigbe naa kan si ẹbi ẹnikan lara awọn ti wọn ji gbe pọ mọ olori.
Ọkan lara awọn ara ilu ọhun to ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe awọn ajinigbe naa pe baba Fẹranmi lori ẹrọ ibanisọrọ ti wọn si beere fun owo ọgọrun kan miliọnu naira.












