'Nígbà tí àwọn ajínigbé tó pa Kábíèsí ri pé mi ò lè rìn mọ́ ní wọn ní kí n padà sílé'

Pasitọ kan, Adeyemi Simon Aremu, ti o jẹ ọmọ ọdun metalelọgọrin to moribọ lọwọ awọn ajinigbe to ṣekupa ọba ilu Koro nipinlẹ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri.
Ni alẹ, ọjọ kiini, osu keji ni awọn ajinigbe yawọ ilu Koro ni ìjọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara, wọn seku pa Ọbalaye ilu naa, Ọgagun fẹyinti Segun Aremu, wọn si tun ji Olori Iyabo Aremu ati ọmọbìnrin kan gbé lọ.
Pasitọ Aremu sọ wi pe oun n jẹun alẹ lọwọ ni awọn gende mẹfa wọle pẹlu ibọn lọwọ ti wọn si ni ki oun ka lọ.
O ni bi wọn ṣe n mu oun lọ ni wọn ri Olori labẹ igi ọsan, ti wọn si pa awa mejeji pọ ati ọmọbinrin kan ti wọn n pe ni Fẹranmi gba inu igbo lọ.
"Nise ni ibọn n ro ti ẹru si n bawa, igba ti mi o ni okun mọ lati tẹsiwaju, wọn bẹrẹ si n wọ mi nilẹ titi a fi de ibikan ti wọn ti ni ki gbogbo wa doju bolẹ.



"Ọkan lara wọn pe mi, o si ni ki n maa pada lọ sile, ero mi ni wi pe wọn yoo yinbọn pa mi latẹyin sugbọn mo de ile mi pada lai farapa.
"Wọn ti rii pe ilera mi o peye, to si le fa ifasẹyin fun irinajo wọn ni wọn ṣe fimi silẹ.
"Igba ti mo dele ni mo ba ọpọ ero ni ile Kabiesi ti wọn ni wọn ti yinbọn pa Kabiesi.
Ni aafin Onikoro ti ilu Koro, awọn olugbe ilu naa fidi ẹ mulẹ pe, ko si ẹni to le salaye idi ti wọn fi pa Kabiesi, wọn ni ṣe ni awọn ba Kabiesi ninu agbara ẹjẹ lagbala nibi ti o ti n mu ohun mimu ẹlẹrin dodo.
Wọn rọ ijọba ki wọn ran awọn lọwọ lori eto abo ilu naa ki irufẹ iṣẹlẹ naa ma ba a sẹlẹ mọ.
Igbakeji Gomina Ipinlẹ Kwara naa ti sabẹwo si aafin Ọba to waja naa lati ba wọn kẹdun.
O ni ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ko ni sinmi lati ri pe eto aabo yanranti ni ipinlẹ naa.
O seleri pe awọn ẹsọ alaabo yoo doola awọn ti wọn ji gbe ni kopẹ kopẹ.
Ẹwẹ, Kọmisọnla Ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe awọn ọmọ ogun ti wa kaakiri lati daabo bo awọn eeyan ilu naa ati lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe.
Awọn ọmọ ogun, eleto abo abẹle, Fijilante ati bẹẹ bẹẹ lọ naa ko gbeyin ni agbegbe naa.

Àwọn ajínigbé sekúpa ọba alayé ní Kwara, wọ́n jí olorì kábíyèsí àti èèyàn méjì míì gbé lọ

Oríṣun àwòrán, John Adewoye
Ẹkọ o ṣoju mimu lalẹ ana Ọjọbọ lẹyin tawọn agbebọn ti wọn furasi gẹgẹ bi ajinigbe ṣe yawọ ilu Koro ni ijọba ibilẹ Ekiti ipinlẹ Kwara ti wọn si yinbọn pa ọba alaye ilu na, ọba Ajagunfẹyinti Sẹgun Arẹmu.
Ọkan lara awọn agba ilu naa, Taiwo Atọlagbe ṣalaye pe nkan bi ago mejọ alẹ ni awọn ajinigbe ọhun yabọ afin Onikoro ti ilu Koro.
Ọgbeni Atọlagbe tun fi idiẹ mulẹ pe, awọn ajinigbe naa tun ji olori kabiyesi ti wọn pa ati eyaan meji mi.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti ba awọn eyan ilu Koro kẹdun lori iṣẹlẹ isekupa ọba alaye ilu naa.
Ninu atẹjade ti akọwe eto iroyin Gomina, Ọgbeni Rafiu Ajakaye ṣalaye pe Gomina Abdulraman Abdulrasaq gbarata pupọ lori iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Gomina Abdulrasaq ti seleri pe awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ko ni lọ lai jiya ẹsẹ wọn.
Gomina ipinlẹ Kwara tun fi dawọn eeyan ilu Koro loju pe ijọba yoo sa ipa rẹ lati dola awọn ti wọn jigbe.
Ninu ọrọ rẹ, alukoro ajọ ọlọpa ipinlẹ Kwara, arabirin Ejirẹ Toun Adeyẹmi to fidi iṣẹlẹ na mulẹ ṣalaye pe kete ti ileesẹ ọlọpaa gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni kọmisona ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Victor Olaiya ti kawọn ẹṣọ alabo sọwọ si agbegbe naa.
Kọmiṣọna sẹleri pe ajọ ọlọpaa yoo fi ọwọ ofin mu awọn ajinigbe ọhun.
Ilu Koro to wa ni ijọba ibilẹ Ekiti paala pẹlu ipinlẹ Ekiti nibi ti iṣẹlẹ ijinigbe ti waye lera wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















